Aláàfin Oyo, Ọba AbdulAkeem Owoade bẹ̀rẹ̀ orò ìpèbí lẹ́yìn oṣù kan tó gba ọ̀pá àṣẹ

Alaafin Owoade lásíkò tó ń gba ìwé ẹ̀rí lọ́wọ́ gómìnà Seyi Makinde
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aláàfin ìlú Oyo, Ọba AbdulAkeem Owoade ti bẹ̀rẹ̀ ìgbélé ọlọ́jọ́ mọ́kànlélógójì, Orò Ìpèbí bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Keje, oṣù Kẹta, ọdún 2025.

Olórí òṣìṣẹ́ sí Aláàfin tuntun náà, Rotimi Osuntola ló kéde èyí nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lọ́jọ́ Ẹtì.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹta ni ètò ìgbélé náà yóò sí òpin

Osuntola nínú àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé ó pọn dandan fún ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ Aláàfin láti ṣe Oro Ipebi ọlọ́jọ́ mọkànlélógún náà kí wọ́n tó le wọ ààfin gẹ́gẹ́ bí Aláàfin.

Ó sọ pé, gẹ́gẹ́ bí ìṣe, òfin kónílé ó gbélé yóò wà káàkiri ìlú Oyo láàárín aago mẹ́jọ alẹ́ sí aago mẹ́fà ìdájí ní gbogbo ọjọ́ mọ́kànlélógún náà.

Èyí túmọ̀ sí pé kò ní sí lílọ̀ bíbọ̀ láti aago mẹ́jọ alẹ́ títí di aago mẹ́fà ìdájí àti pé ẹni tó bá tàpá sí òfin náà yóò fojú winá òfin.

Lẹ́yìn èyí ni ayẹyẹ ìwúyè yóò wáyé lọ́jọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹrin, ọdún 2025 ní ìlú Oyo bákan náà.

Ọba Owoade ló bẹ̀rẹ̀ Ipebi lẹ́yìn tó padà sí Nàìjíríà láti orílẹ̀ èdè Canada tó lọ lẹ́yìn tí gómìnà Seyi Makinde kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Aláàfin Oyo tuntun nínú oṣù Kìíní, ọdún 2025.