A gbàgbọ́ pé Tinubu yóò buwọ́lu N250k bíi owó oṣù tó kéré jù - Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́

Aworan Aarẹ Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Presidency

Bi awọn ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria ṣe n retí esi nípa owo oṣu tuntun lati ọdọ Aarẹ Tinubu naa ni awọn araalu n gbe ojú soke.

Igbimọ to ṣíṣẹ lori ọrọ owo oṣu tuntun ti setan lati fun Aarẹ Tinubu ni ohun ti wọn pinnu le lori ọrọ owo oṣu tuntun.

Pinnu naa, eyi to n gbero N62,000 gẹgẹ bii owo oṣu tuntun ni awọn alasẹ ẹgbẹ osisẹ ti kọ lati tẹwọgba, wọn ní awọn gba kere ju ni N250,000 gẹgẹ bii owo oṣu to kere ju.

"N62,000 ko ka nkankan lasiko ti a wa yii, kii se nnkan ti Aarẹ sọ lasiko to gba agbara ree"

Nigba to n sọrọ, igbakeji Aarẹ TUC, Tommy Okon ni ẹgbẹ naa se atilẹyin fun N250,000 gẹgẹ bii owo oṣu tuntun nitori owo naa ni agbára lati ka isoro ọrọ aje to mẹhẹ lorilẹede Naijiria lasiko yii.

Okon ni oun ni igbagbọ pe Aarẹ Tinubu yoo se ohun ti awọn osisẹ n fẹ, ti yoo si buwọlu owo oṣu tuntun ti ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria n bere fun.

"Ko si nnkan to jọ mọ pe a fẹ ero wa pada lori owo oṣu tuntun N250,000.

"Ẹ jẹ ki Aarẹ gbe igbesẹ. A ti sọ nnkan ti a fẹ. N250,000 ni a fẹ gẹgẹ bii owo oṣu to kere ju.

"A n se iranlọwọ fun ijọba nitori nigba ti Aarẹ Tinubu kede pe ko si owo iranwọ epo bẹntiroolu mọ, o se ileri pe oun yoo fowo kun owo oṣu osisẹ lati le gbe igbeaye rere.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ti ẹ ba owo ti ìjọba fẹ san to jẹ N62,000, ko ka nkankan lasiko ti a wa yii, ko si gbọdọ jẹ nnkan ti Aarẹ sọ lasiko to tẹwọgba agbara ree.

Agbẹnusọ ẹgbẹ osisẹ, Benson Upah ni ijọba apapọ ko kọ bí ara sí ijororo owo oṣu tuntun ati awọn ko ti fẹnu ko lori ọrọ naa.

Upah ni ẹgbẹ osisẹ ko setan lati tẹwọgba N62,000 ti Aarẹ n fi lọ wọn gẹgẹ owo oṣu tuntun.

"Ko si adehun kankan laarin wa, ìjọba ko kọ bi ara si ijororo yii."

Bẹẹ ba gbagbe, Ijọba apapọ lorilẹede Naijiria fi ẹgbẹrun mẹta kun owo ti wọn gbe siwaju ẹgbẹ osisẹ lọsẹ to kọja, to fi jẹ 60,000 lati 57,000 ninu ipade lọjọ Isẹgun ọjọ kejidinlogun oṣu karun un ọdun 2024.

Bakan naa ni awọn olori ẹgbẹ osisẹ NLC ati TUC naa mu adikun ẹgbẹrun mẹta ba iye owo oṣu ti wọn gbe siwaju ijọba apapọ lọsẹ to kọja to fi jẹ N250,000.

Ọjọ karun un oṣu kẹfa ọdun 2024 ni Apapọ awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ kede pe awọn ti fi opin si iyanṣẹlodi alainigbedeke ti wọn gunle

Amọ igbimọ kan yoo ṣi jiroro fun ọsẹ kan gbako, lati fẹnuko lori iye owo ti yoo tẹ ijọba ati awọn oṣiṣẹ lọrun.

Ẹ kọ̀wé fípò sílẹ̀, ti ẹ kò bá le san owó oṣù tuntun - Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ sí àwọn Gómìnà

Aworan egbe osise ati egbe awon Gomina lorileede Naijiria

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria NLC ati TUC tí fẹsun kan ẹgbẹ awọn Gomina lorilẹede Naijiria pe wọn ní erongba buburu si jiroro ọrọ owo oṣu tuntun to n lọ lọwọ.

Bẹẹ ba gbagbe, ẹgbẹ awọn Gomina lorilẹede faake kọri pe awọn ko ni agbara lati san owo oṣu #60,00ọ b fun awọn osisẹ nipinlẹ wọn.

Ninu atẹjade tí Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Halimah Ahmed fi lede fun awọn akọroyin, awọn Gomina ni owo naa pọju agbara wọn lọ, ti ko si le fẹ sẹ mulẹ.

Ẹgbẹ Gomina tun fikun pe tí ìjọba apapọ ati ẹgbẹ osisẹ ba fẹnu ko lori #60,000 gẹgẹ bii owo oṣu tuntun, ọpọ awọn ipinlẹ ni ko ni le san owo naa fun awọn osisẹ wọn.

Ẹwẹ, ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria ni gbogbo ohun ti wọn bẹrẹ fun ni kí ìjọba ṣe lori ọrọ owo oṣu tuntun tí Gomina tí ko ba le san owo oṣu naa kọwe fipo silẹ.

Igbakeji Aare TUC, Tommy Etim ba Ileeṣẹ iroyin The Punch sọrọ;

"Gbogbo nnkan to jọ mọ owo oṣu tuntun ni o gbọdọ wa si imusẹ.

"Fun awọn Gomina, a ti la han wọn, ti wọn ko ba le san owo oṣu tuntun yii, ko kọwe fipo silẹ nitori a dibo fun wọn fun ijoba rere ko se fun ohun alumọni nìkan.

"Ni orilẹede Naijiria ti awọn Gomina tí ń sọpe #30000 pọju lati san gẹgẹ bii owo oṣu ni Gomina kan ni gbe ẹsẹ le #80bn.

"O mase, a ko ni fo igbesẹ kankan. Ẹgbẹ osisẹ yoo se ipade. A n fun Aarẹ ni anfani lati sọrọ."

Bakan naa ninu atẹjade ẹgbẹ osisẹ Labour, Benson Upah fi lede, o ni awọn gbagbọ pe awọn Gomina lorilẹede Naijiria gbe igbesẹ naa pẹlu erongba buburu.

"Pẹlu nnkan ti wọn sọ, ko si nnkan to le le wa kuro nibi otitọ nitori afikun tí wa fun owo FAAC awọn Gomina lati #700bn sì 1.2trn, eyi to fihan pe owo n bẹ lọwọ awọn Gomina

Aworan

Oríṣun àwòrán, X/Nigeria Gov Forum