Òṣìṣẹ́ aláàbò orí omi lorílẹ̀èdè Greece ju àwọn aṣàtìpó sínú omi - Àwọn ẹlẹ́rìí sọ̀rọ̀

Iṣẹlẹ iku ọpọlọpọ awọn arin rin ajo ori omi to ti waye ni nkan bi ọdun mẹta sẹyin nilu Greek ni awọn eeyan tọrọ naa ṣoju wọn ti sọ pe awọn oṣiṣẹ aabo ori omi lo mọọmọ fi wọn soko jabọ latinu ọkọ.
Iwadi ti BBC ṣe fidi ẹ mulẹ pe, Awọn arin rin ajo bii mẹsan to ṣẹṣẹ faragba iṣẹlẹ ọhun lo wa lara awọn bii ogoji to kọkọ ku, nipasẹ jiju jabọ tipa tipa latinu ọkọ, tabi awọn to jade latinu omi lẹyin ti ọkọ de ebute.
Ileesẹ to wa fun aabo ori omi ni ilẹ Greek sọ fun oniroyin BBC wi pe, awọn ko faramọ ẹsun naa rara.
Ọjọ ti pẹ ti wọn ti n fi ẹsun fifi tipa tipa da awọn arin rin ajo pada kọ ijoba ilẹ Greek lọrun, ṣugbọn igba akọkọ ree ti BBC yoo ṣe iwadi lori ọrọ.
Iwadi fihan pe iṣesi awọn oṣiṣẹ aabo ori omi ibẹ lo ṣokunfa iku ọpọ awọn arin rin ajo naa.
Ninu alakalẹ iṣẹlẹ marundinlogun ọtọọtọ ti wọn ṣe agbeyewo le lori, laarin osu karun ọdun 2020- 2023, ni iṣẹlẹ iku awọn eeyan mẹtalelogoji waye, nitori aiduro re eto ibara ẹni sọro abẹle ati awọn ajọ ti ko gbarale ijọba pẹlu ijọba ile Turkey.
Ninu eyi, pupọ ninu awọn ti iṣẹlẹ soju wọn lo di awati bẹẹ ni ibẹru pa awọn kọọkan lẹnu mọ, ṣugbon diẹ lara wọn ba BBC sọrọ ninu iṣẹ iwadi miran.
Marun un lara awọn arin rin ajo naa salaye wi pe, awọn alabojuto eto aabo lori omi tilẹ Greek lo ju wọn jabọ si okun latinu ọkọ.

Ọkunrin ọmọ ilẹ Cameroon kan mẹnuba, bi ọwọ sikun awọn oṣiṣẹ aabo ori omi naa ti tẹ oun ni ebute Samos losu kesan ọdun 2021.
Ọpọ to ba BBC sọrọ to ka sii, bi wọn ti n gbiyanju lati foruKọ silẹ lati beere fun aṣẹ bi wọn yoo ti maa ṣe atipo lọdọ ijọba ilẹ Greek, ṣugbọn ti awọn agbofinro to daṣọ bo oju si fi pampẹ ofin gbe wọn.
Okunrin ọmọ ilẹ Cameroon ọhun sọ pe, ninu awọn mẹta ti wọn mu ni okunrin ọmọ ilẹ Ivory Coast kan wa, nipa bi wọn ṣe gbe wọn sinu ọkọ ori omi ti Greek, ti iṣẹlẹ naa ti pa wọn lara gidi gan nibẹ.
O ni, wọn kọkọ ju ọkan lara wọn sinu omi nigba ti ekeji si n pariwo, mii fẹ ku, ṣugbọn ti omi ti boo lori mọlẹ.
Awọn o ṣoju mi koro naa salaye pe, awọn to ji wọn gbe fi iya to nipọn jẹ wọn, ko to dii pe wọn ju wọn sinu omi lai wọ aṣọ adaabo boni sọrun, ṣugbọn wọn ri oku awọn meji ni ebute ilẹ Turkey.
Nibayi, awọn agbejọro fun ẹni ori ko yọ naa ti n pefun bi ijọba ilẹ Greek yoo ti ṣi iwe ẹsun ipaniyan lori awọn iṣẹlẹ naa.















