Lórí ọ̀rọ̀ Ìmáàmù Ogbomosho, àwọn kan ń yarí pé àwọn alágbara ló gbé e sípò, kìí ṣe ọmọ ìdílé t'óyè tọ́ sí

Aworan Yunus Teliat Olushina

Oríṣun àwòrán, Imaamu Yunus Teliat Olushina /Facebook

Idile Imaamu Ayilara niluu Ogbomoso ti sọ pe ki Soun ti ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye to gori oye lawọn ti ke gbajare pe Imaamu Teliat Olushina ki i ṣe ọmọ ile awọn.

Ninu atejade kan ti Ọmọba Hassan Abdulkareem Tunde Ayilara ka jade fawọn oniroyin lorukọ gbogbo ẹbi, lo ti salaye pe lẹyin ti Imaamu ilu Ogbomoso tẹlẹ, Sheikh Sanusi Ashafa ku ni o kan ẹbi awọn lati jẹ Imaamu.

"Amọ, awọn to lagbara ju wa lọ lo ọgbọn alumọkọrọi lati fa Alfa Olushina kalẹ.

A fẹhonu han lori bi wọn ṣe fa Olushina kalẹ ṣaaju ki wọn to ṣe ayẹwo fun un, ṣugbọn wọn yan wa jẹ.

A ke gbajare de aafin Soun to w'aja lori ọrọ yii, Ọba Jimoh Oladunni Oyewumi, Ajagungbade Kẹta, amọ, awọn eeyan yii tun lo agbara wọn de ọdọ kabiesi nigba naa.

Pẹlu ibi ti ọjọ ori Soun Ajagungbade Kẹta de nigba naa, awọn eeyan naa ri pe kabiesi gba orukọ Alfa Olushina wọle.

Ko si ẹni to n jẹ Yunus Teliat Olushina ninu ẹbi Imaamu Ayilara

A ṣe ifẹhonuhan titi di ọjọ ti wọn fi gbe ọpa aṣẹ fun Olushina ni aafin lọjọ kọkandinlogun oṣu Kọkanla ọdun 2023.

Ọjọ mọkanlelogun lẹyin to gba ọpa aṣẹ tan ni Ọba Oyewumi Ajagungbade Kẹta waja, eyi to fihan pe o ṣeeṣe ki ọkan kabiesi ma fi gbogbo ara wa nibi ọrọ naa.

Gbogbo ẹbi Imaamu Ayilara lẹyin iwadii ti wọn ṣe lo fidi rẹ mulẹ pe Alfa Olushina ko tan mọ ẹbi rara.

A fẹ fi asiko yii sọ fun ẹyin akoroyin wi pe ko si ẹni to n jẹ Alfa Yunus Olushina ni idile Imaamu Ayilara niluu Ogbomoso."

Ewẹ, Imaamu Ayilara ṣi duro lori ẹsẹ rẹ pe oun ko ni sọ ohun kan fawọn akoroyin lori ọrọ naa.

Nigba to n ba BBC sọrọ, Imaamu naa sọ pe "mi o ti sọ ohun kan lati igba ti ọrọ yii ti bẹrẹ.

Ọrọ ẹbi ni ọrọ to wa nilẹ yii, tori naa ẹbi naa lo maa yanju ọrọ naa fun ra wọn.

Mo ti lọ síwájú ìgbìmọ̀ tí Ọba Ghandi gbé dìde, mo fẹ́ kí alága ìgbìmọ̀ gbé èsì ìwádìí wọn jáde - Imaamu Ayilara

Aworan Imaamu ati Soun Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Imaamu Ogbomoso/Rev Peter Olaleye/Facebook

Imaamu agba ilu Ogbomoso, Yunus Olusina Teliat Ayilara sọ pe oun ti ṣe ojuṣe oun nipa igbimọ ti Soun ti ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Olaoye gbe dide.

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ, Imaamu Ayilara ni "mo ti farahan niwaju igbimọ naa.

Ẹyin oniroyin lo yẹ ki ẹ beere lọwọ alaga igbimọ oluwadii naa wi pe ko gbe esi iwadii ti wọn ṣe jade.

Mo ro pe ko bojumu ki ẹ tun maa beere ọrọ nipa igbimọ yii lọwọ awa ti wọn fi ọrọ wa lẹnu wo."

Imaamu Teliat ko ṣai tun mẹnu ba aawọ to n ṣẹlẹ laarin rẹ ati ẹbi Ayilara.

Imaamu Ayilara sọ pe "gẹgẹ bi onimọ nipa ẹsin musulumi, ẹnikẹni to ba ja okun ẹbi ko ni ri iyọnu Ọlọrun ni alikiamọ.

Nitori naa, ọrọ ẹbi inu ẹbi ni a ti maa n sọ ọ, kii ṣe nita.

Ẹsin ti wa ko faramọ ki a maa sọrọ ẹbi lori ẹrọ agbagbe.

Ti ẹ ba ṣe akiyesi daadaa, mi o sọ ọrọ mọlẹbi mi nibi kankan lati igba ti ọrọ yii ti bẹrẹ.

Kii ṣe pe mi o mọ ọrọ sọ tabi mi o mọ ohun ti mo le sọ.

Mi o le wọ ẹbi mi nilẹ tori ohun to n bẹ nilẹ yii naa yoo pada pari.

Amọ ohun ti a ba ti sọ silẹ ko le tan."

Kò sí àkọsílẹ̀ pé mo hùwà àrífín sí Soun Ọba Ghandi Olaoye rí - Ìmáàmù àgbà Ogbomoso

Aworan Imaamu agba Ogbomoso ati Soun Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Rev Peter Olaleye/Facebook

Imaamu agba ilu Ogbomoso, Yunus Olusina Teliat Ayilara ti fesi sọrọ awọn idile afobajẹ marun un ti wọn sọ pe ki o ye tabuku Soun ilu Ogbomoso, Oba Ghandi Afolabi Olaoye mọ.

Imaamu Ayilara sọ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ ti o ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin naa pe oun ko huwa arifin si Ọba Ghandi ri.

"Itẹ Ṣoun Ogbomoṣo kii ṣe itẹ ti eeyan gbọdọ ri fin.

Ki i ṣe itẹ Ṣoun Ogbomoṣo nikan, itẹ gbogbo ọba ni.

Gẹgẹ bi ọmọ Yoruba, mi ki i ṣe ẹni ti eeyan ṣẹṣẹ maa kìlọ fun pe ki o maa kan ọba labuku.

Yoruba ni mo sun mọ ọba niwọn egbeje, mo jina sọba niwọn ẹgbẹfa, arọba fin lọba a pa.

Ọba ko ṣe ri fin, ko si akọsilẹ pe mo ri ọba fin nigba kan, n ko si ni ri ọba fin," Imaamu Ayilara lo sọ bẹẹ.

Lori ẹsun ti wọn fi kan an pe, ki i ṣe ojulowo ọmọ ile Ayilara, Imaamu Ogbomoso ni ọrọ ẹbi ni ọrọ naa eyi ti oun ko ni sọ ohun kankan nipa rẹ.

Imaamu naa ni oun ko ni sọ ọrọ ẹbi oun nita gbangba.

Ìmáàmù Ayilara, yé sọ̀rọ̀ àlùfànsá sí Soun Ogbomoṣo Ọba Ghandi Olaoye mọ́ - Àwọn afọbajẹ kìlọ̀

Aworan Soun Ogbomoṣo

Oríṣun àwòrán, OLALEYE OLAWUYI PETER/FACEBOOK

Idile Ọba marun un niluu Ogbomoso, Aburumaku, Gbegun, Laoye, Bolanta ati Odunaro tí kilọ fun imamu agba Ogbomoso, Teliat Yunus Olushina Ayilara lati dẹkun riri Soun fin.

Awọn idile Ọba marun-un yii jẹ ki eyi di mimọ nigba ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Aafin Soun Ogbomoso.

Awọn Olori Ebi, ti a n pe ni Mogaji lo lewaju awọn idile naa ni ihuwasi Imamu agba si Soun ku diẹ kato, to si n tan kaakiri gbogbo ilu Ogbomoso.

Gẹgẹ bii wọn ṣe salaye, awọn Mogaji ni ihuwasi yii bẹrẹ nigba ti Soun gbe ìgbìmọ kalẹ lati se iwadii lori boya lootọ ni Imamu agba wa lati idile Ayilara.

Igbimọ tí Soun gbe kalẹ ni ki Imamu agba yẹra kuro lori ipo, ko si lọ yanju awọ pẹlu mọlẹbi rẹ.

Wọn jẹ ko di mimọ pe gbogbo iyansipo tí Imamu agba naa se ni ko lẹtọ lati se nitori Soun ko buwọlu wọn gẹgẹ bii o ṣe wa niluu ilana ilu Ogbomoso.

"Mọsalasi Ogbomoso, dukia Soun ni o jẹ, a bu ẹnu atẹlu ihuwasi Imamu agba si Soun gẹgẹ bii idile Ọba Soun.

"To fi le igboya gbe Soun to fi jẹ oye lọ Ile ẹjọ, o ti pọju, ti iru eyi ko si waye ri ninu itan Ogbomoso

Aworan lati bí ipade àwọn idile Ọba l'Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Others

"Ipo Soun ko wa fun ẹṣin kankan, boya Musulumi tabi Kristẹni.

"A n kilọ fun un lati ye darukọ Soun mọ, ko ni isoro pẹlu Soun, ko lọ ba awọn Mọlẹbi, kí wọn yanju awọ to wa laarin wọn

"Olori Ebi Ayilara fẹsun kan pe ko ki n se ọmọ ile Ayilara, ti Kabiyesi sì gbe ìgbìmọ kalẹ lati se iwadii.

"Ababọ igbimọ naa ni pe ki Imamu yẹra kuro lori ipo. Sẹnẹtọ Ayo Adeseun ati Dokita Saka Balogun lo ba Imamu bẹ Kabiyesi pe ki fún wọn lọjọ meje, bẹrẹ lati ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹwaa ọdun to kọja lati se atunse.

"Ṣugbọn títí di asiko yii wọn ko ti pada wa ba Kabiyesi."