Ègbé ni fún ẹnikẹ́ni tó bá gbìyànjú láti yẹpẹrẹ àkọ́bí mi: Iyabo, ìdí rèé – Obansajo

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, @KwankwasoRM

Aarẹ Naijiria nigba kan ri, Oloye Olusegun Obasanjo ti ṣe ileri pe oun yoo tẹsiwaju lati maa ṣatilẹyin fun ẹkọ awọn ọmọdebinrin.

Obasanjo tun ṣalaye bo ṣe bẹrẹ si n ṣatilẹyin fun ẹkọ awọn ọmọdebinrin lẹyin ti ọkan lara awọn aburo rẹ obinrin fi ile ẹkọ silẹ lati lọ sile ọkọ.

Baba iyabo lo sọ ọrọ naa nibi ayẹyẹ ayajọ ọjọ aisan itọ ṣuga lagbaye, eyii to waye ni gbọgan Olusegun Obasanjo Presidential Library, to wa niluu Abeokuta.

O ni “Nigba ti mo bẹrẹ ile ẹkọ ni abule wa, mo ni aburo obinrin kan to bẹrẹ ile ẹkọ lẹyin ọdun meji ti mo bẹrẹ.”

“Mo gbe ipo kinni ni ọdun meji mi akọkọ, oun naa si gbe ipo kinni ni kilaasi rẹ, amọ lojiji ni baba wa sọ pe ile idana ni gbogbo ẹkọ awọn obinrin maa n pari, o si mu kuro nile ẹkọ naa, amọ mo tẹsiwaju ninu ẹkọ mi.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Obasanjo, Kehinde Akinyemi fi lede lo ti ṣalaye ọrọ naa.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, igbesẹ baba rẹ ọhun mu iyatọ gedegbe wa laarin idagbasoke oun ati aburo rẹ ọhun.

O tẹsiwaju pe “Lasiko ti mo maa fi pada de lati ilẹ Gẹẹsi, iyawo mi ti fi aburo mi fun ọkọ eyii to mu ko ma pari ẹkọ rẹ.”

“Lati ọjọ naa ni mo ti ṣeleri pe mo maa ṣe gbogbo ohun to yẹ ni ikawọ mi lati ri daju pe awọn ọmọdebinrin lọ sile ẹkọ nitori ko si ootọ kankan ninu ọrọ ti awọn eeyan maa n sọ pe inu ile idana ni ẹkọ awọn obinrin maa pari si.”

Obasanjo pari ọrọ rẹ pe kii ṣe ohun to tọ ki awọn eeyan maa ran ọmọ ọkunrin nikan lọ sile ẹkọ, ko si ya ọmọbinrin sọtọ.

O ni “Egbe ni fun ẹnikẹni to ba gbiyanju yẹpẹrẹ akọbi mi, Iyabo.”

“Iyabo yoo fi oju irufẹ ẹni bẹẹ gbolẹ.”