Ọ̀mùtí Ṣójà wa ọkọ̀ pa ọ̀gá rẹ̀ nínu báráàkì ní Eko

Oríṣun àwòrán, Others
Corporal ni ileeṣẹ ikọ ọmọogun ori ilẹ ni Naijiria, Abayomi Ebun ti fi ọkọ pa adari eto iṣunna ni ileeṣẹ ikọ ọmọogun, Ọgagun A.O James pẹlu ọkọ rẹ.
Iṣẹlẹ naa lo waye ni agbegbe NAFRC ni Old Barracks ni ilu Eko.
Corporal Ebun to n ṣiṣẹ ni ẹka kan naa pẹlu ọga rẹ lo fi ọkọ kọlu, ti Ọgagun James si gba ibẹ lọ.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?

Oríṣun àwòrán, Others
Oṣojumikoro ni Ọgagun James lo n fi ẹṣẹ rin lọ si ile rẹ ninu barrack,Corporal Ebun fi ọkọ kọlu lati ẹyin.
Kete ti iṣẹlẹ naa waye ni wọn ti gbe lọ si ileewosan ninu barrack ọhun amọ ti o ti papoda.
Ọkan ninu awọn to ba awọn oniroyin sọrọ nipe Ebun ti mu ọti yo nigba to n wa ọkọ, ni ijamba naa fi waye.
Nibayii, wọn ti tii mole ni ọgba awọn ologun titi iwadii yoo fi pari.








