Àwọn àgbà òṣèrè sọ èrò wọn lórí òfin t'íjọba fi de fifi oògùn owó àti sìgá mímu ṣeré nínú fíìmù

Aworan Latin, Tunubu ati Kosoko

Oríṣun àwòrán, Mr Latin, Tunubu Kosoko/Instagram

Awọn alẹnulọrọ ninu iṣẹ tiata lorileede Naijiria, ẹka ti Yoruba ti sọ pe kii ṣe awọn ni wọn n fa gbogbo iwa aibofin mu to n ṣẹlẹ lawujọ orileede yii.

Wọn ni anfaani nla ni awọn fiimu agbelewo ti wọn n gbe jade sita fawọn araalu n ṣe, ati pe pupọ araalu ni kii ṣamulo awọn ẹkọ ti wọn n ri kọ ninu awọn sinima wọn.

Laipẹ yii ni ijọba apapọ fi ofin de awọn agbekalẹ kan ninu iṣẹ sinima gbigbe jade, awọn ipa bii siga ati egboogi oloro mimu, oogun owo ati ipani-ṣẹṣo ṣiṣẹ ninu awọn sinima.

Alaga ajọ to n bojuto fiimu agbelewo ni Naijiria, NFVCB, Shaibu Husseini lo gbe ikede yii jade nipinlẹ Ẹnugu laipẹ yii.

Ijọba sọ pe awọn ipa naa n ko ipalara to pọ ba awọn ọmọde, paapaa awọn ọdọ ti wọn fẹran lati maa wo sinima agbelewo.

Ṣugbọn ṣa awọn agbaagba yii ṣalaye pe awọn ipa ti ijọba n sọ yii, lawọn n lo lati fi kọ awọn eeyan lẹkọọ lati le jẹ ki wọn mọ pe ko dara, kii ṣe lati le jẹ ki wọn maa huwa buruku.

Wọn wa jẹ ko di mimọ pe awọn ti gbọ ohun ti ijọba sọ, ṣugbọn awọn agbaagba ninu ẹgbẹ oṣere naa yoo jokoo lati jiroro, ki wọn se ṣagbeyẹwo lati mọ ipalara ati anfaani ti ofin naa yoo ṣe fun awọn.

Lẹyin agbeyẹwo ọhun ni wọn sọ pe awọn to le sọ boya o tẹ wọn lọrun, tabi ko tẹ wọn lọrun.

Awa agbaagba ẹgbẹ maa jokoo ijiroro ni ti ipa 'oogun owo ṣiṣe - Mr Latin
Aworan Mista Latin

Oríṣun àwòrán, Bolaji Amusan/Instagram

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere, ẹka ti Theatre Arts And Motion Pictures Practitioners Association Of Nigeria (TAMPAN) ni Ọgbẹni Bọlaji Amuṣan ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Mista Latin ba BBC Yoruba sọrọ.

Mista Latin sọ pe igbesẹ to dara ni ofin ti ijọba gbe kalẹ yii ni ẹka ti fifi ofin de Siga ati Tobako (Tobacco) mimu ninu awọn sinima.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe oun ko tii le sọ ohunkohun ni ti ipa oogun owo ati ipaniyan ṣẹṣo ti wọn n sọ, bi ko ṣe pe lẹyin ipade awọn agbaagba ẹgbẹ loun yoo to le sọrọ lori rẹ.

Ogbontarigi adẹrinpoṣonu naa ni gẹgẹ bi aarẹ ẹgbẹ TAMPAN, oun ati awọn agbaagba ẹgbẹ naa yoo jokoo ipade lati jiroro lori ofin ijọba tuntun yii.

Ninu ọrọ rẹ, o ṣalaye pe “Ṣe ẹ mọ pe ti ọrọ ba ti ri bayii, gbogbo awa ọmọ ẹgbẹ la maa pe ara wa jọ, paapaa awa ti a jẹ oloye ẹgbẹ lati jiroro lee lori, ko to di pe a sọ ipinnu wa.

“Nigba ti a ba pe ara wa jọ, onikaluku yoo sọ amọran wọn, ati ọna ti a fẹẹ gbe e gba. Ṣugbọn ohun ti mo fẹẹ sọ fun un yin ni pe ti ẹ ba wo gbogbo awọn sinima to n jade kaakiri gbogbo agbaye, ati ohun ti awọn World Health Organizations n sọ, ẹ maa ṣakiyesi pe siga mimu ti n kasẹ nilẹ diẹdiẹ.

“Nitori awọn atunbọtan ailera to maa n fa ni igbesi aye ọpọlọpọ awọn eeyan. Ẹ maa ṣakiyesi pe ẹ ko le ri ki wọn polowo siga lawọn ileeṣẹ amohunmaworan mọ.

“Ti wọn ba tiẹ maa wa gbe ipolowo ọhun jade, wọn a tun fi ikilọ nla sibẹ pe o ṣee ṣe ki awọn to n mu siga tete ku iku aitọjọ, tabi ko ni akoba fun ara.

“Nipa ti ọrọ onisiga yẹn, ohun to n tan tipẹtipẹ ni, nitori pe ibi ti aye n lọ nisinyi niyẹn. Wọn fẹẹ pa Tobako mimu rẹ patapata ni, tabi ki wọn din in ku patapata.

“Ṣe ẹ si mọ pe iṣẹ ti a ṣe, iṣẹ araalu ni, ti ẹ ba si wo pupọ awọn sinima ti a n gbe jade, a n din ọrọ fifa siga kun nitori ipalara to n ṣe fun agọ ara.

“Ṣugbọn lori ti oni oloogun owo de, nigba ti a ba jokoo pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ wa ati awọn alẹnulọrọ, a maa ṣe ipade ni a maa fi ẹnu ko lori ibi ti a duro le lori.”

Ki ijọba ma ṣe ro pe awa oṣere la n kọ araalu nikọkukọ - Jide Kosọkọ

Aworan Omooba Jide Kosoko

Oríṣun àwòrán, Jide Kosoko/Instagram

BBC YORUBA tun tẹsiwaju lati ba ogbontarigi oṣere to tun jẹ alẹnulọrọ pataki ninu ẹgbẹ oṣere TAMPAN, Ọmọọba Jide Kosọkọ sọrọ, lati gbọ erongba tiẹ, baba naa sọ pe awọn agbaagba ẹgbẹ yoo jiroro le aṣẹ ijọba yii lori, ko to di pe awọn fi ẹnu ko sibikan.

Ninu ọrọ rẹ, Ọmọọba Kosọkọ sọ pe “Mi o gba pe awọn fiimu ti a n gbe jade lo n fa awọn ohun to n ṣẹlẹ lawujọ. Ẹlẹẹkeji ni pe, ki ijọba too ronu nipa ohun ti wọn sọ, o ti maa ni awọn nnkan ti wọn ri, ati ohun ti wọn ro.

“Gẹgẹ bi araalu, a ko le sọ pe boya ko ye awa naa, ati pe boya nitori ki awọn nnkan wọnyi ma baa maa ni ipalara lara awọn araalu to n wo fiimu agbelewo, ko ma jẹ gbogbo nnkan ti wọn n wo ni wọn ma maa fi ṣe arikọṣe ti ko dara.

“Amọ ṣa, bo wu ki ijọba ro o to, o di dandan ki awa naa wo ọna ipalara rẹ fun iṣẹ ti wa, nitori pe bi a ba ni awọn ọmọ kan n ṣe janduku, ti a si fẹẹ ba wọn wi lati le jẹ ki wọn mọ pe ohun ti wọn n ṣe ko dara, a ni lati ri janduku ti wọn ṣe yẹn.

“Awọn eeyan gbọdọ mọ janduku ti wọn ṣe ninu sinima naa. Ti a ba sọ pe baba kan kii ṣe ojuṣe rẹ, imukumu bii siga lo n mu kaakiri, to si fi koba ailera ara rẹ, a ni lati ri ẹni to ṣee, ti a si maa ṣe atunṣe ohun to ṣe ninu sinima.

“To bẹẹ ju bẹẹ, bi mo n ṣe n sọrọ yii, mi o ni sọ pe ohun ti ijọba ṣe ko dara tabi pe o dara gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, awa naa ni lati ṣagbeyẹwo ti wa laarin ẹgbẹ wa, ka si mọ ọna ti yoo gba pa wa lara.

“Ti a ba rii pe ipalara yẹn ko dara, awa naa maa sọrọ sita. Araalu lo ni pupọ ninu ọrọ to wa nilẹ yii, awọn ni wọn maa sọ pe bẹẹni tabi bẹẹkọ.

“Aimọye nnkan ti a maa n ṣafihan rẹ ninu sinima, to n jẹ ki a ṣi oju awọn eeyan daadaa lawujọ sii, ti wọn si n kẹkọọ, lati le tọ ọmọ wọn lati ma ba a ya si iru ọna bẹẹ.

“Gbogbo wa ko le dọgba, awọn miran wa to jẹ pe eyi ti ko dara ninu awọn sinima yii lo maa dimu lati lo.

“Eyi ti mo fẹẹ sọ ni pe ki ijọba ma ṣe ro pe awa la n kọ araalu nikọkukọ. Awa la n ṣe afihan ohun ti awọn eeyan n ṣe, eyi to ku diẹ kaato lawujọ lati fi kọ awọn eeyan lẹkọọ.

“Ko to di pe a sọrọ lee lori, awa naa maa jokoo lati ṣagbeyẹwo ibi ati oore to n ṣe. Ohun ti awa ba ri, o di dandan lati sọ ọ jade.”

Nigba to n sọrọ lori igba ti awọn agbaagba ẹgbẹ yoo jokoo ijiroro ipade, Ọmọọba Kosọkọ ni;

“Ẹnikan kii jẹ awa de, a ni awọn ọmọ ẹgbẹ to pọ loriṣiriṣi, a si ni awọn eeyan to jẹ pe wọn n ṣe adari awọn ẹgbẹ yii. Nigba ti wọn ba maa ṣe ipade, o di dandan ki wọn pe iru awa bayii sii lati le ri ohun sọ sii.”

Igbesẹ to dara ni ijọba gbe - Onimọ

Ọkan pataki lara awọn Ọjọgbọn nipa iwoye ohun to n ṣẹlẹ lawujọ, Ọjọgbọn Dhikhrulah Adewale Yagboyaju nigba toun naa n ba BBC Yoruba sọrọ, o ni igbesẹ to dara ni ijọba gbe yii lati le din iwa ibajẹ ku lawujọ si ni.

Ọjọgbọn Yagboyaju ni ojuṣe ijọba ni lati ṣabojuto gbogbo ohun to ba maa jẹ ipalara fun un ati araalu lapapọ, ki wọn si gbe igbesẹ to yẹ.

“Ojuṣe ijọba ni lati wo ohun ti yoo fa igbayegbadun araalu to wa lorileede kan.

Ọkan lara awọn ọna igbayegbadun naa ni igbesẹ ti ijọba Naijiria gbe yii.

“Bi ijọba rii pe ẹnikan n hu iwa to le ni ipalara ba oun funra rẹ, lai tii sọ ẹlẹmiran, ijọba le wa ọna lati daa lọwọ kọ. Ijọba ko le lajusilẹ lati maa wo ẹni to fẹẹ pa ara rẹ niran nitori pe oun lo ni ara rẹ.

“Lara awọn ewu to le mu ipalara ba ọmọnikeji ni ka maa wo iwokuwo tabi gbọ igbọkugbọ. Bi ka maa sọ pe a le di olowo ojiji lai ṣiṣẹ.

“Redio ati tẹlifiṣan lagbara pupọ, ko si ṣee juwe tan, ko si sibi ti ko tan de. Ijọba ni lati ṣọra ṣe pẹlu iru nnkan bẹẹ, nitori pe ohun ti ko dara lo ma maa jẹ ki awọn eeyan mọ.

“Ni iwọnba bi a ṣe mọ, sayẹnsi ko tii fidi rẹ mulẹ pe lotitọ ati lododo ni eeyan le mu eeyan kan lati sọ ọ di owo. Koda bi sayẹnsi gan-an ba fidi rẹ mulẹ, ijọba ko gbọdọ gba laaye.

“Bi awọn nnkan wọnyi ṣe n pa ọmọniyan lara, naa lo tun n sọ awọn kan di ọlẹ. Gbogbo ohun to ba le mu ipalara ba ẹda eeyan ni ijọba ni lati dẹkun rẹ.

“Bi oore ba wa ninu rẹ fun awọn eeyan, ijọba ko nii fa igi lee, nitori pe igbayegbadun ọmọniyan ni ijọba wa fun.

“Ọna keji ni ti siga ati taba. Awọn to n ṣe siga lati fi pawo naa maa n sọ ninu ipolowo wọn pe o ṣee ṣe ki ẹmi ẹni to ba n mu siga ma gun, eyi to tọka si pe ki wọn dẹkun mimu siga awọn eeyan.

“Ewu to tun wa ninu eyi ni pe kii ṣe ẹni to n mu siga nikan lo n ni ipalara fun, bi ko ṣe ẹni to ba tun wa nibi ti wọn ti n mu siga naa yoo tun ni ipalara.

“A ti ri awọn orileede to ti fi ofin de mimu siga nita gbangba. Ẹni to ba wa ro pe ko sẹni to le da oun lọwọ kọ lati mu siga, ko gba kọọtọ yara rẹ lọ lati mu, kii ṣe laarin ero.

“Awọn to n ṣe sinima tun le ṣe awọn nnkan miran lati fi kọ awọn araalu lẹkọọ. Awọn nnkan ti wọn si le fi kẹkọọ pọ gan-an. Ibo lati wo ti wo ti wi pe ẹni to ba n gba bọọlu le di olowo de?

“Ibo lati wo o pe ẹni to n kọrin le di olowo, ibo la ti wo fiimu dokita to n gba ẹmi la tabi agbẹjọro le di olowo de? Birikila, aranṣọ naa le di olowo bi wọn ba mura si iṣẹ, ibo la ti wo awọn fiimu yii de.

“Ibo lati wo awọn fiimu wọnyi de, to fi wa jẹ pe ohun ti a ma maa wo lojoojumọ ni oogun owo ṣiṣe. A ri awọn eeyan to sọ pe bi ẹmi awọn ko ba tiẹ gun, ki awọn saa ti lowo ni. Fun idi eyi, ewu to wa nibẹ pọ ju anfaani to wa nibẹ lọ, iyẹn lerongba temi.”

Ìjọba àpapọ̀ fòfin de oògùn owó àti sìgá mímu nínú fíìmù àgbéléwò

Film

Oríṣun àwòrán, facebook:Best Okoduwa

Ijọba apapọ ti fofin de ṣiṣe oogun owo, siga mimu, atawọn iwa mii ti ko bojumu ninu awọn fiimu agbelewo ni Naijiria.

Alaga ajọ to n bojuto fiimu agbelewo ni Naijiria, NFVCB, Shaibu Husseini, lo fi ọrọ naa lede nibi ipade awọn oṣere fiimu kan nipinlẹ Enugu l'Ọjọru.

Ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria jabọ pe ọrọ lori bi wọn yoo ṣe fopin si siga mimu atawọn iwa buburu mi ni wọn jiroro le lori nibi apero ọhun.

Film

Oríṣun àwòrán, facbook/Best Okoduwa

Apapọ ajọ to n ri si ọrọ fiimu, National Film and Video Censors Board ati ajọ Corporate Accountability and Public Participation Africa (CAPPA) lo ṣe onigbọwọ apero ọhun.

Lara awọn to wa nibi apero naa ni awọn to n kọ fiimu ati oṣere kaakiri Naijiria, to fi mọ awọn adari ẹgbẹ awọn oṣere.

Husseini sọ pe awọn obi, alagbatọ atawọn ti ọrọ kan nipa ere agbelewo ti n sọrọ soke lori awọn irfufẹ fiimu to n jade laye ode oni.

O ni “ọga mi to wa ni ipo yii tẹlẹ kan si minisita eto iroyin ana, Lai Mohammed lati fofin de siga mimu ati oogun owo ninu awọn fiimu wa.

“Lara awọn ofin to daba rẹ ni fifi opin si bi wọn ṣe n pa eeyan joogun atawọn iwa aburui mi lọna ati fọ awọn fiimu wa mọ.

“Lonii, inu mi dun lati fi to yin leti pe minisita fun ọrọ aṣa, Hannatu Musawa ti buwọlu ofin naa.

“Minisita ọhun ti buwọlu ofin to de oogun owo, fifi eeyan joogun, siga mimu atawọ oogun oloro mii ninu awọn fiimu, orin to fi mọ awọn fidio apanilẹrin kekeke ori ayelujara.”

O fi kun pe awọn ti fi ofin tuntun naa ṣọwọ si ileeṣe to n ri si eto idajọ.

Husseini sọ pe ṣiṣẹ afihan awọn iwa aburu naa ninu awọn fiimu n ṣakoba fun awọn ọmọde to ṣẹṣẹ n dagba bọ.