Wo nǹkan mẹ́rin tó lè fa ikú òjijì fún èèyàn

Oríṣun àwòrán, Getty image
Bo tilẹ jẹ pe gbogbo ẹni to wa saye naa lo mọ pe oun yoo pada sọrun lọjọ kan, sibẹ, ko sẹni to wu ko ku iku ojiji.
Eyi lo fi maa n jẹ nnkan iyalẹnu nigba ta a ba gbọ iku ẹni ti nnkan kan ko ṣe tẹlẹ lojiji, yoo maa ṣe eeyan ni kayeefi ni.
Bi eeyan to ti n ṣe àárẹ̀ fun igba pipẹ tabi to ti darugbo ba ku, o le ma jọju.
Ṣugbọn iku ko kan ọjọ ori, nitori ọmọ ọwọ n ku, bẹẹ ni ọdọ langba ti nnkan ko ṣe naa a maa ku lojiji.
Iru iku eyi ni wọn n pe ni iku ojiji (Sudden death).
Dokita Adamu Mohammed, oniṣegun oyinbo nipa aisan ọkan, salaye fun BBC pe bi ọkan eeyan ba daṣẹ silẹ lo saba maa n fa iku ojiji.
Dokita to wa lati Yunifasiti Usman Danfodiyo, nipinlẹ Sokoto naa ka nnkan mẹrin to n fa iku ojiji.
Bí èémí èèyàn bá ń ṣe ségesège

Oríṣun àwòrán, Getty image
Aisan kan wa to maa n daamu ọkan eeyan ‘Arrhythmias’ ni wọn n pe e.
O le jẹ ki iṣẹ ọkan sare pupọ ju tabi ko maa lọra.
Eemi eeyan ti iṣoro yii n da laamu yoo maa ṣe segesege.
Bi ọkan eeyan ṣe n ṣiṣẹ le sare pupọ lasiko teeyan ba n ṣe ere idaraya lọwọ, o si le walẹ nigba mi-in.
Ṣugbọn to ba le ju, iṣoro nla ni.
Awọn nnkan to n fa ki eemi maa ṣe segesege yii ni aṣilo oogun, aisan ọkan to lagbara, ki ara eeyan daṣẹ silẹ patapata ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Dokita Adamu sọ pe awọn eeyan kan wa to jẹ wọn bi ki ọkan maa sare ṣiṣẹ mọ wọn ni.
‘’Ohun ti ko to nnkan lo maa n gbe ọkan iru awọn eeyan bayii soke. Koda, bi wọn ba ṣe wahala ranpẹ to si rẹ wọn, o le ṣakoba fun iṣẹ ọkan wọn.
’’Eyi le mu ki ọkan wọn duro iṣẹ, bi ọkan ba si fi dẹkun iṣẹ ṣiṣẹ, iku ojiji yoo de’’
Bẹẹ ni Dokita Adamu wi.
Bí ẹ̀jẹ̀ kò bá dé ọkàn èèyàn
Adinku ẹjẹ si ọkan eeyan yoo mu ki atẹgun to n de ọkan kere si i.
Bi eyi ba ṣẹlẹ, ẹjẹ o ni i ṣan kari orikerike ara bo ṣe yẹ mọ.
Iṣoro kan leyi fun ọkan, aarẹ ti ko ni i tan lo si maa n fa si ara ẹni to ba n ṣe.
Awọn ohun to n fa a bi Dokita Adamu ṣe ṣalaye ni siga mimu, aisan itọ ṣuga, ẹjẹ riru, ara sisan asanju, aiki-n-ṣere idaraya deede, ijaya ojiji ati aṣilo oogun.
Rọpá-rọsẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty image
Bi ẹjẹ ko ba de apa kan ọpọlọ eeyan, boya latari iṣan to n gbe ẹjẹ debẹ to dí tabi to bẹ, nigba naa rọpa-rọsẹ yoo ṣẹlẹ si eeyan.
Eyi ni ohun ti oyinbo n pe ni stroke.
Rọparọsẹ yii maa n pa awọn ibi kan ninu ọpọlọ eeyan ni.
Bi eeyan ko ba wa tete ri itọju to yẹ gba, o le ṣakoba ti ko ni i gbọ oogun mọ fun ọpọlọ.
Diẹ ninu apẹẹrẹ rọpa-rọsẹ ni keeyan ma le sọrọ daadaa, ki eebi maa gbe eeyan lasiko ti rọparọsẹ naa fẹẹ ṣẹlẹ, ki eeyan ma gbọ ohun ti awọn to wa nitosi rẹ n wi mọ, ki eeyan ma riran daadaa mọ ati ẹfọri ojiji.
Rọparọsẹ a maa mu iku ojiji wa.
Bí ẹ̀dọ̀fóró bá dí

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ohun to maa n fa eyi ni bi iṣan kan ba di ninu awọn eyi to n gbe ẹjẹ kari ara, paapaa lọ sibi ẹsẹ.
Ẹjẹ ti ko le rin kari ara mọ naa yoo lọ sibi ẹdọforo, ẹdoforo naa yoo daṣẹ silẹ.
Bi eyi ba si ṣẹlẹ, atẹgun ti ẹdọforo n gbe kari ara yoo duro.
O le mu ki ọkan ma ṣiṣẹ mọ, o si le ṣakoba fun bi ẹjẹ ṣe n kari ọkan eeyan.
Bi itọju kiakia ko ba si, o le fa iku ojiji.
Ẹyọkan ninu eeyan mẹta ti wahala yii ba ṣẹlẹ si lo maa n ku gẹgẹ bi akọsilẹ rẹ sẹ sọ.
Àpẹẹrẹ ikú
Awọn mi-in le maa kigbe aya didun, ẹlomi-in le ma le mí daadaa mọ, ọkan ẹlomi-in si le maa sare ṣiṣẹ ju bo ṣe yẹ lọ.
Gbogbo eyi lewu pupọ to ba n ṣẹlẹ si eeyan.
Eyi ni awọn dokita fi sọ pe awọn eeyan ti wọn ba ni aisan ọkan ko ṣee fi silẹ.
Wọn ni wọn nilo abojuto nigba gbogbo.
Bí o ṣe lè dènà ikú òjijì
Ẹnikẹni to ba n koju awọn iṣoro ti Dokita Adamu ṣalaye rẹ wọnyi nilo lati tete lọ sileewosan.
Ṣugbọn keeyan too lọ si ọsibitu, ẹni naa kọkọ nilo itọju ti yoo sọ ọkan rẹ to n daku-daji pada.
Ọjọgbọn Kamilu Musa Karaye toun naa jẹ onimọ nipa aisan ọkan lati Yunifasiti Mallam Aminu Kano, nipinlẹ Kano, sọ fun BBC pe awọn to ba wa pẹlu ẹni naa gbọdọ ri i pe ẹni naa ṣi n mí.
O ni ki ẹni to ba mọ nipa ilana ti wọn fi n tẹ aya eeyan (Cardiopulmonary resuscitation), CPR, maa tẹ aya ẹni naa leralera titi ti wọn yoo fi gbe e de ileewosan.















