Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ka ìbò lórílẹ̀èdè South Africa, ta ló ń borí?

Oríṣun àwòrán, AFP
Eto kika ibo ti bẹrẹ lorilẹede South Africa lẹyin ti awọn eeyan orilẹede naa jade dibo lọjọru.
Eto idibo naa ni ọpọ onwoye ti tọka si gẹgẹbi eyi ti awọn ẹgbẹ oṣelu ti dije ni pẹkipẹki julọ lati igba ti ẹgbẹ oṣelu Afrcan Nationa Congress, ANC ti n ṣe akoso orilẹede naa lati ọgbọn ọdun sẹyin.
Ninu esi ibo ti wọn ṣi ka, ẹgbẹ oṣelu ANC lo n lewaju pẹlu ida mejilelogoji (42%) ibo ti wọn ti i ka, ẹgbẹ oṣelu DA lo tẹle wọn pẹlu ida mẹrindinlogọgbọn (26%), ẹgbẹ oṣelu EFF ko ida mẹjọ (8%) ibo ti wọn ṣi ka lọwọ yii. Ẹgbẹ oṣelu uMkonto weSizwe (MK Party) to jẹ ti aarẹ tẹlẹ, Jacob Zuma pẹlu wa lori ida mẹjọ (8%) ibo.
O ṣeeṣe ki wọn ka apapọ esi ibo naa titi opin ọsẹ yii.
Awọn onwoye ati ọpọ araalu lo ti n fi ogun rẹ gbari pe afaimọ ki iye ijoko ti ẹgbẹ oṣelu ANC yoo ni lọtẹ yii yoo dinku o si le maa to iye ti wọn nilo lati ṣe ijọba. Bi ọrọ wọn ba ṣẹ, Eyi si ni igba akọkọ laarin ọgbọn ọdun ti iru eyi yoo ṣẹlẹ.
Ibinu araalu nitori ọwọja iwa ijẹkujẹ, iwa ọdaran to n gogo sii ati aisi iṣẹ kun ara awọn ohun to n fa itakun to n da erinlakatabu ẹgbẹ oṣelu ANC lọna bayii.

Oríṣun àwòrán, BBC/David Nkya
Aarẹ Cyril Ramaphosa ti dibo rẹ nibi eto idiboa apapọ orilẹede South Africa to n lọ lọwọ.
Aarẹ Ramaphosa, ati iyawo rẹ, Tshepo Motsepe dibo nibudo idibo Chiwelo Station ni Soweto.
O ni kan oun balẹ pe ajọ eleto idibo orilẹede naa, IEC yoo ṣeto idibo naa daradara nitori wọn kọṣẹmọṣẹ, wọn si dantọ.
“Ọjọ nla leyi fun ijọba awarawa ni South Africa. Loni, a n dibo fun iduroṣinṣin ati itẹsiwaju ijọba tiwantiwa wa.”
Ètò ìdìbò àpapọ̀ bẹ̀rẹ̀ ní South Africa

Oríṣun àwòrán, BBC/Kyla Herrmannsen
Eto idibo ti bẹrẹ bayii lorilẹede South Africa.
Gẹgẹ bi awọn iroyin ti awọn akọroyin BBC kaakiri South Africa n fi ṣọwọ, eto idibo ti bẹrẹ kaakiri orilẹede naa.
Awọn oludibo n dibo lati yan awọn adari wọn lorilẹede naa lẹyin ọgbọn ọdun ti wọn di ibo akọkọ nibẹ.
Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn iroyin n sọ pe awọn idiwọ diẹdiẹ wa lawọn agbegbe kan nibẹ, sibẹ ohun ti a n gbọ ni pe idibo ti bẹrẹ.
Ni ibudo idibo Joubert Park ni ilu Johannesbur, idiwọ kọkọ waye fun nnkan bii ogoji iṣẹju ki wọn to pada bẹrẹ idibo nibẹ.
Ni agbegbe Orlando West ni Soweto, idiwọ kọkọ wa fun idibo ni ibudo idibo to wa ni ile ẹkọ girama Kwansikana Junior Secondary School nitori aitete ri ontẹ ti wọn yoo fi lu iwe idibo nibo.
Awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo to wa nibẹ ti fi da awọn eeyna to ti to lati dibo nibẹ loju pe ontẹ yoo de laipẹ fun idibo lati bẹrẹ nibẹ

Oríṣun àwòrán, BBC/Rafieka Williams
Ki lo n ṣẹlẹ lori idibo naa?

Eto idibo apapọ lorilẹede South Africa yoo waye loni.
Eyi ni eto idibo apapọ keje lorilẹede South Africa lati ọdun 1994 ti wọn ti ṣe eto idibo akọkọ lẹyin ti iṣejọba amunisin dopin lorilẹede naa.
Ọpọ awuyewuye lo n wọ tọ ẹgbẹ oṣelu ANC ti Aarẹ Cyril Ramaphosa n lewaju fun lọwọ bayii.
Lara awọn ohun ti o n mu ki awọn oludibo poruru ọkan ṣaaju idibo ọhun ni ọwọja aisi iṣẹ faraalu. Bi a ṣe n sọrọ yii, ida mejilelọgbọn ninu ọgọrun ni ọwọja aisiṣẹ lorilẹede naa, aidọgba anfa eto ọrọ aje laarin awọn ọmọ orilẹede naa, ẹsun iwa ijẹkujẹ lọrun awọn oloṣelu, ati segesege ati idakureku ina ọba nibẹ ti mu adinku ba gbajumọ ẹgbẹ oṣelu ANC to ti n ṣe ijọba nibẹ lati ọdun 1994.

Bakan naa ni ọwọja iwa ipa pẹlu ti gogo sii nibẹ. Lojumọ kii din ni aadoje iṣẹlẹ ifipa banilopọ ati ọgọrin iṣẹlẹ ipaniyan to maa n waye lorilẹede naa laarin oṣu mẹta to gbẹyin lọdun 2023- eleyi pẹlu tun ta ẹrẹ ba iyi awọn adari orilẹede naa.
Bi ẹgbẹ oṣelu ANC ko ba ni ọpọ ijoko ni ile aṣofin apapọ gẹgẹ bi ti atẹyinwa, o ṣeeṣe ki eto iṣejọba ajumọṣe o waye nibẹ, eleyi ti yoo jẹ igba akọkọ ninu itan oṣelu orilẹede naa.
Wọn ti da awọn ọmọogun sita lati pese abo

Oríṣun àwòrán, SA National Defence Forc
Ọpọ awọn Ologun lo wa nigboro lati pese abo lasiko idibo naa
Ni bi a ṣe n sọrọ yii, ko tii si wahala kankan to niiṣe pẹlu idibo yii.
Nnkan bii ẹgbẹrun mẹta ṣọja ni wọn n ba awọn ọlọpaa ṣiṣẹ lati rii pe abo to peye wa lasiko idibo ọhun.
Bakan naa lawọn ologun ọhun tun n ran awọn oṣiṣẹ eleto idibo lọwọ pẹlu kiko awọn ohun elo idibo lọ si awọn agbegbe ti o jẹ pe ọkọ oju omi ati baluu hẹlikọputa nikan lo le de ibẹ.












