Ọlọ́pàá yabo ibùba ajínigbé, ọwọ́ tẹ afúrasí mẹ́rin pẹ̀lú ohun ìjà olóró

Oríṣun àwòrán, Imo State Police Command
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo ti tẹ afurasi ajinigbe mẹrin pẹlu oniruuru nnkan ija oloro lọwọ wọn.
Lẹyin ti iroyin gbalẹ kan wi pe iṣẹlẹ ijinigbe n waye lera lera lagbegbe Irete atawọn awujọ mii niluu Owerri ni ileeṣẹ ọlọpaa yabo inu igbo Irete nibi ti wọn ti mu awọn afurasi mẹrin ọhun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo, DSP Okoye Henry, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita.
DSP Henry ni eyi wa lara akitiyan ileeṣẹ ọlọpaa lati fọwọ ofin mawọn to wa nibi iṣẹlẹ ijinigbe atawọn iwa ọdaran mii to ti n ṣẹlẹ lera lera lagbegbe ọhun.
Awọn ọlọpaa yawọ inu igbo Irete lẹyin tawọn kan tawọn lolobo ti wọn si mu afurasi Sulieman Ahmed ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, Mohammed Salisu ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ati Gambo Jefta to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn.
Ọmọbibi ipinlẹ Jigawa ni awọn mẹtẹẹta i ṣe nigba ti Gabriel Ogbuzuru to jẹ ẹnikẹrin wọn wa lati Ebonyi.
Nigba ti wọn wo ibuba awọn afurasi naa ni wọn ri ibọn mẹta ọtọtọ pẹlu oriṣiiriṣii ọta ati ada nla mẹta nibẹ.
Awọn afurasi mẹrin wa ni ahamọ ọlọpaa bayii, wọn yoo si foju ba ile ẹjọ laipẹ.

Oríṣun àwòrán, Imo state Police Command
Lẹyin naa ni Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Imo, CP Aboki Danjuma, tun ṣaaju awọn ọlọpaa lanaa ọjọ Aje ọjọ kẹta oṣu Kẹta lati wa awọn ajinigbe to salọ.
CP Danjuma tun paṣẹ wi pe kawọn ọlọpaa maa kaakiri ilu, ki wọn si tun maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn fijilante ki alaafia le jọba nipinlẹ Imo.
O wa fi dawọn araalu loju wi pe gbogbo ibi tawọn ajinigbe atawọn ọdaran mii ba sa pamọ si lawọn yoo ti wa wọn jade.
Ileeṣẹ ọlọpaa tun kepe awọn eeyan ipinlẹ Imo lati wa lojufo bawọn ọlọpaa ṣe n gbiyanju lati pese abo to peye fun wọn.
Ọga ọlọpaa wa rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati ta ọlọpaa lolobo ti wọn ba ti kẹfin iwa ọdaran kankan lagbegbe wọn.
O ni wọn le pe ọlọpaa lori ago sori nọmba 0803 477 3600 tabi 08148024755 ti wọn ba ni nnkan ti wọn fẹ sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa.















