Kílódé tí wọ́n fi lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásítì ọmọ Nàìjíríà kan dànù ní fásítì orílẹ́èdè UK?

Awọn akẹkọọ fasiti Teesside
Àkọlé àwòrán, Awọn akẹkọọ fasiti Teesside
    • Author, Joanna Morris
    • Role, BBC News, North East and Cumbria

'A wa ko fẹ, awa ko gba, ẹ maa ṣe fi ẹtọ wa dun wa' lorin ti gbogbo awọn ọmọ Naijiria ti wọn n kẹkọọ lọwọ ni fasiti kan to wa nilẹ Gẹẹsi n kọ nigba ti wọn gba iwe 'ẹ pada sile yin' lati ọdọ awọn alaṣẹ fasiti naa.

Fasiti kan ti wọn pe ni Teesside la gbọ pe o le awọn ọmọ Naijiria ti wọn n kẹkọọ lọwọ kuro lojiji.

Lara awọn ohun ti awọn alakoso fasiti Teesside sọ ni pe awọn ko mọ-ọn-mọ le awọn akẹkọọ to wa lati Naijiria danu, bi ko ṣe ti owo naira ti ko gbewọn mọ, eyi to si n jẹ iṣoro fun wọn lati ri owo ile-ẹkọ san.

A gbọ pe niṣe ni wọn tilẹkun abawọle fasiti ọhun mọ awọn akẹkọọ yii lati ma le ri aaye wọle, ti wọn si n kọrin fun wọn pe 'ẹ pada sile yin'.

Ohun ti awọn akẹkọọ wọnyi n sọ ni pe iwa ọdaju lawọn alakoso fasiti ọhun hu si wọn, to si le ṣeku pa awọn laitọjọ.

Agbẹnusọ fasiti kan sọ pe aile san owo ile-ẹkọ wa lara yiyẹ adehun fun fisa gbigba, leyi to si di dandan lati fi to awọn to ran wọn wa leti. Awọn ileeṣẹ atile naa wa sọ pe awọn alakoso naa lo ni ipinnu lati ṣe.

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe orileede Naijiria n koju iṣoro ati ipenija eto ọrọ aje to dẹnukọle julọ kaakiri agbaye, eyi to si n ko ipa ti ko dara nigbesi aye awọn akẹkọọ Naijiria lawọn fasiti to wa l'Amẹrika

Bi nnkan ṣe n gbogbo lori lọdọọdun ti to ida mẹrinlelọgbọn bayii, eyi to wa lati ọwọ Aarẹ Bọla Tinubu lori bo ṣe yọ owo iranwọ ori epo rọbi kuro lọdun to kọja, to si mu ki owo bẹntiroolu ati disu lọ soke, koda, to tun ti jẹ ki ọpọlọpọ nnkan gbowo lori.

Ijọba tun ti kọ lati maa ṣe iranwọ fun agbara owo naira ni ọja okoowo, to si ti jẹ ki owo naa ja wa silẹ ni ida igba si ti owo dọla.

Awọn akẹkọọ kan to gbe pata ifẹhonuhan dani
Àkọlé àwòrán, Awọn akẹkọọ kan to gbe pata ifẹhonuhan dani

Ṣaaju ko to di pe wọn bẹrẹ eto ẹkọ wọn ni Teesside, awọn akẹkọọ ti ọrọ yii kan ni wọn ti sọ pe ki wọn ṣafihan ẹri to sọ pe wọn ni owo to to owo lọwọ lati fi san owo ile-ẹkọ wọn ati owo ti wọn yoo maa na lasiko ti wọn yoo fi wa nibẹ.

Ju gbogbo rẹ lọ, awọn owo yii lo ti wa ja wa silẹ latari wahala to n ṣẹlẹ lorileede wọn.

Ipenija nla yii lo bẹrẹ nigba ti wọn sọ pe awọn alaṣẹ fasiti yii ṣatunto lori ilana sisan owo ile-ẹkọ ni igba meje ọtọọtọ, ti wọn din ilana ọhun ku si igba mẹta.

Awọn akẹkọọ naa ti ọgọta ninu darukọ wọn fun BBC ni wọn fi ẹhonu wọn han, ti wọn si erongba wọn ati bi iṣẹlẹ ọhun ṣe lọkan wọn.

Wọn lawọn ti kọwe iranlọwọ si fasiti naa lori awọn ti wọn ko ri owo san, ti wọn si yọ orukọ wọn danu.

Awọn miran ninu wọn ni awọn ajọ to n gba owo gbese fun fasiti ọhun ti pe ṣaaju.

Adenike Ibrahim, standing against a brick wall
Àkọlé àwòrán, Adenike Ibrahim ti wa ni ipele aṣekagba ko to di pe wọn lee danu

Adenike Ibrahim ti wa ni ipele aṣekagba, to si ti n palẹmọ lati ṣe ayẹyẹ rẹ ko to di pe ko ri owo ileeṣẹ san, eyi to jẹ ki wọn lee danu pe ko lẹtọọ.

Lẹyin to pada san owo naa ni wọn jẹ ko di mimọ fun un pe wọn ko gba a wọle sile-ẹkọ naa mọ, ati pe o gbọdọ fi orileede naa silẹ pẹlu ọmọ rẹ to mu lọ.

"Nigba kan, mi o ri owo san, ṣugbọn mo ti san ida aadọrun-un ninu owo ile-ẹkọ mi, mo si n lọ si gbogbo kilaasi mi.

"Mo pe wọn lati le jọ fi ẹnu ko lori adehun, ṣugbọn wọn ko bikita lori ohun ti yoo ṣẹlẹ si awọn akẹkọọ wọn."

O sọ pe ibanujẹ nla ni iriri naa jẹ foun , ati pe oun ko mọ nnkan ti yoo ṣẹlẹ si ẹkọ toun wa kọ nibẹ.

"Ibanilọkanjẹ lo jẹ fun ọmọ mi papaa, ọkan rẹ si ti gbọgbẹ latigba ti mo ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun un."

Ko si ẹtọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun

Home Office sọ fun awọn akẹkọọ, to fi mọ Ibrahim pe anfaani wọn lati wọ Amẹrika ti foriṣanpọn niwọn igba ti eto ẹkọ wọn ni fasiti ti duro.

Awọn lẹta naa to tẹ BBC lọwọ ṣafihan igba ti gbogbo awọn akẹkọọ wọnyi gbọdọ fi Amẹrika silẹ, to si tun wa nibẹ pe wọn ko ni ẹtọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun lori ipinnu ti awọn alaṣẹ ṣe.

Latigba ti wọn ti gba lẹta yii, ọkan lara awọn to n ṣeto ẹkọ ipele keji (masters) rẹ, ẹni ti ko fẹ ki orukọ rẹ jade sita sọ pe oun ti pinnu lati gba ẹmi ara oun, ati pe oun ti dawọ ounjẹ ati omi mimu duro.

Fasiti naa ni oun ti sa ipa lati ṣe iranwọ fun awọn akẹkọọ wọnyi, awọn ti wọn ti wa fun ni anfaani ipade ojukoju pẹlu awọn oṣiṣẹ akọṣẹmọṣẹ, ati pe wọn ti pe fun bi wọn yoo ṣe san owo.

Esther Obigwe
Àkọlé àwòrán, Esther Obigwe

Esther Obigwe sọ pe atigbadegba loun gbiyanju lati ba awọn alakoso fasiti naa sọrọ lori ipenija owo to n koju, ṣugbọn toun ko gbọ esi kankan lati ọdọ wọn, titi digba ti wọn fi le oun naa danu, ti wọn ni ko kuro lorileede ọhun.

"Mo n lọ gbogbo kilaasi ati idanilẹkọọ, mo si jẹ akẹkọọ to n ṣe dee dee.

"O banilọkanjẹ, mo ti wa di ẹni apẹjuwe buruku, mo si da wa nibi, mi o ri ẹnikankan lati ba sọrọ.

"Lati oṣu meji le sẹyin ni mi o ti le jẹun daadaa, bẹẹ ni mi o le sun daadaa. Mi o mọ idi to fi jẹ pe awa ni iru ohun to n ṣẹlẹ yii tọ si, nitori pe a ko ṣe ohun ti ko tọna."

O tun fi kun ọrọ rẹ pe "Pupọ ninu awọn akẹkọọ to wa nibi ni wọn ti na ọpọlọpọ owo lati le duro sibi".

Jude Salubri
Àkọlé àwòrán, Jude Salubri fẹ ki awọn fasiti gba awọn akẹkọọ yii pada
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Jude Salubi, ẹni to kẹkọọ lati di oṣiṣẹ igbalode lo ti kẹkọọ de idaji, ko to di pe wọn sọ fun un pe ko le ni anfaani lati tẹsiwaju ninu eto ẹkọ rẹ mọ, ati pe o di dandan fun un lati fi orileede naa silẹ.

Yatọ si eyi, Jude maa n rin irin ajo lati Teesside lọ si Liverpool ni gbogbo opin ọsẹ lati ṣiṣẹ wakati mẹjọ ko le ri gbese owo ile-ẹkọ rẹ san.

"Titri di asiko yii, mo ti san "As of now I have paid ẹgbẹrun mẹrinla pọun (£14,000), to si tun ku ẹgbẹrun mẹrinla poun ki n san.

"Mo ṣtan lati ba wọn tọwọ bọ iwe adehun lori bi maa ṣe ri owo yii san, ṣugbọn mo ni lati ri idaniloju wi pe wọn gba mi pada sile-ẹkọ yii, ati pe wọn tun da fisa mi pada."

Lara awọn akẹkọọ wọnyi ni wọn ti san gbogbo gbese ti wọn jẹ silẹ, ṣugbọn ti fasiti naa ṣi le wọn kuro nile ẹkọ.

Agbẹnusọ fasiti sọ pe, "Fasiti Teesside ni igboya ati iwuri lati jẹ ile-ẹkọ agbaye to ni akẹkọọ to kun fun oriṣiriṣi ẹya, ati pe sibẹ wọn tun maa n ṣọra lori ọrọ ilana gbigba fisa.

"Ilana nla yii la n bẹru lati rii pe fasiti yii ṣe iranwọ fun awọn akẹkọọ to n wa, fun idi eyi, ohun to n ṣẹlẹ yii kọja agbara fasiti."

Agbẹnusọ naa fi kun ọrọ rẹ pe "a mọ nipa ipenija owo ti awọn akẹkọọ kan n koju" ti awọn si ti wa ọna lati ṣagbeyẹwo bi wọn yoo ṣe maa ri owo san.

"Erongba yii ni ọpọ awọn akẹkọọ wa lati orileede miran ti gbe igbesẹ rẹ; ṣugbọn ṣa, awọn akẹkọọ kan ko tun ri owo naa san sibẹ."