Èèyàn 274 ni Israel ṣekúpa ní Nuseirat - Hamas

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ẹka to n risi eto ìlera Hamas ni eeyan 274 to jẹ ọmọ ilẹ Palestine pẹlu awọn ọmọde ni ikọ ologun Israel ṣekupa ninu Ikọlu ti wọn ṣe si ibudo kan lati doola awọn eeyan to wa ni ahamọ.
Lọjọ Satide, ọjọ kẹjọ oṣu kẹfa ọdun 2024 ni ikọ ologun Israel kọlu awọn ọmọ ologun Hamas ni Nuseirat níbi tí wọn tu awọn ẹlẹwọn mẹrin silẹ.
Ikọ ologun Israel ni o to eeyan ọgọrun un to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ṣugbọn Iwadii ti awọn alasẹ Gaza fi lede ni eeyan 274 ni awọn ologun Israel ṣekupa nibi Ikọlu naa
To ba jẹ pe otitọ ni pe eeyan 274 lo ba iṣẹlẹ naa lọ gẹgẹ bii awọn alasẹ Gaza ṣe gbe sita, Ikọlu naa yoo jẹ eyi to buuru ninu itan ogun.
Ile iwosan Al-Aqusa ati Al-Awda ni o le ni aadọrin oku eeyan ti wọn ti ri lẹyin Ikọlu naa.
Ni bayii, ẹka ìjọba Hamas to n risi eto ìlera ti fi orúkọ eeyan mẹrindinlaadọrun sita lara awọn eeyan 274 ọmọ Palestine ti wọn padanu ẹmi wọn lasiko Ikọlu naa.
Eeyan mẹrin gba itusilẹ kuro ni ahamọ Ikọ ologun Hamas

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn eeyan mẹrin ti Ikọ ologun Hamas jigbe ni wọn ti wa pẹlu awọn mọlẹbi wọn lẹyin ti Ikọ ologun Israel gba silẹ níbi Ikọlu kan ti ogunlọgọ eeyan ti padanu ẹmi wọn.
Noa Argamani, 26, Almog Meh Jan, 22, Andrei Kozlov, 27 ati Shlomi Ziv, 41, ní orí ko wọn yọ lọjọ Satide lẹyin oṣu mẹjọ tí ikọ ologun Hamas tí jí wọn gbe níbi ayẹyẹ orin Nova lọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2023.
Ikọ ologun Hamas pẹlu ado oloro ofurufu kọlu ikọ Hamas ni Nuseirat ti wọn si do ju ija kọ ara wọn.
Awọn alasẹ Palestine ni obìnrin ati ọmọde wa lara awọn to padanu ẹmi wọn lasiko Ikọlu naa.
Olootu ìjọba Israel, Benjamin Netanyahu ti wa kan sara si ileeṣẹ ologun fun bi wọn ṣe gba awọn mẹrin naa kuro ni ahamọ.
"A ko ni dakẹ titi a yoo fi pari isẹ yii, ti a yoo si tun ri pe a gba gbogbo awọn eeyan wa kuro ni ahamọ."

Oríṣun àwòrán, Reuters















