Èèyàn 75,000 kó HIV, 45,000 kú láàrin ọdún kan ní Naijiria - Wo bí o ṣe le dáàbò bo ara rẹ

Àyẹ̀wò tó fìdí HIV múlẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others

Àjọ tó ń rí sí àmójútó ààrùn kògbóògùn HIV/AIDS ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, NACA ní èèyàn 75,000 ló kó ààrùn HIV ní Nàìjíríà lọ́dún 2023 nìkan.

Bákan náà ni wan sọ pé èèyàn 45,000 ló pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àìsán tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ààrùn HIV lọ́dún 2023.

Adarí àjọ NACA, Dókítà Temitope Ilori ló sọ èyí níbi ètò kan tí ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìdènà HIV ṣe agbátẹrù rẹ̀ nílùú Abuja lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà, ọdún 2024.

Ilori ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àdínkù ti bá bí àwọn èèyàn ṣe ń kó ààrùn HIV síbẹ̀ ó ní ó pọn dandan láti ṣe àmúṣẹ àwọn àbá tí wọ́n dá níbi ìpàdé àpérò láti dènà HIV tí wọ́n yóò bà á fòpin sí ààrùn HIV/AIDS ní ọdún 2030.

Ó ní ó jẹ́ ohun tó bani lọ́kàn jẹ́ pé èèyàn 75,000 ṣì ń lùgbàdì ààrùn HIV, táwọn 45,000 sì tún pàdánù ẹ̀mí wọn lọ́dún 2023.

Ó wòye pé ohun tó nílò àmójútó gidi ni àti pé iṣẹ́ pọ̀ fún àwọn láti ṣe tí àwọn yóò bà á dènà bí ààrùn náà ṣe ń tàn láti ara sọ́mọ.

“Ní ti dídènà kí ìyá máa kó ààrùn HIV ran àwọn ọmọ wọn, ìdá márùndínlógójì sí ogójì ni a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àmúṣẹ rẹ̀ nínú ìdá márùndínlọ́gọ́rin, a mọ̀ pé a níṣẹ́ púpọ̀ láti ṣe.”

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Mínísítà fétò ìlera àti ìgbáyégbádùn ará ìlú, Ọ̀jọ̀gbọ́n Muhammad Pate rọ àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ lẹ́ka ètò ìlera láti ṣàmúṣẹ àwọn ọ̀nà láti dènà ìtànkálẹ̀ ààrùn ọ̀hún.

Pate ní àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera nílò láti jẹ́ kí àwọn aráàlú mọ̀ nípa àwọn nǹkan tí ó tọ̀ àtàwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n nílò láti dènà ìtànkálẹ̀ ààrùn kògbóògùn HIV.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàtọ̀ wà lórí bí àwọn èèyàn ṣe ń kó ààrùn náà tẹ́lẹ̀ síbẹ̀, ó ní iṣẹ́ pọ̀ láti ṣe láti ri pé ìtànkálẹ̀ ààrùn náà kò tún burú bíi ti àtẹ̀yìnwá.

Abdulkadir Ibrahim, eni tó jẹ́ alákòso àwọn èèyàn tó ń gbé pẹ̀lú ààrùn HIV/AIDS ní Nàìjíríà tẹmpẹlẹmọ ìnílò láti wá òògùn tí yóò máa ṣètọ́jú ààrùn HIV láti ri pé ààrùn náà kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá.

Ó ní tí ẹni tó bá ní ààrùn bá ń lo àwọn oògùn rẹ̀ déédéé bó ṣe tọ́, ó túmọ̀ sí pé ẹni náà kò ní lè kó ààrùn náà ran ẹlòmíràn.

KÍ ni ààrùn HIV/AIDS?

Ẹni tó ń ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ láti mọ̀ bóyá ó ní HIV

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ààrùn HIV tí àpèjá rẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ “Human Immunodeficiency Virus” jẹ́ ààrùn tó máa ń bá àgọ́ ara èèyàn jà, tó sì máa ń mu ṣòro fún ara láti kojú àwọn àìsàn mìíràn.

Tí kòkòrò HIV bá ti wọ èèyàn lára, ẹ̀yà ara onítọ̀hún yóò máa ṣiṣẹ́ lòdì sí bó ṣe yẹ, tí yóò sì máa ṣiṣẹ́ sẹ́yìn.

HIV ló máa ń di AIDS nígbà tó bá ti wọra tán.

Èèyàn kò lè ní AIDS láì ṣe pé onítọ̀hún ní HIV ṣáájú, tí èèyàn bá ní HIV lára, tí kò sí tọ́jú rẹ̀ ló máa di AIDS.

Ẹ̀yà ara tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ni HIV máa ń ṣe lọ́ṣẹ́ èyí tó máa ń mú kí “white blood cell” má ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.

Èyí kò ní jẹ́ kí ara le bá àwọn àìsàn jà láti má dààmú èèyàn kòdá kó jẹ́ èyí tí kò yẹ kó dàámù èèyàn tí kò bá sí HIV.

HIV le wà lára èèyàn fún ọjọ́ pípẹ́ láì sí àmì kankan tó fojú hàn títí tó máa fi dàgbà di AIDS.

AIDS ní tirẹ̀ máa ń fa kí èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní rù, kó máa rẹ èèyàn ní gbogbo ìgbà, kí àwọ̀ ara èèyàn máa yípadà àtàwọn àpẹẹrẹ míì láìpẹ́ tó bá ti dé ara.

Kò sí ẹni tí ààrùn HIV kò lè mú yálà ọmọdé tàbí àgbàlagbà, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kìí sì tètè mọ̀ pé àwọn ní ààrùn yìí.

Àwọn àmì àpẹẹrẹ HIV

Èèyàn le ní HIV fún ọdún pípẹ́ láì mọ̀ pé òun ni nítorí kìí tètè hàn lára àti pé àwọn àmì rẹ̀ náà jọ ti àìsàn mìíràn.

Àwọn àmì tí ẹni tó bá ní HIV sábà máa ń ní ni:

  • Ibà
  • Kó máa rẹ èèyàn
  • Kí ọ̀nàfun máa dun èèyàn
  • Kí ẹran ara máa dun èèyàn
  • Kí èèyàn máa làágùn púpọ̀ ní alẹ́
  • Ẹnu dúndùn
  • Kúrúnọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

Báwo ni HIV ṣe máa ń ràn?

Oògùn láti dènà ìtànkálẹ̀ HIV

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Èèyàn le kó ààrùn HIV bí ẹ̀jẹ̀, omi ara tàbí omi ọyàn ẹni tó ní ààrùn yìí bá wọ ara èèyàn.

Ó lè gba ẹnu, ìdí, ojú ara tàbí ojú egbò gbà wọ ara èèyàn.

Ọ̀nà tó wọ́pọ̀ táwọn èèyàn máa ń gbà kó ààrùn HIV ni látara ìbálòpọ̀ láì sí ohun ìdáàbòbò.

Èèyàn tún lè kó HIV nípa lílo abẹ́rẹ́ tí èèyàn tó ní ààrùn yìí bá ti lò.

Èèyàn kò lè mọ̀ pé òun ní HIV láì ṣe àyẹ̀wò nítorí kìí hàn lójú.

Ṣé ìtọ́jú wà fún HIV?

Títí di àsìkò yìí, kò ì tíì sí oògùn tó ṣe é tọ́jú ààrùn HIV àmọ́ àwọn òògùn wà láti fi mú ipá rẹ̀ dínkù.

Àwọn onímọ̀ ìlera ni àwọn oògùn tí wọ́n máa ń fún àwọn tó bá ní ààrùn yìí láti ri pé wọn ò ko ran ẹlòmíràn.

Ìdènà ààrùn HIV

Ọ̀nà tó tọ̀nà láti fi dènà àìsàn HIV jùlọ ni láti kọ́kọ́ mọ bí àìsàn yìí ṣe máa ń tàn.

Àwọn ọ̀nà láti fi dènà rẹ̀ jùlọ nìyí:

  • Lílo rọ́bà ìdáààbòbò lásìkò ìbálòpọ̀
  • Dènà lílo abẹ́rẹ́ tí èèyàn kan ti lò tẹ́lẹ̀
  • Má gba ẹ̀jẹ̀ tí wọn kòn ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ sára
  • Jìnà sí lílo rọ́bà ìdáàbòbò tí wọ́n fi àwọ̀ ẹranko ṣe
  • Máa ṣe àyẹ̀wò HIV nígbà gbogbo