Ikú kẹ̀, mo kú tì, lákọ ni mo wà bí ìbọn – Ààrẹ tẹ́lẹ̀ Olusegun Obasanjo sọ̀rọ̀ lórí àwọn tó ń gbé ìròyìn ikú rẹ̀ kiri

Olusegun Obasanjo wọ ẹwu pẹlu fila ati igo loju rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Olusegun Obasanjo ti sọ pe kampe loun wa bayii lẹni ọdun mọkandinlaadọrun, ati pe oun ko tii ṣetan iku lasiko yii.

Obasanjọ lo sọ ọrọ naa nibi eto kan ti wọn ṣe fun niluu Abeokuta lati ṣe ọjọ ibi ọdun mọkandinlaadọrun rẹ loke eepẹ.

Baba iyabo sọ pe irọ ni awọn iroyin kan to n lọ ni igboro pe oun ti kọ lẹta kan to n ṣafihan pe ọjọ oun ti sunmọ etile.

Nibi eto naa ni wọn ti ṣe idanilẹkọ kan ti akọle rẹ jẹ "Burden and Blessing of Leadership: Reflections from Global Africa to the World."

Obasanjo ti wọn bi lọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun 1937 sọ pe oun gbagbọ pe Ọlọrun ni eto rere fun oun lo jẹ ko da ẹmi oun si di akoko yii.

O tun sọ pe irọ ni ohun to wa ninu lẹta kan ti awọn eeyan kan n pin kiri ori ayelujara pe ojojo ko ṣe ogun oun, ṣaka si ni ara oun da.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ bẹẹ kiri nipa oun kan n fi akoko ara wọn ṣofo lasan ni.

O ni oun yoo wa laaye ati ni alaafia titi di ọjọ Eledua ba sọ pe akoko oun ti to.

Aarẹ Naijiria nigba meji ọtọtọ naa sọ pe "Kampe ni mo wa."

O fi kun pe oun gbagbọ pe Ọlọrun ni eto rere fun ẹda, bẹẹ ni kii ṣe aṣiṣe ninu ọrọ ọmọ eniyan.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, alaafia ti oun wa pẹlu ọjọ ori oun n ṣapẹrẹ pe Ọlọrun ni eto rere fun aye oun.

O ni "Mo fẹ pe akiyesi yin si ọrọ awọn kọlọrọsi ẹda kan, wọn gbe ayederu iwe kan jade pe emi ni mo kọ lati sọ asọtẹlẹ nipa iku mi.

"Ero wọn si mi niyẹ amọ iyẹn kii ṣe ero Ọlọrun fun mi… Ọlọrun yoo ba mi da seria fun gbogbo awọn to n ro iku ro mi. Kampe ni mo wa bi mo ṣe maa n wa."