Ọba ni mí, mi ò lè fẹ́yàwó kan- Portable

Habeeb Okikiola (Portable Omo Olalomi)

Oríṣun àwòrán, Portable / Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lẹyin abọde kootu to ti jẹjọ lori awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun ti wọn lo ba ja lẹnu iṣẹ wọn, Habeeb Okikiola ti a mọ si Portable ti ni ọba loun, oun ko le fẹ obinrin kan ṣosọ bii iyawo.

Ninu ifọrọwerọ kan ti Were olorin ṣe pẹlu sọrọsọrọ ori afẹfẹ ti a mọ si Egungun laipẹ yii lo ti ni ṣina ọla ni ọpọ iyawo fifẹ jẹ.

Portable Ọmọ Olalomi sọ pe oun ki I paarọ iyawo ni toun.

O ni awọn toun kan n ba ṣere ifẹ lasan loun maa paarọ, toun yoo tun mu ẹlomi-in ti akoko ba to.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ''Agboole amuludun ti a wa yii ko si fun nnkan mi-in ju obinrin lọ.

''Awọn obinrin mi-in gan-an ti o ko fẹ a maa ro pe oun fẹ awọn ni. Awọn obinrin kan dẹ wa ti wọn maa n ṣina ọla fun eeyan.

''Emi o ki n paarọ iyawo, ọ̀la mi wa nile. Awọn ti mo kan n ni ibalopọ lasan pẹlu wọn ni ni mo maa n ṣenji.

''Ọba ni mi bi mo ṣe wa yii, oo le sọ fun mi pe ki n fẹyawo kan ṣoṣo.

''Mo nifẹẹ iyawo mi akọkọ ati ikeji, ṣugbọn mi o ti i le sọ nipa iyawo kẹta.

''Pupọ wọn lo fẹẹ gba ipo iyawo kẹta yẹn, ṣugbọn ṣe o le ṣe bi iyawo akọkọ ati ikeji, ṣe o le ma yan ale nigba tọkọ rẹ ba n yan ale.''

Bakan naa ni Portable ṣalaye pe oun n tọju awọn iyawo oun daadaa nitori awọn obinrin naa maa n foriji oun lori ohunkohun toun ba ṣe.

'Mo gbìyànjú láti ṣe Yahoo rí, ìgbà tí wọ́n ń wá mi ní mo pa á tì'

Olorin Zazu naa ko ṣai ṣalaye pe oun ti figba kan gbiyanju lati maa ṣe jibiti ori ayelujara ti a mọ si 'yahoo' ri.

O ni ko too di pe oun lokiki nidii orin loun ti gbiyanju yahoo.

''Ki n ma parọ, oju opo Facebook ati Instaram kan wa ti mo fẹẹ lo nigba yẹn lati fi kọ yahoo ṣiṣe, ṣugbọn ko ṣiṣẹ.

''Bi mo ṣe gbọ pe wọn n wa mi bayii nitori mo ti n lokiki, mo pa oyinbo to wa loju opo naa rẹ ni.''

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji ọdun 2025 ni ileeṣẹ ọlọpaa Ogun kede pe awọn n wa Portable lori ija to ba awọn oṣiṣẹ ajọ alaato ipinlẹ naa ja.

Nibi ija ọhun ni wọn ni oun ati awọn ọmọ ẹyin rẹ ti yọ ada ati awọn nnkan ija mi-in si awọn oṣiṣẹ ijọba naa.

Were olorin pada fa ara rẹ kalẹ fawọn ọlọpaa Eko, awọn iyẹn taari rẹ si Ogun, nibi to ti jẹjọ ni kootu ti wọn si fun un ni beeli pẹlu miliọnu meji naira.

Adajọ kilọ fun un lọjọ naa pe ko ṣọ ẹnu rẹ to ba jade sigboro aye tan.

Igbẹjọ Portable mi-in di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun yii.