Èmi àti ẹ̀gbọ́n mi, Ayodele Fayose ń yan odì ọ̀lọ́jọ́ pípẹ́, bí a kò bá sọ̀rọ̀ láyé, á pàdé lọ́run - Isaac Fayose
Ọkan lara awọn gbajumọ ori ayelujara ni Isaac Fayose, ẹni to maa n woye nipa ọrọ to n lọ lawujọ wa ati ni orilẹede yii.
Bakan naa, Isaac yii lo jẹ aburo fun gomina tẹlẹ nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose.
Laipẹ yii si ni BBC Yoruba kan si agba onwoye awujọ naa, to si sọrọ nipa idile rẹ ati ajọsepọ rẹ pẹlu ẹgbọn rẹ.
Ko tan sibẹ o, Isaac Fayose tun salaye lori idi to se ni aya marun ati ọmọ meje, to si ni bi oun ba tun aye wa, oun yoo tun tẹ oju opo yii.

Oríṣun àwòrán, Collage
"Emi ko gbe igbesẹ kankan lati ba ẹgbọn mi sọrọ, oun naa ko si gbe igbesẹ kankan lati ba mi sọrọ"
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ajọsepọ to wa laarin rẹ ati ẹgbọn rẹ, Isaac Fayose ni odi ni awọn mejeeji n yan, awọn kii si ba ara awọn sọrọ.
"Kii se dandan ni ki emi ati ẹgbọn mi Ayodele Fayose ba ara wa sọrọ, bi a ko ba sọrọ si ara wa nile aye, a maa pade ni ọrun alakeji.
Emi ko gbe igbesẹ kankan lati ba sọrọ, bẹẹ naa ni ẹgbọn mi ko gbe igbesẹ kankan lati ba mi sọrọ.
Ọmọ iya ti mo ni pọ, dandan kọ ni ki emi ati ẹgbọn mi sọrọ nile aye.
Amọ to ba tun ti rẹ wa, a tun ba ara wa sọrọ, o le to ọdun mẹwa, oun lo ju mi lọ, emi ni aburo rẹ.
Amọ ti mo ba ri, maa kan tẹriba ni pe ẹ pẹlẹ o, to ba wa dahun, tabi ko dahun, maa maa ba temi lọ ni."
Mo ti 'delete' nọmba ipe foonu ẹgbọn mi, n ko le pe laelae"
Ni itẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Isaac Fayose ni oun ko le pe ẹgbọn ounb Ayodele mọ nitori pe oun ko tiẹ ni nọmba ipe ori foonu rẹ mọ.
"Mo ti pa nọmba ipe ẹgbọn mi rẹ lori foonu mi, ko si bi mo se le pe mọ, n ko si setan lati pe lori aago.
Aarin emi ati awọn ọmọ iya wa to ku gun rege amọ omiran wa ninu ọmọ iya wa ti ẹgbọn mi ko ba sọrọ fun bi ọdun marun sẹyin.
Idi to se ni agidi bẹyẹn ni gomina to ti se ri, oun nikan ni gomina laarin wa, idi ree ti ko fi fẹ ba wa sọrọ.
Mo si maa n beere pe ti ko ba ba wa sọrọ, se o jẹ bi Ọlọrun ni?"
"Agidi ẹgbọn mi Osokomọlẹ pọ, ọmọ lile bii okuta ni amọ o fẹran awọn eniyan"
Aburo Ayodele Fayose ni agidi n ba ẹgbọn oun ja, tori naa lo se n huwa to n hu.
"Agidi ẹgbọn mi Osokomọlẹ pọ pupọ, ọmọ lile ni, agidi pọ, tori naa ni wọn se n pe e ni Osoko.
Lootọ ni wọn sọ pe gbogbo awọn ọmọ bibi ilu Ekiti lo ni agidi amọ ti ẹgbọn mi yii yatọ.
Baba wa naa ni agidi, a le sọ pe oun ni ẹgbọn mi fi agidi rẹ jọ.
Amọ ẹgbọn mi ni oju aanu pupọ, o si fẹran awọn eeyan ipinlẹ Ekiti pupọ."
"Bi ẹgbọn mi ba ni oun fẹ dije fun ipo aarẹ Naijiria, oun ni maa tẹle"
Yoruba ni ti a ba n sunkun, a maa n riran, ija to wa laarin Isaac Fayose ati ẹgbọn rẹ ko buru debi eto oselu o.
Idi ni pe Isaac fọwọ gbaya fun BBC Yoruba pe ọmọ ẹni kii se idi bẹbẹrẹ, ka lọ fi ilẹkẹ si idi ọmọ ẹlomiran.
Bi ẹgbọn oun ba si kede pe oun fẹ dije fun ipo aarẹ Naijiria, oun setan lati gbaruku ti oi.
"Ija ti mo n ba ẹgbọn mi ja, kii se ija iku bikose ija ifẹ.
Nigba to dije fun ipo gomina, a kii sọrọ sira wa, amọ owo apo mi ni mo n na fun awọn eeyan pe ki wọn dibo fun ọmọ iya mi.
O ku ọdun meji ki ijọba rẹ tan, ni a sẹsẹ bẹrẹ si ni sọrọ, ija wa kii se bii ti ka ku, ija ifẹ ni."
"Idile baba kan, iyawo meje ni mo ti jade, idi ree ti mo se jẹ ki obinrin marun bimọ meje fun mi"
Nigba to n salaye lori idi to se jẹ ki obinrin pupọ bimọ fun oun, Isaac Fayose ni idile olobinrin pupọ ni oun ti wa.
"Idile Baba kan, iyawo meje ni mo ti jade wa, idi ree ti mo se pinnu pe maa jẹ ki obinrin pupọ bimọ fun mi, ki n le mọ eyi to mọ ọmọ tọju.
Iya marun, ọmọ meje ni mo ni, awọn ọmọ miran wa ti kii se pe mo mọọmọ pinnu lati bi amọ mo kan ni ajọsepọ pẹlu iya rẹ ni, to si di oyun.
Emi ko gbagbọ ninu ka maa sẹyun, tori naa mo ni lati sun sokoto mi soke, lati tọju ọmọ naa.
Nigba ti mo wa nilu Oyinbo, mo ni ọrẹbinrin ti a jọ n jade, o loyun fun mi, laarin ọdun naa, mo tun ni ọrẹbinrin miran, oun naa tun loyun fun mi.
Mo bi ọmọ meji silu oyinbo, ki n to ko pada wa si Naijiria, nigba ti mo si de naa, mo tun ni ọrẹbinrin miran silu Ibadan, ti oun naa si tun loyun fun mi."
"Ọkàn mi balẹ̀ pẹ̀lú ìyá márùn-ún, ọmọ méje ju oníyàwó kan lọ, tí mo bá tún ayé wá, ojú òpó yìí ni máà tọ̀"
Isaac Fayose ni oun pinnu lati se igbeyawo nigba to di pe ọmọ oun ti pe mẹta lọdọ iya mẹta, ti oun ko si fẹ maa ko ọmọ kiri mọ.
Mo wa fẹ obinrin kan nilu Abuja nisu lọka, amọ lẹyin ọdun kan, o ni oun ko se mọ, to si lọ sile ẹjọ.
Lẹyin ọdun meji, ile ẹjọ tu wa ka, mo sẹsẹ wa fẹ iyawo miran, ti mo si ko gbogbo wọn papọ.
Ọkan emi ti mo ni iya marun, ọmọ meje balẹ ju ọkan awn ọrẹ mi miran, ti wọn ni iyawo kan soso lọ.
Ti mo ba tun aye wa, oju opo yii ni maa tun tọ, iya pupọ, ọmọ pupọ.






