Iléeṣẹ́ ológun fẹ̀sùn kan ẹgbẹ́ IPOB pé wọ́n ṣekúpa sọ́jà márùn ún, aráàlú mẹ́fà ní Abia

Aworan awọn ologun Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti kede pe awọn agbebọn kan ṣekupa ọmọ ogun marun un nibi ikọlu ojiji kan to waye nipinlẹ Abia.

Bakan naa ni wọn ni awọn agbebọn yii tun ṣekupa araalu mẹfa lasiko ti wọn kọlu awọn ologun.

Ibeere ikọ ajijagbara IPOB to lo n beere fun yiya kuro lara orilẹede Naijiria lo ti wa di lemọlemọ ni agbegbe naa.

Awọn ologun ti wa fẹsun kan IPOB pe awọn lo wa nidi ikọlu si awọn ọmọ ologun.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ologun, Ọgagun Edward Buba fi lede, o ni ikọlu naa waye ni agbegbe ijọba ibilẹ Obingwa, nibi ti awọn ọmọ ologun duro si lati ri pe alaafia jọba, ti wọn si n da abo bo awọn araalu.

O ni ko ti si ẹgbẹ kankan to jade pe awọn naa wa nidi ikọlu naa sugbọn wọn fẹsun kan awọn ikọ to digbara fun idasilẹ Biafra.

“Ileeṣẹ ologun n daro lori iku awọn ọmọ ologun to padanu ẹmi wọn.

“Iwadii n lọ lọwọ.

“Bakan naa o ṣe koko ka ṣawari awọn to ṣe ikọlu yii, ki wọn si jiya labẹ ofin.

“A ni lati gbe igbesẹ nla lati fopin si ikọ yii.”

Olori ikọ IPOB, Nnamdi Kanu, ẹni to wa ni atimọlẹ, to si tun jẹjọ fun ẹsun igbesunami

Àwọn agbébọn IPOB yìnbọn pa ṣọ́jà méjì l’áyájọ́ àwọn akọni Biafra ní Aba

Aworan bi agbegbe naa ti ri

Oríṣun àwòrán, screenshot

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn agbebọn ti pa ṣọja meji ni agbegbe Obikabia Junction ni ilu Aba, ipinlẹ Abia lẹkun ila oorun guusu Naijiria.

Nnkan bi agogo mẹsan owurọ Ọjọbọ, ọgbọn ọjọ oṣu karun un ọdun 2024 ti awọn ẹgbẹ IpoB ya sọtọ gẹgẹ bi ọjọ iranti awọn akọni ‘Biafra Day’.

Awọn agbebọn mejila ninu ọkọ meji, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ṣa dede kọlu awọn agbofinro kan lagbegbe Obikabia ti wọn si ṣina ibọn bolẹ.

Bakan naa ni wọn tun dana sun ọkọ awọn ologun naa ki wọn to sa lọ pẹlu awọn nnkan ogun wọn.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe awọn ri awọn oku ṣọja mejeeji loju popo.

Nigba ti BBC kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Abia, Maureen Chinaka, o ni ka yoo ni lati pe ileeṣẹ ologun ni nitori oun ko le gbẹnusọ fun wọn.

Akọroyin BBC to kaakiri awọn agbegbe kan ṣalaye pe ọpọ eeyan ni ko tilẹ mọ pe ayajọ naa n waye , bẹẹni wọn ko mọ si ofin gbele ẹ ti IpoB pa laṣẹ.

Awọn ologun atawọn ọlọpaati kaakiri awọn agbegbe ti awọn agbebọn IpoB ti n fi idi aṣẹ wọn mulẹ, bẹẹni awọn balu agbofinro n fo kaakiri pẹlu.

Bawo ni Idanwo WAEC ṣe n lọ pẹlu ofin gbele ẹ ti Ipob ṣe layajọ ‘Biafra Day’

Aworan ile ẹkọ kan

Idanwo aṣekagba ile ẹkọ girama WAEC n lọ lọwọ lawọn ile ẹkọ kan lẹkun ila oorun gusu Naijiria pẹlu bi ẹgbẹ IpoB ṣe kede ayajọ iranti awọn akọni Biafra.

Lara ohun ti ẹgbẹ agbebọn naa sọ ni pe ki gbogbo awọn eeyan lẹkun naa o joko sile nitori ko ni si lilọ bibọ nibẹ.

Akọroyin BBC kaakiri awọn ile ẹkọ kan lowurọ Ọjọbọ to si ri i pe awọn akẹkọọ kan n gbaradi fun idanwo wọn.

Bakan naa lo tun fi idi rẹ mulẹ pe awọn alamojuto idanwo pẹlu ti wa nikalẹ pẹlu iwe idanwo awọn akẹkọọ naa.

O ni awọn akẹkọọ onidanwo WAEC nikan lo wa si ile ẹkọ lọjọbọ, awọn akẹkọọ kilasi yoku ko wa rara.

Ki ni awọn gomina ipinlẹ lẹkun ila oorun gusu Naijiria sọ?

Awọn akẹkọọ kan n lọ si ile ẹkọ

Awọn gomina ipinlẹ kan ni ẹkun naa ti kọ ẹyin si aṣẹ konile o gbele ti IpoB pa.

Ijọba ipinlẹ Enugu, ninu atẹjade ti Ken Ugwu to jẹ agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ naa fi sita ṣalaye pe ijọba ipinlẹ naa ko fara mọ aṣẹ ẹgbẹ Ipob naa ati wi pe “wọn n gbero ati ba ọjọ ọla