NCDC dá ibúdò pàjáwìrì sílẹ̀ fún Cholera, wọ́n ni inu ewu ńlá ni Naijiria wà

Aarun cholera

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n mojuto ajakalẹ aarun ni Naijiria, NCDC, ti da ibudo itọju pajawiri silẹ fun Cholera.

NCDC sọ pe awọn kede igbesẹ naa lẹyin ti awọn onimọ nipa aarun ọhun ṣe agbeyẹwo ibi ti itankalẹ Cholera de duro ni Naijiria, lọsẹ to kọja.

Eyi si lo mu ki ajọ eto ilera naa da awọn ibudo amojuto pajawiri silẹ niluu Abuja ati awọn ipinlẹ mẹrindinlogoji yooku.

Wọn ni igbesẹ wọn jẹ ọna lati fi bi itankalẹ aarun naa ṣe to han, ati lati le mu adinku ba a.

Eeyan 1,528 lo ti ni Cholera ni Naijiria, o si ti pa 53.

NCDC sọ pe ojuṣe ibudo pajawiri naa ni lati pese atilẹyin fun awọn ipinlẹ ti Cholera n ba finra, paapaa lati ri daju pe wọn ni anfaani si awọn irinṣẹ aywo, amojuto, idanilẹkọọ, ilanilọyẹ araalu ati awọn oṣiṣẹ.

Ajọ naa sọ pe ṣaaju ki oun to o da ibudo pajawiri silẹ, ni oun ti pin awọn irinṣẹ eto ilera fun amojuto ati idena rẹ, jakejado awọn ipinlẹ.

NCDC dá ibúdò pàjáwìrì síll fún Cholera, wọ́n ni inu ewu ńlá ni Naijiria wà

Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nipa àrùn Cholera

Bi akọsilẹ awọn eleto ilera ṣe wi, awọn ibi ti arun onigba-meji ko ti i de ni Naijriia lasiko yii ko to nnkan.

Ni Naijiria, kọlẹra jẹ ọkan lara awọn arun to maa n ṣẹlẹ latigba degba, paapaa julọ lasiko ojo. Eyi maa n ri bẹẹ lawọn ibi ti imọtoto ba ti mẹhẹ.

Itan sọ pe ajakalẹ arun onigba-meji akọkọ bẹ silẹ ni Naijiria laarin ọdun 1970 si 1990.

Awọn eyi to lagbara mi-in tun waye ni 1992, 1995-1996 ati 1997.

Laaarin oṣu kinni, ọdun 2010 si oṣu kẹwaa, eeyan 1,434 ni ileeṣẹ eleto ilera kede pe kọlẹra pa ni Naijiria.

Ni 2011, eeyan 728 ni wọn ni o pa.

Bí o bá ń rí àwọn ǹnkan wọ̀nyí nípa kọ́lẹ́rà, àpẹẹrẹ ni

Gẹgẹ bi ajọ ‘National Health Service’ (NHS) to n ri si ilera ni UK ṣe wi, eyi ni awọn apẹẹrẹ arun Kọlẹra:

Igbọnsẹ olomi gbuuru ti yoo mu ọ maa paara ile igbọnsẹ.

Aarẹ ara

Inu rírun

Ki omi gbẹ lara (dehydration)

Bí o ṣe lè dènà àrùn onígbá-méjì

Ti o ba ba ara rẹ lori irin ajo lọ sawọn ibi ti kọlẹra ti n ja ran-in, eyi lawọn ohun ti o le ṣe lati dena rẹ

  • Ma a fọ ọwọ rẹ loore-koore pẹlu ọṣẹ ati omi to mọ, paapaa lẹyin ti o ba lo ile igbọnsẹ tan
  • Ri i daju pe o n fọ ọwọ rẹ ki o too bẹrẹ si i se ounjẹ pẹlu
  • Omi inu ike ti wọn ti sè mọ tonitoni tabi ti iwọ funra rẹ sè nikan ni ki o maa mu
  • Omi inu ike ti wọn ti sè tabi ti o sè funra rẹ nikan ni ki o maa fi fọ ẹnu rẹ
  • Ma ṣe jẹ ewebẹ ti wọn ko fi omi inu ike fọ, ti ki i ṣe iwọ lo fọ ọ funra rẹ
  • Ma ṣe jẹ salaadi ti wọn ko fi omi inu ike fọ ewe rẹ
  • Yago fun awọn ounjẹ inu omi bii ede, ẹja, akan ati bẹẹ bẹẹ lọ lasiko yii
  • Ma ṣe lo yinyin tabi bulọọku (ice) fun awọn nnkan mimu rẹ

Ìtọ́jú àrùn Cholera

Itọju gboogi to wa fun arun Onigba-meji ni ki eeyan mu ọpọlọpọ omi, titi to fi mọ omi ti wọn maa n lo ti omi ara ba ti gbẹ.

Omi yii ni wọn tun n pe ni omi ìyè.

Iyẹfun oyinbo ti wọn ti ṣe bii oogun leeyan yoo po mọ omi lati rọpo iyọ, ṣuga ati eroja minira to ti kuro lara latari Kọlẹra.

Iyefun naa wa lawọn ile itaja oogun kaakiri.

Bi ara rẹ ko ba ya gidi, iwọ yoo ni lati lọ sile iwosan, nibi ti wọn yoo ti tọju rẹ pẹlu fifa omi si ọ lara.

Ati fifun ọ loogun apakokoro ti ko ni i jẹ ki Kọlẹra kari ara rẹ.