Kọ́lẹ́rà pa èèyàn 25 l'Eko, Ogun, tí ọ̀pọ̀ èèyàn míì sí dèrò ilé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, AFP
Ijọba ipilẹ Ogun ati ipinlẹ Eko ti fidi itankalẹ aarun onigba meji mulẹ ni ipinlẹ kowa wọn Ogun, eyi ti wọn ni o gba ẹmi eeyan mẹdọgbọn
Ni ipinlẹ Ogun. obinrin kan, ẹni ọdun mejilelọgọta naa ti padanu ẹmi rẹ sọwọ aarun.
Oṣeojumikoro to ba awọn akọroyin ni oloogbe na jade laye lasiko to n se itọju ọmọ rẹ to ni aarun naa, ti ọmọ naa si wa lara awọn eeyan marun un to wa ni ile iwosan.
Bakan naa ni ijọba tun jẹ ko di mimọ pe eeyan marun un ti wa ni ile iwosan bayii nibi ti wọn ti n gba itọju aarun onigba meji Kọlẹra
Kọmisana fun eto ilera nipinlẹ Ogun, Tomi Coker sọ pe iṣẹlẹ naa waye ni Ijebu Ode , ni ijọba ibilẹ Ariwa Ijebu.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ awọn onimọ iṣegun nipinlẹ Ogun fi lede, Alaga ẹgbẹ naa, Kunle Ashimi ni otitọ ni pe aarun naa ti tan ka, to si n ṣe ijamba ni ipinlẹ ọgbọn pẹlu ipinlẹ Ogun.
O wa ransẹ ibanikẹdun si awọn mọlẹbi awọn eeyan naa, “Lonii, aarun onigba meji ti wa ni ipinlẹ ọgbọn to fi mọ ipinlẹ Ogun, ti ọgbọn eeyan si ti ku kakiri orilẹede . A gbadura fun awọn eeyan naa.”
Ashimi ni ijọba ati NMA ko kọ ẹti ikun si iṣẹlẹ yii, ti wọn si n gbe gbogbo igbesẹ lati fopin si itankalẹ naa.
Bakan naa ni ipinlẹ Eko, eeyan mẹrinlelogun lo ti padanu ẹmi wọn sọwọ aarun onigba meji bayii
Ijọba kede ọrọ naa lọjọ Eti nigba ti wọn sọrọ nipa awọn eeyan to ti padanu ẹmi wọn lati igba ti iṣẹlẹ naa ti bẹrẹ.















