Ewú ńlá ni Peter Obi àti Kwankwaso jẹ́ fún PDP ní ìdìbò 2023 – Fayose

Oríṣun àwòrán, others
Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose, ti sapejuwe awọn oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati NNPP gẹgẹ ewu nla fun aṣeyori ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo lọdun 2023.
Fayose, nigba to n sọrọ lori tẹlifisan Channels salaye pe Obi ati Kwankwaso ni agbara lati le ṣe idiwọ fun ẹgbẹ oṣelu ẹgbẹ PDP lati bori ninu eto idibo aarẹ.
Gẹgẹ bii o ṣe sọ , o ni oun ko ni igbagbọ pe Obi le ri ida mẹdọgbọn ibo kojọ ninu eto to n bọ ati pe ko le bori ibo apa guusu iwọ oorun ati guusu ila oorun orilẹede Naijria.
“Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni mii, olori ni mi sugbọn mo ti n sọ fun tin tipẹ, a ko gbọdọ ma otitọ ọrọ. Ewu ni Obi jẹ fun wa sugbọn n ko ni igbagbọ pe yoo ni ida mẹdọgbọn ibo awọn ipinlẹ. N ko tako Obi, mo nifẹ rẹ, olori to daa ni.
“Ẹ jẹ ki sọ fun yin, aarun jẹjẹrẹ ni Obi jẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP, ko si aniani nibẹ. E jẹ ki salaye nkan fun yin, ni guusu iwọ oorun, awọn eyan le ma fẹ gbọ otitọ ọrọ sugbọn n ko ri bii ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe fẹ bori ibo ni apa ibi.
“Ẹni to ba tan wa, ko tẹsiwaju. Koda n ko ri ibi a ṣe le bori ni guusu ila oorun orilẹede yii pẹlu.
O ni sugbọn oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NNPP, eyiu Rabiu Kwankwaso ni agbara lati mu inira ba bibori ni apa ariwa ila oorun bakan an.
“Ni apa aarin ariwa, ko si isẹ pupọ lati ṣe nitori oludije PDP ati APC ko wa lati ibẹ sugbọn a ko gbọdọ gba gbe Kwankwaso, aarun jẹjẹrẹ miiran.
Anfani wa fun PDP ti wọn ba le fọwọsowọpọ pẹlu Obi ati Wike
Fayose salaye siwaju pe anfani wa fun ẹgbẹ oṣelu PDP ba le fọwọsowọpọ pẹlu Peter Obi ti Labour Party, ki wọn si tun bu omi pa awọ pẹlu gomin ipinlẹ Rivers, Nelson Wike.
O ni igbesẹ yii yoo fun ẹgbẹ oṣelu PDP ni ọpọlọpọ anfani lati bori ninu eto idibo lọdun 2023.
“Fifi ọwọ sowọpọ pẹlu Obi jẹ nkan to da pupọ, ti wọn ba si omi pa awọ to wa laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ati Gomina Nelson Wike ti ipinlẹ Rivers.”
Ìdì rèé tí mi ò ṣe ní sọ̀rọ̀ àbùkù sí Tinubu láíláí – Fayose

Oríṣun àwòrán, @GuardianNigeria
Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayodele fayose ti sọ pe oun ko ni sọrọ kobakungbe si oludije fun ipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu.
Fayose, to jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle, Channels.
O ni “Jẹ ki n sọ fun ọ, ti awọn eeyan ba n reti ki n sọrọ kobakungbe nipa Tinubu lati fi han pe mi o ṣatilẹyin fun,mi o ni ṣe bẹẹ rara.”
Fayoṣe ni, bo tilẹ jẹ pe awọn gomina atawọn oloṣelu kan ni iha Ariwa ni ariyanjiyan pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari, wọn kii sọrọ kobakungbe si.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, Tinubu jẹ ọkan lara awọn aṣaju ilẹ Yoruba, nitori naa oun ko ni maa sọrọ abuku si nitori wọn ko si ninu ẹgbẹ kan naa.
Mi o ni bu Tinubu lailai

Oríṣun àwòrán, @GovAyoFayose
Gomina Ekiti tẹlẹri naa ṣalaye pe oun ko ni bu Tinubu lailai.
O ni “To ba jẹ pe ọna kan ti mo le fi han gbogbon eeyan pe ọta Tinubu ni mi ni ki n maa bu gẹgẹ bii ọmọ Yoruba, mi o ni ṣe bẹẹ lailai.”
“Ọjọ ori Atiku Abubakar ati Bola Tinu ti le ni aadọrin ọdun, ki lo de ti awọn mejeji fi n joko papaọ lati jiroro ti wọn ko si maa yọ ada si ara wọn? Ẹ yọ mi kuro lara awọn ti yoo maa bu Tinubu.”
“Mi o ni bu Atiku.... bẹẹ naa ni mi o ni bu Tinubu.”
Fayose sọ pe lootọ ni ipo Aarẹ tọ si iha Guusu Naijiria ni bayii ti Buhari to wa lati Ariwa yoo pari saa rẹ to lẹyin ọdun mẹjọ.
O pari ọrọ rẹ pe oun yoo ṣiṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP bo tilẹ jẹ pe aarin ẹgbẹ ọhun ko gun rege.












