Njẹ́ o mọ̀ pé ewu wà fún àwọn tó máa n la ẹnu sílẹ̀ lójú oorun? Ìdí abájọ rèé

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọdé lóde òní ló máa ń la ẹnu sílẹ̀ tí wọ́n bá ń sùn gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ṣe fi hàn lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.
Ọ̀pọ̀ òbí àti alágbàtọ́ ni kìí ka ìwà yìí kún tàbí ròó wí pé ó le ni àwọn ìjàmbá tó le fà fún àwọn.
Ìwádìí BBC News Brazil fi hàn wí pé kí ènìyàn máa la ẹnu sílẹ̀ tí ó bá ń sùn léwu fún àgọ́ ara lọ́pọ̀lọpọ̀.
Lára àwọn àkóbá tí kí ènìyàn máa la ẹnu sílẹ̀ lójú orun le ṣe ni pàápàá fún àwọn ọmọdé ni ẹnu rúrùn.
Ìwádìí fi hàn wí pé ẹnu rúnrùn yìí tí wọn kò bá tètè mójúto ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ le ṣe bẹ́ẹ̀ bá irú ọmọ náà dàgbà.
Kódà ó tún le ṣe àkóbá fún bí ọpọlọ ọmọ ṣe lè jí pépé sí àti bí ó ṣe le mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ rẹ̀ tó.
Àwọn àkóbá tí líla ẹnu sílẹ̀ le ṣe fún ọmọdé àti àwọn ọ̀nà láti mójúto nìyí:
Kíkó ìdọ̀tí sí àgọ́ ara
Gẹ́gẹ́ bí imú ṣe jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀yà tó wà fún mímí, ó ní àwọn iṣẹ́ pàtàkì tó máa ń ṣe sí èémí tí ènìyàn máa ń fà sínú kó tó dé ara.
Àwọn iṣẹ́ tí imú ń ṣe wọ̀nyìí ni ẹnu kìí ṣe tí ènìyàn bá ń fi ẹnu mí.
Onímọ̀ nípa ètò ìlera kan Alexandre Ordones ṣàlàyé fún BBC wí pé tí ènìyàn bá ń fi ẹnu mi, gbogbo àwọn ìdọ̀tí tí imú máa ń fọ̀ kó tó dé àgọ́ ara ni ẹnu kò lágbára láti ṣe.
Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló máa ń fa kí imú máa dí tí èèyà yóò sì máa ní kàtá ní gbogbo ìgbà.
Bákan náà ló máa ń da bí ojú ènìyàn ṣe yẹ kó rí rú nítorí ìjàgbọ̀n, ẹ̀ẹ̀kẹ́, ojú àti eyín kò ní dàgbà bó ṣe yẹ kí wọ́n dàgbà.
Apnea
Àwọn ọmọdé tó máa ń la ẹnu kalẹ̀ lóju oorun máa ń ní ìpèníjà ti àwọn olóyìnbó ń pè ní Apnea.
Èyí túmọ̀ sí pé ọmọ náà kò ní rí oorun sùn wọra, tí ọmọ náà yóò máa jí ní ìṣẹ́jú ìṣẹ́jú.
Èyí máa ń ní ipa tí kò dára tó lórí ọpọlọ ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà.
Ìwádìí kan tí ilé ẹ̀kọ́ Sergipe ṣe lọ́dún 2016 fi hàn wí pé àwọn ọmọdé tó máa ń la ẹnu kalẹ̀ sùn máa ń ní ìṣòrò nínú ẹ̀kọ́ wọn.
Àwọn ni wọ́n máa ń sábà kẹ̀yìn nínú àwọn akẹgbẹ́ wọn.
Kí ọmọ máa tọ̀ sílé
Nnkan mìíràn tí kí ọmọ máa la ẹnu sílẹ̀ tó bá ń sùn máa ń fà ni kí ọmọ máa tọ̀ sílé.
Nígbà tí ènìyàn bá ń sùn fọnfọn lọ́wọ́ ni ẹ̀yà ara to máa ń ṣe àmójútó ìtọ̀ máa ń jẹ́ pípèsè lára tí èyí kìí sì rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ọmọ tó bá ń lanu kalẹ̀ sùn nítorí wọ́n kìí sùn wọra.
Báwo ni ènìyàn ṣe le tọ́jú kí ọmọdé máa la ẹnu sílẹ̀ sùn?
Lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà, àwọn ènìyàn máa ń fi ẹnu mi nítorí pé imú wọn ti dí, tí nnkan tí àwọn onímọ̀ sì ṣàlàyé wí pé rhinitis ló máa ń fà á.
Gbogbo nǹkan tí kìí bá à jẹ́ wí pé ohun ló ṣokùnfà kí ọmọdé máa la ẹnu sílẹ̀ sùn, àwọn onímọ̀ gbàgbọ́ wí pé tí ènìyàn bá tètè mójúto ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ pàápàá kì ọmọ tó pé ọdún mẹ́rin yóò ṣe àǹfààní púpọ̀.
Bohadana ṣàlàyé pé kò sí ìgbà tí ènìyàn kò lè ṣe àtúnṣe yìí ṣùgbọ́n ó máa ń dára kó jẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
Ó fi kun pé ohun àkọ́kọ́ tí ó yẹ kí ènìyàn ṣe to bá ṣàkíyèsí pé ọmọ òun ń lanu sílẹ̀ sùn ni láti tọ àwọn dókítà lọ láti ṣe àyẹ̀wò fún ọmọ náà.
Lára àyẹ̀wò tí wọ́n yóò ṣe fún ọmọ náà ni láti mọ̀ bóyá nǹkan kò dí tàbí wú nínú àwọn ẹ̀yà ara ti a fi ń mí.
Ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé ògùn tàbí àmójútó àwọn nǹkan kan ni yóò tán ìṣòro yìí tàbí kí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún ọmọ náà.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn dókítà ṣe sọ iṣẹ́ abẹ ọ̀hún kìí ṣe ohun tó le rárá, kódà ọmọ náà le padà sílé ni ọjọ́ tí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ abẹ yìí tí ara rẹ̀ yóò sì yá pátápátá lẹ́yìn ọjọ́ méje.












