Mọ̀ sí i nípa Ìlúbìnrin, níbi tí àwọn obìnrin kò ti gbà fún ọkùnrin

Aworan Obinrin lati Mexico

Oríṣun àwòrán, Getty images

    • Author, José Carlos Cueto
    • Role, BBC News Mundo
    • Reporting from, Juchitán de Zaragoza, Mexico

O ti han gbangba pe Idaniloju wa pe Ilu Mexico yoo Aarẹ akọkọ lobinrin.

Eyi jẹ aṣa ni orilẹede to wa ti tipẹ, ti wọn si n pe aṣa naa ni “macho”. Mexico jẹ ọkan ninu awọn orilẹedee ti wọn dibọ ṣekupa obinrin lagbaye.

Erongba lati jẹ ki obinrin di Aarẹ orilẹede ni Mexico ti di ohun ti ọpọlọpọ n lero ko waye kaakiri agbaye.

Awọn oludije aarẹ lobinrin, Claudia Sheinbaum, lati ẹgbẹ oṣelu to n ṣe ijọba lọwọ ati Xochitl Galves, to jẹ olori ẹgbẹ oṣelu alatako ni wọn jọ n dupo lati di Aarẹ ninu eto idibo to n bọ.

Ṣugbọn fun awọn obinrin ti o wa ni agbegbe Istmo de Tehuantepec, otitọ pe obinrin le di olori ilu ko da bi pe o jẹ ohun ti ko dara.

Ni agbegbe yii, awọn agbara obinrin ni a le pe ni “nnkan to yatọ” ni agbegbe Mexico.

Wọn jẹ ohun iwuri fun awọn oṣere ati amọye lati ṣe afihan iran to n ro awọn obinrin Mexico lagbara fun ọpọlọpọ ọdun.

Aworan Diana Manzo

'Ilu awọn Obinrin'

Griselda Martinez jẹ ọmọ bibi ilu Zapotec, ẹya kan to lagbara ju ni agbegbe Istmo de Tehuantepec. O ṣapejuwe ara rẹ bi ologun to lakikanju, to si da duro.

“Asiko ti to fun obinrin lati ṣe akoso Mexico. Ẹ jẹ ki a rii boya e le gbe ohuyn meremere se fun orilẹede wa, ”o sọ.

Agbegbe naa ni wọn tun mọ si “Istmo”, agbegbe naa wa laarin guusu Oaxaca ati Veracruz.

Map of the Istmo region

Juchitan de Zaragoza ni o jẹ "ilu awọn obinrin" ni Istmo.

Ọja to wa niluu yii fi han pe awọn obinrin lo wa ni gbogbo ẹka ọrọ aje.

Gbogbo awọn nnkan wọnyi lo jẹ ki awọn oninwadii gbagbọ pe obinrin lo ni ilu naa.

“Eyi ki se otitọ.Obinrin ati ọkunrin lo n da si eto ọrọ aje ninu ile ,” Martinez ṣalaye.

Dida owo fun ile lo dọgba, ti wọpọ bii ibomiiran ni Mexico, bo ti lẹ jẹ pe aṣa ti n yipada ni awọn ọdun diẹ sẹyin.

Itan nipa ominira awọn obinrin

Aworan obinrin kan ninu Ọja
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni ibi to n ta ounjẹ ninu ọja, Martinez sọrọ nipa itan ijagbara Istmeñas.

“Ní ọdun 90s, awọn obinrin ja pẹlu awọn ọkunrin lati tako awọn to gbe ogun ti wọn ilẹ France. A lo igi, awọn okuta ati awọn obe lati fi le wọn jade,” o sọ.

Agbegbe naa rii ọpọlọpọ ogun abele ni ọdun 90s, to sọ ọpọlọpọ obinrin di opo to nilo iranlọwọ owo lati fi tọju ile.

Ọpọlọpọ lo ni lati di onisowo to n rin irinajo lati ibi kan si ibi kan lati ri owo.

“Ijagbara waye ni bi, ti awọn obinrin si kopa.” Patricia Matus, onimọ-jinlẹ, to jẹ ọmọ bibi Zapotec lati Ile-ẹkọ giga ti Ilu Mexico ti Universidad Autónoma Metropolitana Unidad Xochimilco sọ

Orisirisi awọn eya lo gbe papọ ibi, bo ti lẹ jẹ pe awọn Zapotecs ni o ni agbara ju.

“Labẹ iṣejọba Spain, awọn Zapotecs ṣetọju idanimọ ẹya wọn ati fagile aṣa ati iṣelu Spain,” Howard Campbell, onimọ-jinlẹ lati fasiti Texas ni El Paso ṣalaye.

Awọn opitan sọrọ ni pa awọn obinrin to kopa ninu gbigbe ogun ti awọn ara Spain ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin.

“Jijẹ akikanju jẹ ohun ro wa lati ọdọ awọn baba wa,” oniroyin Zapotec, Diana Manzo sọ fun BBC.

.

Ile gbe

Aworan obinrin lati iran kan si iran mii

Awọn iye obinrin Zapotec ni o wa lati ile ti wọn si jogun rẹ nipasẹ iran kan si iran mii.

Fun awọn obinrin nibi, jija fun obinrin ko ohun ti wọn kọ sugbọn o jẹ ohun ti wọn bi mọ wọn.

Ọpọlọpọ eeyan ti a sọrọ lati ranti bi awọn iya wa ko ipa nla to fi di pe awọn sọ wọn di obinrin to n da duro, ti wọn si ma sọ pe “ma ṣe duro de ọkunrin kan kan”.

"Mo ṣe aṣeyọri lori nnkan ti mo fẹ to fun mi ni igboya lati ile. Fun ọpọlọpọ ọdun a ko ni atilẹyin ọkunrin. Awọn obirin lo n pese ti wọn si n moju to ile papọ," Michelle Lopez, to jẹ akẹkọọ to n kọ nipa osowo ṣalaye.

Pẹlu bi wọn ṣe n tan eyi mọ oṣelu ati ayipada, o sọ pe oṣelu nikan kọ irinsẹ ti wọn nilo lati pese ominira tuntun.

“Yoo dara lati ni Aare obinrin, ṣugbọn obinrin ko nilo ipo oloselu lati ni ipa. A ti fihan pe a le ṣe koriya awujọ tia si le ṣe itọsọna lai si ni ipo kankan, ”Lopez sọ.

Osẹlu sise

Awọran akẹkọọ, Michelle Lopez

Gẹgẹ bi o ṣe wa ni ọpọlọpọ orilẹede, awọn obinrin Mexico ti tiraka lati ni raye sinu agbara iṣelu.

“Sibẹsibẹ, iyasọtọ nla ni Istmo jẹ fun ọpọlọpọ,” Campbell sọ.

Lọdun 1970s, awọn Istmeñas ko ipa nla lakoko iṣọpọ ti oṣiṣẹ ti wọn mọ si COCEI.

O tako oṣelu nigba naa eyi ti Institutional Revolutionary Party (PRI) lewaju fun.

Gẹgẹ bi ohun ti Matus sọ, ẹya Zapotec ni wọn lo gẹgẹ bí ami igbegun ti ijọba.

“Ati pe agbara obinrin Zapotec wa lara nnkan ti wọn lo,” o sọ.

Lasiko Ija COCEI, ni ọdun 1981, Juchitan di ọkan ninu awọn ilu Mexico ni akọkọ ti ijọba alajọṣepọ n ṣe ijọba rẹ.

“Awọn obinrin tun pọju awọn ọkunrin lọ nigba ifẹhonuhan ati ipade. Wọn fi ebi pa ara wọn, ti wọn la ewu kọja,” Campbell sọ, ofikun pe iru iwọde yii ko wọpọ fun awọn obinrin Ilu Mexico ni ọdun 1980.

Lati igba naa, wọn yan awọn obinrin akọkọ sipo ni agbegbe naa, bo ti lẹ jẹ pe awọn iye wọn kere.

Ijiroro nipa awọn ipo obinrin ninu oṣelu

Iwa ipa si awọn obinrin jẹ ọkan ninu awọn ewu to n ṣe akoba fun Mexico.

Laarin Oṣu Kinni ati Oṣu Kẹta ọdun 2024, awọn ẹsun awọn odaran nipa sise iku pa obinrin ti le ni 184 jakejado orilẹ-ede naa. Ni awọn ọdun to lọ, wọn jẹ ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun.

Istmo de Tehuantepec ti jẹ ọkan ninu awọn agbegbe ti iwa-ipa wa si ju fun ọpọlọpọ ọdun.

Nitori eyi, ọpọlọpọ awọn obinrin agbegbe kọ aba to ni pe awujọ obinrin wa rara nibi.

Ti iyẹn ba jẹ otitọ, wọn jiyan pe awọn ko ni koju iwa ipa ati aidọgba ni gbogbo igba.

Campbell tun jiyan pe bi o tilẹ jẹ pe ijafafa iṣelu ti Istmeñas jẹ iyalẹnu, idọgbadọgba gidi ni iṣelu lati wa ni agbegbe naa, eyi ti o tun jẹ pe awọn ọkunrin lo pọju ninu oṣelu.

Rogbodiyan

Aworan obinrin kan lasiko iwọde

Ipolongo idibo yii ni wọn ti ṣapejuwe gẹgẹ bii ti rogbodiyan ti pọ ju ninu itan Mexico.

Ile-iṣẹ kan Mexico to n ṣe iwadii,Integralia sọ pe awọn oṣiṣẹ ijọba, awọn oloselu ati awọn oludije ti wọn ṣekupa tabi halẹ mọ lori idibo naa.

O ni ipo ẹgbẹrun lona ogun ti dupo fun ninu eto idibo yii.

Ni ọdun 2019, ijọba Ilu Mexico ṣeto pe ida aadọta gbogbo awọn iṣẹ ijọba ati awọn isẹ ilu ko wa ipamọ fun awọn obinrin.

Ṣugbọn awọn idojukọ si maa wa lori awọn ẹbun to jọni loju: Ipo Aare.

Pada ni ọja Istmo, ọrọ n lọ lọwo nipa awọn idibo.

“Ko ṣe pataki pe ka ni Aarẹ obinrin kan. Ohun ti o ṣe pataki ni pe o ṣe iṣẹ to dara.

“A ni ọpọlọpọ awọn obinrin ọlọgbọn ti wọn le ṣe nnkan nla fun Ilu Mexico ti wọn ba ni aye,” Martinez sọ.