Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lórílẹ̀èdè Ghana ní àwọn ilúmọ́ọ̀ká kò gbọdọ̀ polówó ọtí mọ́: Shatta Wale, Camidoh àtàwọn ìlúmọ̀ọ́ká míràn bá fọnmú

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/WENDY SHAY/ FACEBOOK/SHATTA WALE/GETTY GETTY
Ileẹjọ to ga julọ ni orilẹede Ghana ti buwọlu aṣẹ ti ajọ to n n ṣakoso ounjẹ ati mimu lorilẹede naa, FDA pa pe awọn gbajumọ ilu ko gbọdọ polongo tabi polowo ọti lile mọ.
Ajọ naa kede aṣẹ ọhun lọdun 2016 ninu eyi ti wọn ti ni awọn eekan ilu ko gbọdọ bawọn polowo ọti lile mọ.
“Eekan ilu tabi ilumọọka kankan ko gbọdọ farahan ninu ipolowo ọja ọti lile kankan.
Ajọ naa ni eyi wa lara awọn igbesẹ lati dẹkun bi awọn majesin atawọn ọdọ ṣe n bọ sinu aṣa ọti mimu nitori ọna ati fara we awọn ilumọọka wọnyii.
Bakan naa ni ofin ọhun tun ṣalaye pe ileeṣẹ apọnti yoowu to ba fẹ ṣe onigbọwọ eto kankan ko gbọdọ ko ọja wọn lọ fun tita, tabi gẹgẹ bi ẹbun tabi fun awọn eeyan ti ọjọ ori wọn ko to mejidinlogun to ba kopa nibi eto bẹẹ ni ọfẹ”
Ofin naa tun sọ peileeṣẹ apọnti to ba fẹ ṣe onigbọwọ ayẹyẹ, ajọdun, ipolowo ọja tabi awọn ilumọọka gbọdọ kọkọ fi irufẹ ipolowo ọja bẹẹ ranṣẹ si ajọ naa fun ayẹwo.
Nigba to di oṣu kọkanla ọdun 2022, alakoso awọn gbajumọ akọrin meji kan, Reggie ‘N’Bollie ati Screwfaze gbe ajọ naa lọ si ile ẹjọ to ga julọ ni orilẹede GhanaO ni aṣẹ ti ajọ naa gbe kalẹ dẹyẹ si awọn eekan to wa lẹka agbo idaraya.
O wa rọ ile ẹjọ naa lati da aṣẹ tuntun naa nu.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, adajọ agba lorilẹede Ghana, Gertude Torkonoo ni aṣẹ ti ajọ FDA pa naa ko tako iwe ofin orilẹede ọhun.
O tun fi kun un pe aṣẹ naa ko ni i ṣe pẹlu idẹyẹsi, ofin lati fọ ẹka naa mọ ni.
Ki ni wọn sọ lẹyin idajọ naa?

Oríṣun àwòrán, x/Shatta wale
Ọkan lara awọn to gbe ẹjọ naa lọ si ile ẹjọ, Nii Ofoli Yartey ni awọn abala kan ninu aṣẹ naa nilo ki wn tan imọlẹ si i daadaa.
Bakan naa, ọkan lara awọn oṣere tiata ni Ghana, George Quaye kọminu bi o ṣe jẹ pe awọn oṣiṣẹ igbohunsafẹfẹ yoo le darukọ awọn ọ̀ti wọnyii lori eto wọn ṣugbọn wọn ko le polongo rẹ lori afẹfẹ.
Camidoh to jẹ akọrin takasufe ati R&B ni tirẹ sọ pe idajọ naa ko mu ọgbọn dani rara.
“O yẹ ki ile ẹjọ fofin de awọn eeyan pe wọn ko gbọdọ mu ọti mọ ni, amọ lati wa fofin de awọn eekan ilu to fẹ polowo rẹ lati pa owo si apo wọn runi loju diẹ.”
Amọ fun ajọ to n ṣakoso ounjẹ ati ogun lorilẹede Ghana iroyin ayọ ni idajọ yii jẹ.
Oludari ẹka ofin ni ajọ naa, Joseph Bernie ni fun anfani ilu lapapọ ni aṣẹ ti awọn gbe kalẹ naa ati ilera awọn araalu.
Ofin FDA ko mọgbọn wa rara

Oríṣun àwòrán, x/camidoh
Akọrin takasufe, Wendy Shay wa lara awọn akọrin ati ilumọọka tio tisọrọ pe ofin yii ko mu ọgbọn lori rara.
Ninu atẹjade kan to fi si oju opo X rẹ ni ọdun 2020, “Mo ti padanu owo to to ẹgbẹlẹgbẹ dọla Amẹrika pẹlu ileeṣẹ apọnti kan lati ilẹ okeere. Mi o mọ pe awọn ilumọọka ko gbọdọ polowo ọti ni orilẹede Ghana. Iwọnba ounjẹ kekere ti eeyan tun n ri jẹ, ẹ tun fẹ gba a lẹnu mi.” O ni ofin naa ndẹyẹsi awọn ilumọọka ni.
Bakan naa ni Gbajumọ akọrin lorilẹede Ghana, Shatta Wale pẹlu fariga lori ofin naa lọdun 2020. O ni ofin ti ajọ FDA gbe kalẹ naa ti n mu ki awọn ileeṣẹ apọnti lorilẹede naa maa gbe ipolowo ọja wọn fun awọn ilumọọka lati orilẹede Naijiria.
Eyi waye lẹyin ti awọn fọto eekan bii Ini Edo, Jim Iyke, Victor AD atawọn miran ti wọn fi oju wọ̀n han gẹgẹ bi aṣoju ọja wọn.
Lẹyin ọdun meji, ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Ghana ti gbe idajọ rẹ kalẹ.
















