Pásítọ̀ rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́sàn án he lórí ẹ̀sùn wíwọ́ ike àti jìbìtì

Oríṣun àwòrán, getty Images
Pasitọ kan to maa n fi dukia rẹ han faraye lagbegbe Brooklyn, ni New York ti ri ẹwọn ọdun mẹsan an he fun ẹsun jibiti.
Lamor Whitehead, ni apẹle rẹ n jẹ “Bling Bishop” latari bo ṣe maa n wọ oniruru ẹṣọ ara.
Inu oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii ni ile ẹjọ sọ pe o jẹbi ẹsun wiwọ ike, igbimọpọ lati wọ ike, igbimọpọ lati gba owo lọwọ ẹni lọna ti ko tọ ati jijẹri eke fun awọn ẹṣọ agbofinro ijọba Amẹrika.
Awọn agbejọro sọ nile ẹjọ pe Whitehead lo ipo rẹ gẹgẹ bii oniwaasu lati gba owo lọwọ awọn eeyan lọna ati maa gbe igbeaye aladun.
Ọdun 2022 ni orukọ Whitehead kọkọ bẹrẹ si n milẹ titi lẹyin ti awọn adigunjale kọlu u nibi to ti n waasu lori ayelujara lọwọ.
Awọn ole naa gba ẹṣọ iyebiye ti owo rẹ to miliọnu kan dọla lọwọ rẹ lọjọ naa.
Agbẹjọro ijọba kan ni New York, Damian Williams, juwe pasitọ naa gẹgẹ bii onijibiti, ati pe iwa jibiti rẹ ti dopin bayii lẹyin idajọ to gba.
Awọn alaṣẹ ni Whitehead, to jẹ adari ijọ Tomorrow International Ministries, ni Canarsie, New York, tan awọn eeyan jẹ lati gba owo lọwọ wọn, eyii to fi ra awọn aṣọ igbalode ati ọkọ ayọkẹlẹ.
Obinrin kan to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ijọ rẹ fun pasitọ naa ni $90,000 to jẹ owo to fi gbogbo ọjọ aye rẹ pa, eyii to gbagbọ pe pasitọ naa yoo fi ra ile fun oun.
Amọ ṣe ni Whitehead fi owo naa ra aṣọ ati ọkọ ayọkẹlẹ.
Ẹwẹ, awọn agbẹjọro rẹ ti sọ pe awọn yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ rẹ ọhun.















