Bí EFCC ṣe ń kó àwọn èèyàn sí àhámọ́ lọ́nà àìtọ́ tako ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn - Àwọn ọ̀dọ́ yarí

Awọn ọdọ to n fẹhonu han

Ogunlọgọ awọn ọdọ pejọ si Agbegbe Alagbaka ni ilu Akure lati ṣe iwọde tako igbesẹ EFCC bi ajọ naa ṣe sakọlu si awọn ilẹ ariya meji lopin ọsẹ to kọja.

Awọn ọdọ naa ni wọn bẹrẹ iwọde yi lati First Bank ni Alagbaka ti wọn si pari rẹ si ofisi Gomina n'ilu Akure.

Awọn ọdọ ọhun ke si ijọba lati fopin si iwa ipa ti EFCC n lo lati mu awọn eniyan, bi wọn ṣe sapejuwe igbesẹ awọn ikọ EFCC gẹgẹ bi eyi ti o tako ẹtọ ọmọ eniyan labẹ ofin.

Awọn ọdọ naa kẹsi ijọba lati fopin si iwa ipa ti EFCC n lo lati mu awọn eniyan

Awọn ọdọ to n se iwọde

"Bí EFCC ṣe lu àwọn èèyàn, gba dúkíà wọn kò bojumu"

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, ọkan lara olori awọn ọdọ nipinlẹ Ondo Oluwaseun Ogunmola sọ pe ikọlu ikọ EFCC naa jẹ ohun ti ko bojumu, o si pe fun itusilẹ awọn ọdọ ti wọn fi panpẹ ọba mu naa.

Ajafẹtọ awọn ọdọ l'Ondo, Yemi Fash, sọ pe EFCC nilo lati maa ṣe iṣẹ wọn lọna ti o bofinmu.

O salaye rẹ pe, awọn ikọ EFCC naa tẹ ẹtọ awọn eniyan loju mọlẹ bi wọn ṣe nawọ lilu si ọpọlọpọ awọn obinrin to wa nibẹ ati bi wọn se gba nnkan ini awọn eniyan ni asiko naa.

O seleri pe awọn ọdọ nipinlẹ Ondo ko ni faaye gba iru iwa kotọ yi, ti wọn yoo si ri daju pe wọn gba gbogbo ohun ini awọn eniyan ti wọn gba pada, ti wọn yoo si gba itusilẹ awọn ti wọn ko lọ si ilu Ibadan.

Awọn ọdọ to n se iwọde
Aworan afurasi ọmọ Yahoo

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook

Ọ́pọ̀ ọ̀dọ́ fẹ́ ṣe ìwọ́de l‘Akure tako EFCC lórí bó ṣe ya wọ òde àríyá láti mu àwọn afurasí ọmọ Yahoo

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, awọn ọmọ Naijiria kan ti ko ara wọn jọ bayii lati ṣe iwọde tako bi ajọ EFCC ṣe fi ọwọ ofin mawọn afurasi onijibiti ori ayelujara 127 ti ọpọ mọ si ọmọ Yahoo lode ariya ti wọn ti n gbafẹ meji niluu Akure ni ipinlẹ Ondo lọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja.

Ọpọ awọn to n gbero lati ṣe iwọde yii lo ti n pin fọto kaakiri ori ayelujara nipa akoko ati ibi ti wọn fẹ lo fun iwọde ọhun.

Oluyemi Fasipe to jẹ ọkan lara awọn eeyan to fẹ ṣe ifẹhonuhan yii fi lede loju opo X rẹ pe laago meje aarọ ọjọ Aje ọjọ kẹwaa oṣu Kẹfa ọdun 2024 yii lawọn o pade lagbegbe Agbalaka niluu Akure fun iwọde naa.

‘’Wọn lu awọn eeyan ti ko din ni ọdunrun un to wa ni ile ariya naa, wọn si tun yin tajutaju si wọn."

Fasipe ṣalaye fun iwe iroyin ori ayelujara, Gazette, pe nigba ti awọn eeyan n gbafẹ ni ode ariya lọwọ ni awọn ọkunrin kan ṣadeedee ya wọle pelu ibọn lọwọ wọn ti wọn si tun fi aṣọ boju wọn.

O ni bayii ni wọn bẹrẹ si ni lu awọn eeyan to wa lode ariya naa ti wọn si sọ fun wọn pe ki gbogbo wọn dọbalẹ.

Ọgbẹni Fasipe ni bayii ni wọn wọ inu ile itura naa lọ ti wọn ṣi n yin tajutaju.

‘’Wọn lu awọn eeyan ti ko din ni ọdunrun un to wa ni ile itura naa, wọn si tun yin tajutaju si wọn.

Wọn tun ba CCTV kamẹra ile itura naa jẹ, wọn si tun gbe e lọ.

EFCC tun gbe ọkọ ọpọ eeyan to wa ni itura naa lọ.

Awọn ẹṣọ EFCC yii tun gba foonu gbogbo awọn ọmọbinrin to wa ni ilura naa.

@Mosky101 naa sọrọ loju opo X rẹ pe asiko ti to lati fopin si iwa ipa EFCC si araalu.

Oun naa sọ pe agbegbe Agbalaka ni iwọde naa yoo ti waye ni ago meje aarọ ọjọ Aje niluu Akure.

Aworan iwe iwọde

Oríṣun àwòrán, Oluyemi Fasipe/X

A o huwa ipa si ẹnikẹni nibi ti a ti mu awọn afurasi ọmọ Yahoo l’Ondo - EFCC

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin ti awọn eeyan kan ti n sọ lori itakun ayelujara pe awọn ẹṣọ EFCC huwa ipa sawọn ti wọn mu lode ariya niluu Akure, ajọ naa ti sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ rara.

EFCC ṣalaye loju opo Facebook rẹ pe iṣẹ iwadii tawọn ṣe lo gbe awọn lọ si ode ariya meji niluu Akure nibi tawọn ti fọwọ ofin mawọn afurasi onijibiti ori ayelujara.

Ajọ EFCC ni ko si ọkan kan ninu awọn ẹṣọ ajọ naa to huwa ipa tabi dunkoko mọ ẹnikẹni nibẹ.

EFCC ṣalaye pe iyalẹnu lo jẹ bi awọn kan ti n pin fidio to n ṣafihan obinrin meji ti apa ẹgba wa lara wọn kiri lori ayelujara.

Ajọ EFCC ni irọ to jina si ootọ ni fidio yii, o ṣi ṣeeṣe ko jẹ agbelẹrọ fidio.

Ajọ fiku ọrọ rẹ pe irọ mii tawọn eeyan kan tun n gbe kiri ni pe EFCC yin tajutaju nibi ti wọn fi fọwọ ofin mawọn afurasi onijibiti ori ayelujara naa.

Ajọ naa sọ pe awọn to mọ nipa bi EFCC sẹ n ṣiṣẹ mọ pe awọn ẹṣọ ajọ naa kii yin tajutaju lẹnu iṣẹ wọn.

Bakan naa ni EFCC tun sọ pe awọn ẹṣọ ajọ naa ko fọwọ kan ẹrọ CCTV kamẹra to wa nile itura ọhun.

Lakootan, ajọ EFCC fidi rẹ mulẹ pe bi awọn ṣe n ṣiṣẹ awọn ko pe fun fifi iwa ipa mu afurasi tori ajọ naa bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan araalu.

Skip Facebook post, 1
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post, 1

Aworan awọn afurasi ọmọ Yahoo

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook

Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí EFCC ya wọ òde àríyá àwọn afurasí ọmọ Yahoo 127 l’Ondo

Ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria ti fọwọ ofin mu afurasi onijibiti ori ayelujara 127 ti ọpọ mọ si ọmọ Yahoo ni ode ariya wọn niluu Akure ni ipinlẹ Ondo lọja Abamẹta.

Gẹgẹ bi atẹjade ti EFCC fi lede loju opo Facebook ati X rẹ, ni ode ariya ti wọn n pe orukọ rẹ ni ‘’Signature’’ ati Abah Clubs’’ l’Akure ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi 127 ọhun.

EFCC ṣalaye pe iṣẹ iwadii fihan pe Ọjọru ọjọ karun un oṣu Kẹfa yii ni wọn fẹ ṣe ariya naa tẹlẹ.

Amọ, wọn sun un siwaju si ọjọ Satide nigba ti wọn ro pe awọn ẹṣọ EFCC le ma raye lati tọpinpin wọn.

EFCC ni awọn afurasi ọhun ti n ṣe iranwọ fawọn ẹṣọ ajọ naa lori iṣẹ iwadii wọn.

Lara awọn nnkan ti ajọ EFCC gba lọwọ awọn afurasi naa nibi ode ariya ọhun ni ọkọ olowo nla mẹwaa, ẹrọ ibanisọrọ.

Awọn nnkan mii ti EFCC tun gba lọwọ wọn ni ẹrọ kọmputa, alupupu, ago ọwọ atawọn oniruuru iwe to lodi sofin.

EFCC ni gbogbo awọn afurasi mẹtadinlaadoje yii pata ni yoo foju ba ile ẹjọ ti iwadii ba ti pari lori wọn.