Mi ò ní ọ̀rọ̀ láti sọ lórí "Muslim-Muslim ticket" Ọlọ́run nìkan ló mọ ẹni tí yóò tún Nàìjíríà ṣe– Kumuyi

Oríṣun àwòrán, PASTOR W F KUMUYI
Alufaa agba ijọ Deeper Christian Life Ministry, Ọmọwe William Kumuyi, ti sọ pe oun ko ni bu ẹnu atẹ lu ẹgbẹ oṣelu kankan tabi ṣatilẹyin fun wọn nitori ẹni to n du ipo Aarẹ ati igbakeji rẹ jẹ Musulumi.
Kumuyi lo fi ọrọ naa lede lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni papakọ ofurufu Danbaba Sundati, to wa niluu Jalingo, nipinlẹ Taraba.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, Ọlọrun nikan lo le sọ ẹni ti yoo tun Naijiria ṣe, ati pe eeyan ko le ṣe ju Ọlọrun lọ, nitori naa ki awọn araalu fun Ọlọrun laaye lati ṣiṣẹ rẹ.
O ni “Mi o fẹ maa bu ẹnu atẹ lu ẹnikẹni tabi kin ẹnikẹni lẹyin, ohun ti a le ṣe ni ki a maa gbadura si Ọlọrun ko fun wa ni adari rere ti yoo ba wa tun ilu ṣe.”
“Oun nikan lo mọ ohun ti ẹniẹni le ṣe ti wọn ba de ori alefa.”
“Oniṣe iyanu ni Ọlọrun, a ko le sọ ọna to maa gbe ọrọ rẹ gba tabi ohun ti ẹnikẹni yoo ṣe ti wọn ba gori alefa tan.”
Kumuyi tẹsiwaju pe “A mọ bi Ọlọrun ṣe mu ileri rẹ ṣe nipasẹ ọba Nebukadinesari ati gbogbo awọn ọba to jẹ lasiko ninu Bibeli.”
“Fun idi eyii, a fẹ fa gbgobgo rẹ le Ọlọrun lọwọ, ki a si gba awọn ọmọ Naijiria laaye lati dibo yan ẹnikẹni ti ọkan wọn ba fẹ.
Bi ọrọ Muslim-Muslim ticket ṣe ṣẹ
Ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu keje ọdun 2022 yii ni ọrọ ‘Muslim-Mislim ticket’ fẹ da wahala silẹ laarin awọ oloṣelu ni Najiria atawọn ọmọlẹyin Kristi.
Eyii ko ṣeyin bi Bola Tinubu to n dije du ipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC to si jẹ Musulumi ṣe yan Kashim Shettima gẹgẹ bii igbakeji rẹ ti wọn yoo jọ dije, ti oun naa si jẹ Musulumi bakan naa.
Pupọ ninu awọn Kritẹni, paapaa awọn ọmọ ẹgbẹ CAN, lo lodi si igbesẹ naa, amọ awọn mii gbagbọ pe adari rere lo ṣe pataki si awọn araalu, kii ṣe ki wọn maa ni ariyanjiyan lori ọrọ ẹsin.












