Wo àgbàlá Ogundoyin lórí òkè ìlú Eruwa, akọni ọkùnrin táwọn òbí rẹ̀ fẹ́ gbé sọnù ní kékeré àmọ́ tó d'èèyàn ńlá

Àkọlé fídíò, Wo àgbàlá Ogundoyin lórí téńté nìlú Eruwa, akọni ọkùnrin tó dárà sílùú abínibí rẹ̀
Wo àgbàlá Ogundoyin lórí òkè ìlú Eruwa, akọni ọkùnrin táwọn òbí rẹ̀ fẹ́ gbé sọnù ní kékeré àmọ́ tó d'èèyàn ńlá

Yoruba bọ wọn ni bi inirese ko ba fingba mọ, eyi to ti fun silẹ ko le parun.

Bayii ni ọrọ ṣe ri pẹlu Ọgbẹni Adeseun Ogundoyin to jẹ ọmọbibi ilu Eruwa lẹkun Ibarapa ni ipinlẹ Oyo.

Ọkunrin yii lawọn eeyan ilu Eruwa ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi akinkanju eeyan to ṣe oriṣiiriṣii nnkan ribiribi silu Eruwa.

Ọgbẹni Sunday Ojeleye to jẹ olupitan sọ pe awọn obi Ogundoyin fẹ lọ gbe e sọnu nigba ti wọn bi i tori niṣe ni o ri bi alangba, mama kan to jẹ aburo Ogundoyin lo sọ pe ki wọn fi ọmọ naa silẹ tori o le di eeyan nla lọjọ iwaju.

‘’Ogundoyin ṣẹgi ta ki o le lanfani lati tẹsiwaju ẹkọ rẹ nigba to pari iwe mẹfa tan tori ọmọ atapata dide ni.

Iṣẹ to n ṣe yii lo gbe de ilu Igbo-ora ti oyinbo kan to ṣabẹwo si ilu naa fi mu un lọ si ilu Eko tori pe o jara mọ iṣẹ.

Nnkan ti o ṣe ni Eruwa ti gbogbo eeyan fi n ranti rẹ ni pe oun lo ṣagbatẹru ti ile ẹkọ giga gbogbnṣe ti ipinlẹ Oyo ṣe de ilu Eruwa, eleyii ti wọn fi orukọ rẹ sọ.

Bakan naa ni awọn ileeṣẹ ti o da silẹ niluu Eruwa.

Ere iṣẹ ọwọ Ogundoyin ọmọkunrin rẹ, Adebo Ogundoyin to jẹ adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo jẹ lonii.