“Ọyàn mi ti n tóbi jù ni mo ṣe fọ̀ọ́ nílànà ìbílẹ̀, mo sì rí ìyàtọ̀”

Àkọlé fídíò,
“Ọyàn mi ti n tóbi jù ni mo ṣe fọ̀ọ́ nílànà ìbílẹ̀, mo sì rí ìyàtọ̀”

Ǹjẹ́ ẹ̀ mọ̀ pé ó ní bí wọ́n ṣe máà n fọ ọyàn obìnrin nílẹ̀ Yorùbá, láti mú kó kérè tàbí yọ àwọn kòkòrò tó bá wà nínú rẹ̀?

BBC Yorùbá bá ọ̀dọ́mọbìnrin Kismotulahi Oteniara, àti àwọn ìyá alágbòo tó má n fọ ọyàn sọ̀rọ̀.

Arabinrin Oteniara ṣalaye pe nigba ti ẹbi oun rii pe ọyan oun ti n tobi ju, wọn ro pe boya oun n lo nnkan lati jẹ ko maa tobi.

Eyi lo mi wọn gbero pe ko fọ ọyan naa ni ilana ibilẹ, nitori o ṣeeṣe ko jẹ kokoro ọyan lo jẹ ko maa tobi.

Fifọ naa ni igbagbọ wa pe yoo mu adinku ba ọyan to n tobi.

Ọmọbinrin naa sọ pe ṣaaju ki oun to fọ ọyan, niṣe lo n tobi ju ọjọ ori oun lọ

Nigba to de ibi ti yoo ti fọ ọyan naa, ni wọn sọ fun pe kokoro wa ninu ọyan naa.

Kismotulahi sọ pe iṣẹ ọyan fifọ ni iya-iya oun n ṣe nilu Ilorin, iya naa lo si ba fọọ.

Ẹnikan lara awọn to n fọ ọyan, to tun jẹ alagbo, Arabinrin Ramat Olonde, sọ fun BBC pe, kokoro ọyan ma n fa ki ọyan maa yun ẹni to ba nii.

“Ṣugbọn to ba ti gbe wa si ọdọ awa ti a jẹ oniṣẹ ibilẹ, a maa n ba wọn fọ danu.

Kini imọ sayẹnsi sọ nipa ọmu fifọ?

Dokita Habeeb Lawal, to jẹ igbakeji oludari eto ilera ni ileewosan ijọba ipinlẹ Kwara, sọ pe aṣa naa ko fidimul ninu imọ sayẹnsi.

O ni lootọ ni awọn ara atijọ maa n sẹ iru nnkan bẹẹ, nitori pe ibi ti imọ wọn de duro nigba naa niyẹn.

Dokita Lawal sọ pe ọyan fifọ ma n mu ki ori ọyan ko gbẹ, eyi to le mu ipalara ba obinrin to n fun ọmọ lọyan.