Ìjàmbá ọkọ̀ pa aláboyún kan àti èèyàn mẹ́ta míì níbi ètò ìsìnkú igbákejì Ààrẹ Malawi

Oríṣun àwòrán, AFP
Ileeṣẹ ọlọpaa ti fi iroyin lede nipa bi ọkan lara awọn ọkọ ijọba to kọwọrin nibi eto isinku igbakeji Aarẹ orile ede Malawi, Saulos Chilima, ti pa awọn mẹrin kan ti alaboyun wa lara wọn nibi ti wọn ti n kẹdun iṣẹlẹ naa.
Awọn mejila miran to farapa nibi eto isinku ọhun to waye lalẹ ọjọ Aiku lo ti wa nile iwoasan fun itọju.
Iṣẹlẹ naa lo waye nipasẹ latari wahala to suyọ laarin awọn eeyan ẹsẹkuku ati awọn ọlọpaa pẹlu awọn oṣiṣẹ ologun to n tẹle ọkọ to gbe oku igbakeji Aarẹ naa kuro ni ilu Lilongwe lọ si ilu abinibi rẹ fun eto isinku.
Nibi aṣayan eto ti wọn ṣe fun oloogbe naa nile rẹ ni ọgọọrọ ero ti wa woran, ko to dii pe awọn kan bẹrẹ si ni ju oko lu awọn ọkọ ijọba ki wọlu-kọlu naa to bẹrẹ.
Atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita salaye pe, ọkan lara ọkọ naa ya bara kuro loju ọna rẹ, to si kọlu awọn eeyan to n kẹdun, ẹmi mẹrin si bọ lara wọn.
Agbẹnusọ fun oloogbe naa, Felix Njawala salaye bi awọn eeyan to n kedun iṣẹlẹ naa ti di oju ọna, lati poosi oku naa daada.

Oríṣun àwòrán, Malawian government
Ninu atẹjade ọhun ni ẹgbẹ oṣelu kan ti pe tako igbeṣẹ rogbodiyan naa, ati bi awọn alatilẹyin wọn yoo ti dẹkun aṣa biba nnkan jẹ laarin ilu.
Akọwe agba fun ẹgbẹ naa, Patricia Kaliati salaye wipe oloogbe Chilima lo maa n pe fun alaafia ko to ku, o gba awọn eeyan ni imọran lati gba alaafia laaye.
Igbakeji Aarẹ ilẹ Malawi, Chilima, ẹni ọdun mọkanlelaadọta ati awọn mẹjo miran lo padanu ẹmin wọn ninu baalu ileeṣẹ ologun to ja sinu igbo kan lapa ariwa orilẹ ede ọhun, nitori ipenija ayipada oju ọjọ.
Iroyin fidi ẹ mulẹ pe, oloogbe naa ni ibaṣepọ to gun rege pẹlu awọn eeyan, ni pataki julọ awon ọdọ.
Ẹgbẹ oselu ti oloogbe Chilima lo ko ara wọn jọ sọtọ gegẹbi ẹgbẹ amugbalẹgbẹ pẹlu ijọba Aarẹ Lazarus Chakwera, lẹyin to jawe olubori nibi eto idibo to waye lọdun 2020.
Ni bayii, pupọ ninu awọn alatilẹyin Chilima ti bẹrẹ si ni sọrọ tako ọwọ ti ijọba ilẹ Malawi fi mu eto isinku naa, nipa eeyan mẹrin miran to ku .
Aarẹ ilẹ Malawi, Ọgbẹni Lazarus Chakwera ti ṣeleri lati ṣewadi ohun to ṣokunfa iṣelẹ naa.
Bàálù tó gbé igbákejì ààrẹ Malawi, di àwátì lójú òfurufú

Oríṣun àwòrán, Malawian Government
Baalu to gbe igbakeji aarẹ orile-ede Malawi, Saulos Chilima, ati eeyan mẹ́sàn-àn mii, ti di awati.
Ileeṣẹ aarẹ sọ ninu ikede kan pe baalu ọhun to jẹ ti ileeṣẹ ologun orile-ede Malawi, ni wọn ko gburo rẹ mọ lẹyin to gbera kuro ni olu ilu orile-ede naa, Lilongwe, lọjọ Aje.
Igbakeji aarẹ naa n rinrin ajo lati ṣoju ijọba nibi eto isinku ọmọ igbimọ alaṣẹ tẹlẹ, Ralph Kasambara, to ku lọjọ mẹta sẹyin.
Aarẹ Lazarus Chakwera, ti paṣẹ pe ki wọn o bẹrẹ si wa wọn, ati lati doola wọn, lẹyin ti awọn oṣiṣẹ to n tọpinpin irinajo ọkọ ofurufu ko gburo baalu naa mọ.
Aago mẹwaa owurọ lo yẹ ko balẹ si papakọ ọkọ ofurufu Mzuzu, ni Ariwa orile-ede ọhun.
Nitori iṣẹlẹ yii, Aarẹ Chakwera fi da irinajo rẹ si Bahamas duro.
A ṣi n ṣe akojọpọ iroyin yii lọwọ. Ẹ tẹti leko.















