Eleruwa tuntun gba ọ̀pá àṣẹ, ìwé ẹ̀rí

Gómìnà Seyi Makinde gbé ọ̀pá àṣẹ lé Eleruwa tuntun lọ́wọ́
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gomina Ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti gbe ọpa aṣẹ fun Eleruwa ti ilu Eruwa tuntun Ọba Samuel Adegbola lonii ninu sekitariat ijọba to wa ni agbegbe Agodi n'iluu Ibadan, olu ilu Ipinlẹ Oyo.

Gomina Makinde ni bi o tilẹ jẹ wi pe Ọba Samuel ti lo saa kan ṣaaju gẹgẹ bi Ọba fun ọdun mọkanlelogun ki idajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria to yọ ọ nipo.

Makinde ni idagbasoke ilu Eruwa lo wa gbọdọ ṣe pataki, ko si jẹ Ọba naa logun to si yẹ ko lo iriri rẹ nigba naa lati mu idagbasoke gba ilu Eruwa.

O fi kun pe ilọsiwaju awọn agbegbe atawọn ilu to wa ni ipinlẹ Oyo lo jẹ ijọba ohun logun, idi rẹ niyi ti ijọba Ipinlẹ Oyo ṣe gbe igbese lati ri wi pe iyansipo Ọba ilu Eruwa tuntun gba ilana to tọ.

Gómìnà Seyi Makinde gbé ọ̀pá àṣẹ lé Eleruwa tuntun lọ́wọ́

Gomina naa rọ Ọba Samuel Adegbola lati ri daju wi pe idagbasoke de ba ilu Eruwa nissinsinyi ti ijọba ti fi ọntẹ lu gẹgẹ bii Ọba ilu Eruwa tuntun.

Ninu ọrọ rẹ, Ọba Adegbola ṣeleri lati mu irẹpọ ba gbogbo idile to kopa ninu eto yiyan Ọba ilu Eruwa, o ni pẹlu atunyansipo oun yii yoo fọwọsowọpọ pẹlu awọn Ọba gbogbo ilu to wa ni Ibarapa mejeeje.

Ọdun 1998 ni Ọba Samuel Adegbola ti ṣaaju gba ọpa aṣẹ gẹgẹ bi Eleruwa lẹyin iku Ọba Bolanle Olaniyan to papoda ni ọdun 1994.

Ti o ba gbagbe, ọdun mọkanlelogun ni ọba Adegbola ti kọkọ dari ilu Eruwa ki ile ẹjọ to ga julọ to yọ ọ nipo lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 2019.

Lati ọdun 2019 ni ilu Eruwa ti wa lai ni Ọba Ṣaaju iyansipo tuntun yii.

Makinde yan Eleruwa tí wọ́n yọ nípò padà lẹ́yìn ọdún mẹ́fà

Oba Adegbola

Oríṣun àwòrán, Oyo state government

Gomina ipinle Oyo, Seyi Makinde, ti da Ọba Samuel Adebayo Adegbola, Eleruwa ti Eruwa ti wọn yọ nipo ọba ni 2019 pada si ori itẹ naa bayii.

Atẹjade ti Kọmiṣanna fun eto iroyin ati ilaniloye nipinlẹ Oyo, Dotun Oyelade, fi sita lo fidi eyi mulẹ.

Ẹ o ranti pe Oba Adegbola ti kọkọ dari ilu Eruwa fun ọdun mọkanlelogun, ki ile ẹjọ to ga julọ too yọ ọ nipo naa lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 2019.

Eyi lo mu ori àpèèrè ọba ilu Eruwa ṣofo fun ọdun mẹfa gbako lẹyin ti wọn yọ Ọba Samuel Adebayo Adegbola kuro nipo.

Kí ló dé tí Gómìnà Makinde fi dá Ọba Adegbola padà sórí ìtẹ́?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi Kọmiṣanna eto iroyin ipinlẹ Oyo , Dotun Oyelade ṣe ṣalaye, o ni iwe to wa lati ọdọ Kọmiṣanna ọrọ oye jijé , Ọnarebu Ademola Ojo, fi han pe ori itẹ Eleruwa ti ṣofo latigba ti ẹjọ ti wa ni kootu.

Paapaa julo nigba ti wọn ti da ẹjọ ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo da lori rẹ nu lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2024.

" Yoo wu mi lati ran gbogbo wa leti, pe idile ọmọ oye to n jẹ Laribikusi ko ri eeyan kankan fa kalẹ fun ori itẹ naa laaarin asiko ti ofin la kalẹ fun wọn lati ṣe bẹẹ.

''Abala kẹẹẹdogun, ẹka kin-in-ni ofin kejidinlọgbọn ipinlẹ Oyo lo ṣalaye eyi (Section 15(1) of the Chiefs Law Cap 28 of Oyo State."

"Fun idi eyi, lẹyin agbeyewo to yẹ, gomina ninu ọgbọn inu rẹ, fi aaye silẹ fun idile Akalako lati fa ọmọ oye kalẹ"

Bẹẹ ni Ọnarebu Ademola Ojo, Kọmiṣanna ọrọ oye jije nipinlẹ Oyo, ṣalaye.

O ni lẹyin ayẹwo finni-finni, awọn afọbaje Eruwa fẹnuko, wọn si fa Ọmọọba Adebayo Adegbola kalẹ gẹgẹ bii Eleruwa tuntun.

Bayii si ni ọba to ti fipo silẹ lati ọdun mẹfa sẹyin ṣe pada si ori itẹ bii Eleruwa tuntun.

Díẹ̀ nípa Eleruwa, Oba Adebayo Adegbola

Ọdun 1998 ni wọn fi Ọba Samuel Adebayo Adegbola jẹ ọba ilu Eruwa, nipinlẹ Oyo.

Ilu Eruwa yii ni Olu ilu ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ibarapa. (Ibarapa East)

Nibẹ ni Adegbola ti wa nipo ọba fun ọdun mọkanlelogun gbako ko too di pe ọrọ ipo to wa naa de kootu.

Wọn ni ọna ti Adebayo Adegbola gba di ọba ko tọna rara.

Ile ẹjọ giga ni wọn ti kọkọ gbọ ẹjọ naa, o pada de ile ẹjọ to ga julọ.

Abajade ijokoo kootu agba naa si ni pe ki Eleruwa Adegbola fipo silẹ. Eyi waye lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 2019.

Latigba naa ni Kabiyesi Adegbola ko ti si lori itẹ mọ, ki ori ti yoo jẹ ọba pada naa too gba ipo rẹ pada loṣu Kẹta ọdun2025 yii, pẹlu aṣẹ Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde.