Ìjọba da ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀fọn tí wọ́n ti pa kádàrá rẹ̀ dà síta láti gbógun ti àìsàn ibà

Malaria

Oríṣun àwòrán, getty images

Ijọba orilẹede Djibouti ti da ẹgbẹgbẹrun ẹya ẹfọn kan si aarin igboro lọna ati gbogun ti aisan iba.

Ilu Ambouli ni wọn da ẹfọn naa si lasiko yii.

Awọn ẹfọn ọhun, ti awọn onimọ sayẹnsi ti ṣe atunṣe si lara ni wọn da sita lọna ati gbogun ti iba.

Igbagbọ wa pe awọn ẹfọn naa yo doju ija kọ awọn ẹfọn to n ṣokunfa aisan iba, ti yoo si mu adinku ba aisan iba lorilẹede naa.

Eyii ni igba akọkọ ti ijọba yoo da irufẹ ẹfọn bẹẹ saarin igboro lorilẹede Djibouti to wa ni ila oorun ilẹ Afrika amọ o jẹ igba keji ti iru rẹ yoo waye nilẹ adulawọ.

Afojusun awọn onimọ ijinlẹ ni pe awọn ẹfọn naa ti wọn pe ni ‘Anopheles stephensi’ yoo gbogun ti awọn akẹgbẹ wọn to n fa iba.

Orilẹede Rusia ni awọ onimọ ijinlẹ sọ pe ẹya ẹfọn ‘Anopheles stephensi’ ọhun ti wa ki wọn to yi iṣẹda rẹ pada.

Bi ẹfọn stephensis ṣe n gbogun ti aisan iba

Ẹfọn naa ni eroja kan lara, eyii ti yoo fi sara abo ẹfọn lasiko ti wọn ba ni ibalopọ.

Lẹyin ibalopọ naa ni abo ẹfọn ọhun yoo ni eroja naa lara.

Ti abo ẹfọn naa ba ti bi ọmọ, eyii to ba jẹ akọ ninu wọn yoo ye, nigba ti eyii to ba jẹ abo ninu ọmọ naa yoo jade laye ko to dagba.

Eredi igbeṣe yii ni pe abo ẹfọn nikan lo le ṣokunfa aisan iba fun ọmọ eniyan tati ẹranko.

Ọdun 2012 ni wọn kọkọ ṣawari ẹya ẹfọn Anopheles stephensi lorilẹede Djibouti.