Kí ló gbé ọ̀gá ẹgbẹ́ àwọn awakọ̀ ìpínlẹ̀ Oyo, Auxiliary délé ẹjọ́?

aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Oyo ti wọ ọga igbimọ alamojuto awọn gareeji ọkọ, PMS, nipinlẹ Oyo, Mukaila Lamidi, ti ọpọ mọ si 'Auxiliary' lọ ile ẹjọ lori ẹsun pe o n wu iwa ọdaran, to ni i ṣe pẹlu biba nnkan aworan ìpolongo ẹgbẹ oṣelu APC jẹ.

Wọn wọ Auxiliary lọ si ile ẹjọ Magistrate, to n joko ni agbegbe Iwo Road, eyii ti Tawio Oladiran le waju rẹ.

Ọlọpaa to n jẹri ni ileẹjọ naa, Sunday Fatola fi ẹsun mẹfa silẹ fun olujẹjọ ọhun, to si ni awọn ẹsun naa lodi si ofin orilẹede Naijiria.

Lara awọn ẹsun naa ni pe o lẹdi apo pọ pẹlu awọn kan, ti wọn si n ṣe ikọlu si aworan ipolongo ẹgbẹ oṣelu APC.

Olupẹjọ tẹsiwaju pe, "Ni nnkan bii aago meje alẹ ku iṣẹju mẹwaa lọjọ naa, iwọ Mukaila Lamidi, ẹni ọdun mọkanlelọgọta (61), pẹlu awọn kan ti wọn ti sa lọ bayii, jọ lẹdi apo pọ, ẹ si ba patako ipolongo ibo oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu jẹ”.

Auxiliary wa sọ fun ileẹjọ pe oun ko jẹbi ẹsun kankan ninu ẹsun mẹfa ti wọn fka si oun lẹsẹ.

Adajọ Taiwo Oladiran wa gba oniduro Auxiliary pẹlu owo ti iye rẹ to ẹgbẹrun lọna ogọrun un marun un ati oniduro meji.

Bakan naa lo wa sun igbẹjọ si ọjọ keji, oṣu keji ọdun 2023.