Israel kọ etí ikún sí ìdájọ́ ICJ, ní àwọn kò ní dáwọ́ ìkọlù sí Gaza àti Rafah dúró

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn alakoso ilẹ Israel ti sọ pe awọn ko nii tẹle aṣẹ ile-ẹjọ agbaye ti ICJ, eyi ti ni wọn gbọdọ dẹkun bi wọn ṣe n gbogun ti Rafah, tabi pe ki wọn ṣekun iṣẹ wọn ni Gaza.

Ile-ẹjọ ICJ ti paṣẹ pe ki Israel dẹkun gbogbo bi wọn ṣe n lo awọn ologun lori Gaza ni waranṣeṣa, eyi lo mu iparun ba awọn ara Palestine.

Onidajọ Salam lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu karun sọ pe ile-ẹjọ naa ti rii pe pẹlu bi nnkan ṣe n lọ, o ṣee ṣe ki ifarapa ti ko ni latunṣe ṣẹlẹ mọ si ẹtọ ọmọniyan fun awọn ara Gaza.

Siwaju sii ni Onidajọ Salam ni latigba ti ICJ ti paṣẹ eyi ti wọn pa ṣaaju, ti wọn si ti rii pe Israel ti gbe igbesẹ to yẹ.

Ile-ẹjọ naa paṣẹ pe ki Israel tete fi ohun to ba n ṣẹlẹ to wọn leti laarin oṣu kan ti wọn gbe aṣẹ naa kalẹ

Aṣẹ ICJ fi ẹsẹ mulẹ labẹ ofin, to si gbọdọ wa si imuṣẹ

Agbẹnusọ ijọba Israel, David Mencer sọ fun BBC pe: "Ko si agbara naa lagbaye yii to le jẹ ka ṣe ohun ti yoo jẹ ka gbẹmi ara wa nita, nitori pe ohun ti a ri eyi si ni pe ka dẹkun ikọlu wa si Hamas."

Bakan naa, awọn alakoso Palestine to ṣakoso apa kan ni West Bank ati Hamas ti wọn n tukọ Gaza ti gba aṣẹ ile-ẹjọ yii wọle, wọn si lawọn ṣetan lati ṣamulo rẹ.

Ṣugbọn ṣa, Hamas sọ pe ọrọ lati dẹkun ikọlu yii, kii ṣe Rafah nikan lo ṣiṣẹ fun, bi ko ṣe fun gbogbo Gaza.

Minisita fọrọ ogun ni Israel, Benny Gantz sọ pe Israel yoo ṣi maa tẹsiwaju pẹlu ogun wọn to ṣe koko lodi si Hamas lati le tu gbogbo awọn eeyan wọn ti wọn ko lẹru silẹ.

O ni awọn ọmọ ogun Israel yoo ṣiṣẹ wọn ni ibamu pẹlu ofin agbaye, wọn yoo si gbiyanju lati ma ṣe ṣe ikọlu si araalu.

"Ilẹ Israel ti farajin lati tẹsiwaju ninu ija wọn lati le gba gbogbo awọn to wa ninu igbekun silẹ, ti wọn si ṣeleri aabo awọn araalu wọn nigbakugba to ba yẹ. – to fi mọ Rafah,"

Aṣẹ ile-ẹjọ

Lara awọn aṣẹ ile-ẹjọ naa ni pe ki Israel dẹkun iṣẹ awọn ologun ni Rafah

Ki wọn ṣi ẹnubode Rafah to yọ si Egypt fun awọn alaabo lati ri aaye

Ki wọn rii pe aaye wa lati wọ Gaza fun awọn oniṣẹ iwadii lati ṣiṣẹ wọn.

Ki wọn pada lọ fi to ile-ẹjọ leti lati mọ ibi ti wọn de lori awọn amuyẹ ti wọn ti ṣe laarin oṣu kan

Onidajọ Salam sọrọ lori bi Hamas ṣi ṣe ko awon ọmọ ilẹ Israel si ahamọ wọn ni Gaza.

“Ile-ẹjọ naa kọminu gidi lori awọn to ṣi wa ni ahamọ yii, to si n woye ireti wọn... to si gbaṣẹ pe ki wọn tu wọn silẹ lai fi asiko ṣofo ati lai ni idi,” o sọ fun ile-ẹjọ.

“A rii gẹgẹ bi adojukọ nla pẹlu bi ọpọ ṣi ṣe wa ni ahamọ,” o fi kun ọrọ rẹ.

Aarẹ South Africa mu ọrọ Mandela bọnu pẹlu bo ṣe gba aṣẹ naa wọle

Lasiko irin ajo ipolongo kan to ṣe lọ sitosi ile Nelson Mandela ni Soweto, Aarẹ Cyril Ramaphosa mẹnuba ọrọ olori wọn to ti papoda: “A ko ni ominira patapata afigba ti awọn ara Palẹstine ba gba ominira.”

Aarẹ tẹlẹ, Madela jẹ ogbontarigi ninu awọn to nifẹ Palestine. Ramaphosa sọ pe Mandela ti kọ awọn ara South African nipa ohun to so wọn pọ pẹlu awọn ara Palestine.

“Aisi idajọ ododo fun Palestine naa tun jẹ aisi idajọ ododo fun South Africa,” gẹgẹ bo ṣe sọ.

Alaga ileeṣẹ to n bojuto ọrọ ilẹ okoore, Zane Dangor ṣapejuwe aṣẹ naa gẹgẹ bi eyi to jẹ iwuri to si dara, ati pe igba akọkọ ree ti ile-ẹjọ naa maa paṣẹ fun Israe; lati dawọn ikọlu rẹ ni agbegbe kan ni Gaza duro.

“A ni ireti wi pe igbimọ alaabo ajọ iṣọkan agbaye naa ni ti gbọ eyi, wọn yoo si ṣiṣẹ lee lori”, o sọ eyi, bẹẹ lo tun ni ijọba South Africa naa tun ti n gba UNSC sọrọ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, South Afrika ni wọn gbe ẹjọ naa lọ sile-ẹjọ ICJ lati gbe igbesẹ to yẹ.

Ibugbamu tun kọlu Rafah lẹyin iṣẹju diẹ ti ICJ paṣẹ

Ko ju bi iṣẹju diẹ lọ ti ile-ẹjọ ICJ gbe aṣẹ rẹ kalẹ, awọn ọkọ baluu ogun tun bẹrẹ sii ju awọn ohun ija ogun afẹfẹ si Shaboura, iyẹn ni aarin gbungbun Rafah.

Onimọ kan to wa nitosi ile-iwosan Kuwait sọ fun BBC pe iro idungbamu naa rinlẹ debi pe o ko ibẹrubojo ba wọn, ti kurukuru dudu si bo ọpọ awọn ori ile mọlẹ ni buba Shaboura.

Wọn ni ko si anfaani fun awọn alaabo iṣẹlẹ pajawiri ni ọsibitu naa lati le debẹ nitori bi ikọlu ọhun ṣe ri.