Emir Ado Bayero fohùn sílẹ̀ fún ìjọba ìpínlẹ̀ Kano tó rọ̀ọ́ lóyè, Ó ní kò sẹ́ni tó kọjá òfin

Oríṣun àwòrán, AMINU ADO BAYERO/INSTAGRAM
Emir Kano ti ijọba ipinlẹ naa rọ loye laipẹ yii, Alaaji Aminu Ado Bayero ti ṣe ikilọ nla fun gbogbo awọn to wa nidi irọloye rẹ lati tẹlẹ ofin, nitori ko sẹni to kọja ofin.
Ado Bayero lo sọ eyi ninu aafin kekere to lọ tẹdo si latigba ti wọn ti kede iyọnipo rẹ, to si n rọ gbogbo awọn alatilẹyin rẹ lati ṣe suuru.
Emir Bayero sọ pe idajọ ododo yoo waye, ati pe gbogbo abajade ohun to ba ṣẹlẹ nileẹjọ loun yoo gba gẹgẹ bi kadara, nitori pe ilu to ṣe pataki ni Kano jẹ ni Naijiria.
“A n pe awọn alakoso lati gbe idajọ ododo kalẹ lori ohun to n sẹlẹ yii. Ipinlẹ to ṣe pataki to si gbajumọ daadaa ni Kano jẹ ni Naijiria. A gbadura pe ki Allah bukun fun Kano pẹlu awọn adari to ṣee fọkan tan.”
Ṣaaju asiko yii ni Gomina Abba Yusuf ti paṣẹ pe ki wọn lọ fi kele ofin gbe Ado Bayero to yọ nipo Emir.
Ṣugbọn ti awọn ọlọpaa sọ pe awọn ko le gbe Ado Bayero, nitori pe gẹgẹ bi agbofinro, aṣẹ ile-ẹjọ lawọn yoo tẹle.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Usaini Gumel ninu ipade awọn akọroyin to ṣe jẹ ko di mimọ pe aṣẹ ti ile-ẹjọ giga apapọ to wa ni Kano gbe jade lọjọ kẹtalelogun, oṣu karun, ọdun 2024 lawọn yoo tẹle.
Gumel ni ki gbogbo awọn to n binu lọ fi ara wọn balẹ, ki wọn si gba alaafia laaye nipa titẹle aṣẹ ile-ẹjọ.
O lẹni tọwọ ba tẹ lori iwa janduku loun yoo fi kele ofin gbe, ti iru ẹni bẹẹ yoo si foju winna ofin.
Ki lo ṣẹlẹ sẹyin?
Diẹ lara awọn ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin ree
Ìjọba Kano pàṣẹ kí wọ́n fi kélé òfin gbé Ado Bayero tó yọ ní Emir, ìdí rèé

Oríṣun àwòrán, Abba Kabir Yusuf/Facebook
Ijọba ipinlẹ Kano labẹ iṣakoso Gomina Abba Kabir Yusuf ti paṣẹ pe ki wọn lọ fi kele ofin gbe Emir to rọ loye, Aminu Ado Bayero.
Gomina Yusuf lo paṣẹ naa ninu atẹjade ti alakoso eto iroyin ileeṣẹ ijọba, Sanusi Bature Dawakin Tofa gbe jade laarọ ọjọ Abamẹta.
Ẹsun ti ijọba Kano fi kan Ado Bayero ni pe o n da họhuhọhu to le da wahala nla silẹ laarin ilu Kano, to si ni awọn ni lati tete fi kele ofin gbe ko too pẹ ju.
Atẹjade ọhun ti akọle rẹ sọ pe ‘Gomina Yusuf paṣẹ ki wọn fi kele ofin gbe Emir Kano ti wọn rọ loye, Aminu Ado Bayero’ ni gomina ti sọ pe oun ko le laju silẹ lati jẹ ki wahala ṣẹlẹ niluu.
“Gomina ipinlẹ Kano, Abba Kabir Yusuf ti paṣẹ pe ki wọn lọ fi kele ofin gbe Emir tiluu Kano tẹlẹ, Aminu Ado Bayero, lori họhuhọhu to n da silẹ nipinlẹ yii.
O ni Emir ana naa wọnu ilu Kano, pẹlu erongba lati fi ipa pada sinu aafin lẹyin ọjọ meji ti gomina ti rọ ọ loye.
O ṣalaye pe eyi lo mu ki gomina, gẹgẹ bi alakoso fun eto aabo ilu ṣe dari Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Kano lati fofin gbe Emir ọhun lai fi asiko ṣofo pẹlu bo ṣe n gbiyanju lati da alaafia ilu laamu.
Tofa tu fi kun ọrọ rẹ pe Emir Muhammadu Sanusi ti pada si aafin to si kọwọrin pẹlu gomina, igbakeji gomina, olori ile igbimọ aṣofin ati awọn alẹnulọrọ ninu ijọba ni nnkan bi agogo kan oru, ọjọ Abamẹta, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2024.
Ado Bayero wọ aafin miran
Ẹwẹ, ninu iroyin miran to tun tẹ wa lọwọ la ti gbọ pe wọn ti mu Emir ana naa, Ado Bayero wọnu aafin miiran to wa to wa ni ipinlẹ Nasarawa.
Bi ẹ ko ba gbagbe, wakati mejidinlaadọta ni Gomina Aminu Yusuf fun Ado Bayero ati awọn Emir yooku ti gomina ana, Ganduje yan sipo lati fi ko kuro ni aafin koowa wọn.
Lojiji ni Ado Bayero ti ko sẹni to mọ ibi to wa lati Ọjọbọ ti wọn ti rọ ọ loye yọ lojiji silu Kano, ti ogunlọgọ awọn ololufẹ rẹ si lọ pada ẹ lati kii kaabọ, pẹlu ariwo nla laarọ ọjọ Aje.
Ko pẹ ni wọn gbe e lọ si aafin kekere kan to wa ni Nassarawa.
Amọ iroyin ni Emir Muhammadu Sanusi II ti wa ni aafin ilu Kano to si ki irun jimọ nibẹ lọjọ Ẹti.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Kano kọ àṣẹ ilé ẹjọ́, dá Muhammadu Sanusi padà sípò Emir Kano

Oríṣun àwòrán, getty images
Gomina ipinlẹ Kano, Abba Yusuf ti da Emir ilu Kano tẹlẹ, Sanusi Muhammadu, pada sori itẹ rẹ gẹgẹ bii Emir Kano.
Oni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinlelogun, ọdun 2024 ni gomina Abba Yusuf fun Sanusi ni lẹta idapadasipo rẹ ọhun.
Idapadabọsipo yii lo waye lẹyin ọdun mẹri gbako ti gomina Kano ana, Abdullahi Ganduje, yọ Sanusi bii jiga.
Awọn baalẹ, Afọbajẹ atawọn eeyan jankan mii lo peju sibi ayẹyẹ naa to waye niluu Kano.
Ayẹyẹ idapadabọsipo ọhun lo waye lẹyin ọjọ kan ti gomina Yusuf buwọlu ofin to ni ko ma ṣe bẹẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ile ẹjọ gigga kan ti kọkọ paṣẹ pe gomina ọhun ko gbọdọ da Emir naa pada bọ sipo, sibẹsibẹ o gbe igbesẹ ọhun.
Ile ẹjọ ọhun tun bẹgi dina ofin tuntun to fopin si ẹmireeti mẹrin to jẹ Bichi, Gaya, Karaye, ati Rano.
Iléẹjọ́ pàṣẹ ìdádúró òfín tó tú ẹkùn lọ́balọ́ba Kano ká, èyí tó dá Sanusi padà sípò Emir

Oríṣun àwòrán, Lamido Sanusi/Facebook
Ile ẹjọ giga ijọba apapọ niluu Kano ti paṣẹ idaduro ofin ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa to tu ẹkun lọbalọba ipinlẹ Kano ka.
Ti ẹ o ba gbagbe, ijọba gomina ana ipinlẹ Kwara, Abdullahi Ganduje lo ṣe agbekalẹ ẹkun lọbalọba marun un ipinlẹ Kano yii lẹyin to rọ Lamido Sanusi loye gẹgẹ bi Emir ilu Kano lọdun 2019.
Ni Ọjọbọ ọjọ kẹtalelogun oṣu Karun un yii ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kano tu ẹkun lọbalọba marun un naa ka ti gomina Abba Kabir Yusuf si kede ipadabọ sipo Sanusi gẹgẹ bi Emir ilu Kano.
Emir Dawaki Babba, Alhaji Aminu Babba Dan Agundi lo pẹjọ tako bi ile igbimọ aṣofin ṣe tu ẹkun lọbalọba marun un ipinlẹ Kano ka.
Lẹyin naa ni adajọ Mai Sharia Liman paṣẹ idaduro ofin ọhun, adajọ ṣi tun sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹta oṣu Kẹfa lati gbọ ẹjọ ti olupẹjọ pe daadaa.
Iroyin yii jẹyọ ṣaaju ibura fun Sanusi gẹgẹ bi Emir Kano tuntun.
Iwe ipẹjọ yii ti tan ka ori ayelujara eyi to jẹ iyalẹnu fun ọpọ eeyan papaa julọ pẹlu bi gomina Kano ti kede ipadabọ sipo Sanusi lalẹ Ọjọbọ.

Oríṣun àwòrán, Other

Oríṣun àwòrán, Other

Oríṣun àwòrán, Other
Ìjọba rọ Aminu Ado Bayero lóyè, dá Sanusi Lamido padà sípò 'Emir' Kano

Oríṣun àwòrán, MAJEEDA STUDIO
Ijọba ipinlẹ Kano ti da Sanusi Lamido Sanusi pada sipo emir ilu Kano, lẹyin ti o rọ Aminu Ado Bayero loye loni Ọjọbọ.
Igbesẹ yii waye lẹyin ti gomina Kabir Yusuf ipinlẹ Kano buwọ́lù ofin tuntun ọdun 2024 to n ri ipo awọn lọbalọba.
Ṣaaju l'Ọjọbọ yii kan naa ni ile aṣofin ipinlẹ Kano tu ikangun marun ọba jijẹ niluu Kano eyi ti ijọba ṣe agbekalẹ rẹ lọdun 2019.
Lẹyin ibuwọlu ofin tuntun naa ni gomina kede Sanusi gẹgẹ bi Emir Kano kẹrindilogun ti o ṣi rọ Ado Bayero loye.
Igbesẹ yii tumọ si pe oye ẹbi l'ọba lọba Gaya, Bichi, Karaye ati Rano ti tuka bayii.
Ni ọdun mẹrin sẹyin ni gomina ana ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje yọ Sanusi nipo emir.
Aigbọran si ijọba wa lara idi ti Ganduje lo ṣe rọ Sanusi loye.














