Kí ló dé tí ilé ẹjọ́ fún ẹbí Mohbad láṣẹ láti tún àyẹ̀wò òkú rẹ̀ ṣe? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, mohbad/Instagram
Ilé ẹjọ́ Májísíréètì tó ń gbọ́ ẹjọ́ lórí ohun tó ṣokùnfà ikú gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé nnì, Ilerilouwa Aloba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad ti fún àwọn ẹbí rẹ̀ láṣẹ láti tún àyẹ̀wò òkú rẹ̀ ṣe.
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ẹbí Mohbad ní àwọn kò faramọ́ èsì àyẹ̀wò òkú Mohbad tó kọ́kọ́ jáde nítorí àyẹ̀wò náà kò fìdí ohun tó pa a múlẹ̀ ní pàtó.
Ẹbí Aloba ní àwọn kò faramọ́ èsì àyẹ̀wò náà, tí wọ́n sì rọ ìjọba ìpínlẹ̀ Eko, lọ́jọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2024, láti gba àwọn láàyé láti tún àyẹ̀wò náà ṣe.
Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà náà ni kò faramọ́ èsì ọ̀hún.
Ẹ ó rántí pé lọ́jọ́ kejìlá, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2023, ni Mohbad jáde láyé lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tí wọ́n sì sin-ín lọ́jọ́ kejì.
Ikú rẹ̀ fa awuyewuye lórí ayélujára tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní Nàìjiríà sì ní ó yẹ kí wọ́n ṣe ìwádìí ikú rẹ̀ láti fìdí ohun tó pa á múlẹ̀.
Ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 ni wọ́n hú òkú Mohbad fún àyẹ̀wò ní ilé ìwòsàn olùkọ́ni ìpínlẹ̀ Eko, LASUTH láti fìdí ohun tó pa á múlẹ̀.
Àmọ́ nígbà tí èsì àyẹ̀wò náà jáde, èsì náà kò sọ ohun tó ṣokùnfà ikú Mohbad ní pàtó tí àwọn èèyàn sì ń kọminú lórí rẹ̀.
Níbi ìgbẹ́jọ́ tó wáyé lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kẹfà ni àwọn ẹbí Mohbad ti rọ adájọ́ láti gbà wọ́n láàyè kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò òkú Mohbad lẹ́ẹ̀kan sí i fúnra àwọn nítorí èyí tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe kò fi ohun tó ṣokùnfà ikú Mohbad múlẹ̀.
Lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà ni adájọ́ Májísíréètì náà, tó wà ní Ikorodu, ìpínlẹ̀ Eko fún àwọn ẹbí Mohmad láṣẹ láti ṣe àyẹ̀wò òkú rẹ̀ fún ìgbà kejì.
Bàbá Mohbad, Joseph Aloba nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé ẹjọ́ fún àṣẹ náà àti gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí ipa tí wọ́n ń kó lórí ìgbẹ́jọ́ ọ̀hún.
Ọ̀gbẹ́ni Aloba sọ pe ọjọ́ keje, oṣù Kẹjọ̀ ọdún 2024 ni ilé ẹjọ́ fún àwọn dì láti pèsè èsì àyẹ̀wò tuntun náà.
Ó fi kun pé lẹ́yìn tí àwọn bá ti ṣe àyẹ̀wò náà ni àwọn tó máa ní àǹfàní láti sin Mohbad gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe ti ń pè fún.















