Wo àǹfàní mẹ́wàá tó wà nínú ẹyin jíjẹ

Aworan ọwọ to mu ẹyin dani

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ọkan lara awọn ounjẹ aṣaraloore ti Ẹlẹdaa fi jinki ẹda eniyan ni ẹyin.

Awọn to fẹ sanra ati awọn ti wọn fẹ din ara sisan ku, gbogbo wọn ni wọn n jẹ ẹyin.

Ibeere kan lo wa ṣe pataki, eyi ni pe ṣe ounjẹ gbogbo igba ni ẹyin ni abi keeyan maa jẹ lẹẹkọọkan tori ọra to pọ ninu rẹ?

Ka iroyin yii lati mọ boya ẹyin jijẹ dara fun ọ tabi bẹẹ kọ.

Kíni ó wà nínú ẹyin?

Ti a ba se ẹyin adiyẹ kan ṣoṣo, o kun fun awọn eroja wọnyii:

72 kcal / 298 KJ

7,0 g of protein

4,8 g of fat

1,4 g of saturated fat

1,8 g of monounsaturated fat

0,8 g of polyunsaturated fats

15 mcg de folate

1,6 mcg of vit D.

Protein ninu ẹyin: Eroja Protein mẹsan-an ti ara nilo wa ninu ẹyin kan ṣoṣo. Yoo si ṣiṣẹ fun idagbasoke ati atunṣe ara.

Awọn ẹwa, ẹpa, agbado tabi irẹsi ko le fun wa ni eroja pipe ti ẹyin ni, nitori protein ara tiwọn ko to mẹsan-an bii ti ẹyin.

Ẹyin tun jẹ olupese 'vitamin B12,' eroja aṣaraloore ta a mọ si iron ati omega-3 fatty acids.

Gbogbo eyi lo jẹ ki ẹyin dara fawọn eeyan ti wọn ki i jẹ ẹran rara (Vegetarian diet).

Àǹfààní mẹ́wàá tó wà nínú ẹyin jíjẹ

Aworan ẹyin dindidn ati ewe ninu awo

Oríṣun àwòrán, Getty image

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

1. Ẹyin kun fun eroja ti ara nilo

Awọn eroja kan wa ti ara nilo ṣugbọn ti wọn ko dẹrun lati ri ninu ounjẹ, awọn eroja bii vitamin D ati B 12.

Ti eeyan ba n jẹ ẹyin, yoo ri awọn eroja naa ni irọrun, yoo si tun jẹ anfaani vitamin A ati E.

2. Olùpèsè èròjà protein ni ẹyin

Bi ẹyin ṣe jẹ olupese protein fun ara naa lo tun maa n tete dà ninu. Protein inu ẹyin ju ti ẹran maaluu lọ, o si fara jọ wara.

3. Olùpèsè choline ni ẹyin

Eroja mi-in ti ara tun nilo ni Choline, oun lo n ṣiṣẹ fun ọpọlọ pipe, eroja yii si wa ninu ẹyin.

Choline yii ṣe pataki fun alaboyun, ati fun obinrin to n fun ọmọ lọmu lọwọ, nitori iṣẹ rẹ yoo han lara ọpọlọ ọmọ.

4. Ẹyin jijẹ ń ran ọkàn lọ́wọ́

Iṣẹ iwadii kan lorilẹ-ede China, fidi rẹ mulẹ pe, jijẹ ẹyin ẹyọkan lojumọ le dena aisan ọkan ati rọpa-rọsẹ. Eyi ri bẹẹ nitori Betaine ati Choline to wa ninu rẹ.

5. Ẹyin jíjẹ fún ìlera ojú

Bi a ṣe n dagba si i, iriran wa yoo maa dinku.

Ṣugbọn pẹlu awọn eroja kan nipasẹ ounjé to pe, iriran eeyan ko ni i bajẹ raurau.

Ọkan ninu awọn ounjẹ to n ṣe iranwọ yii ni ẹyin jijẹ.

Pupa inu ẹyin kun fun eroja carotene, eyi tun ni eroja meji mi-in ti wọn n dena aarun Cataracts to maa n yọ oju lẹnu.

Bakan naa, olupese Vitamin A too daa fun iriran oju tun ni ẹyin jẹ.

6. Ó lè dènà kí iṣan ojú já

Aisan oju kan wa ti wọn n pe ni ‘sarcopenia’, eyi ni ki i iṣan to n gbe oju ro, já, tabi ko ma lagbara mọ.

Pẹlu ẹyin jijẹ, aisan yii ṣee dena.

7. Ó lè ran èèyàn lọ́wọ́ láti rí bó ṣe fẹ́

Protein pọ ninu ẹyin, iwulo rẹ pọ debii pe o le ran eeyan lọwọ lati ri bo ba ṣe fẹ.

8. Ẹyin jijẹ lè ran èèyàn lọ́wọ́ láti dín ara sísan kù

Bi ẹyin jijẹ ba wa ninu eto ounjẹ eeyan, eroja ‘Amino acid Leucine’, ida 500mg ni yoo ri. Eyi wulo fun didin ara sisan ku.

9. Ẹyin jíjẹ ń gbé àwọn ṣọ́jà ara ró

Bi a ba fi ẹyin kun awọn nnkan mimu ti a fi wara ṣe, iwadii fi ye wa pe wọn le parapọ ki wọn si maa ran awọn ṣọja inu ara (immune sysytem) lọwọ.

Eyi ko ni i jẹ ki eeyan maa dubulẹ aisan ni gbogbo igba.

10. Nínú gbogbo ẹranko tó ń pèsè èròjà Prtotein, ẹyin ni ìṣẹ̀dá rẹ̀ rọrùn jù

Ẹyin mélòó ló dáa láti jẹ lọ́jọ́ kan?

Aworan ẹyin ati ata dindin

Oríṣun àwòrán, Getty image

Apọju gbogbo nnkan ko daa. Awọn iṣẹ iwadii fi ye wa pe jijẹ ẹyin niwọntun-wọnsi lo daa ju. Wọn ni ẹyin ẹyọkan ti to lọjọ kan.

Ṣé gbogbo èèyàn ni ẹyin jíjẹ dáa fún?

Aworan tinu ẹyin ati funfun rẹ ninu ike

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ninu itan, bi o ba mu ẹyin tutu tabi ti o jẹ ẹyi ti wọn se ti ko jinna tan, wọn ni eyi le fa kokoro Salmonela.

Ṣugbọn pẹlu ayipada ti ajọ Food Standards Agency (FSA), gbe jade, wọn ni awọn ọmọde, alaboyun ati awọn agbalagba le mu ẹyin tutu, wọn si le jẹ eyi ti ko jinna tan.

Lákòótán, ṣé ẹyin jíjẹ dára fún ọ?

Aworan ẹyin dindin, tumaati ati oriṣi ounjẹ kan ninu awo

Oríṣun àwòrán, Getty image

To ba jẹ pe o maa n ri awọn apẹẹrẹ kan ti ko ba ọ lara mu bi o ba jẹ ẹyin tan, kan si dokita rẹ.

Ṣugbọn bi ohunkohun ko ba ki n ṣe ọ lẹyin jijẹ ẹyin, a jẹ pe alaafia ni fun ọ.