Ọwọ́ NDLEA tẹ àwọn arin ìrìnàjò Mecca pẹ̀lú oògùn olóró l'Eko

Oríṣun àwòrán, NDLEA
Ajọ to n gbe ogun ti egbogi oloro lorilẹede Naijiria NDLEA ti fi isinku ofin mu eeyan mẹrin to n gbero lati lọ ile milọ pẹlu oogun oloro cocaine lọjọru., Ọjọ karun un, Oṣu kẹfa ọdun 2024.
Nigba to n ṣalaye bi ọwọ tẹ awọn afurasi naa ninu atẹjade to fi lede niluu Abuja, Agbẹnusọ fun Ajọ NDLEA, Femi Babafemi ni awọn ọmọ ogun NDLEA yawọ ile itura Emerald ni agbegbe Ladipo ni Oshodi nipinlẹ Eko nibi ti awọn arin irinajo naa duro saaju irinajo wọn.
O ni orukọ awọn afurasi naa ni, Usman Kamorudeen, 31; Olasunkanmi Owolabi, 46; Fatai Yekini, 38; ati obinrin kan, Ayinla Kemi, 34.
Awọn afurasi naa lo duro sinu yara meji ninu ile itura naa nibi ti wọnh ti n gbero lati mi egbogi olori cocaine si ikun ko to di pe awọn ọmọ ogun NDLEA ya wọ le.
O le ni igba cocaine ti wọn ka mọ awọn afurasi naa lọwọ eyi ti gbaradi lati gbe mi.
Alaga ajọ NDLEA, Brig Gen Mohamed Marwa ti wa kan sara si awọn ọmọ ogun nipinlẹ Eko fun iṣẹ taku takun ti wọn n gbe sẹ lati gbe ogun ti lilo ogun oloro lawujọ.
O tun gbe oriyin fun wọn bi wọn mu awọn afurasi ọdaran ti wọn n fi irinajo Mecca boju lati se iṣẹ ibi to n ṣe akoba nla fun orilẹede Naijiria.
Marwa tun fikun pe ajọ NDLEA yoo siṣẹ pọ pẹlu awọn akẹgbẹ wọn lati ri pe ọwọ tẹ eeyan ti wọn ti wa lorilẹede Saudi pẹlu ogun oloro naa, ti ofin yoo si fiya jẹ wọn.

Oríṣun àwòrán, Screenshot















