Wo ohun tí Mbeuno, atamátàsé Cameroun sọ nípa àǹfàní tó ní láti kópa ní ìdíje 'World cup'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Atamatase ẹgbẹ agbabọọlu Brentford, Bryan Mbeuno ti sọ pe idunu nlanla ni yoo jẹ fun oun bi oun ba lee bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ kankan fun orilẹede Cameroun ni idije ife ẹyẹ agbaye.
Agbabọọlu ẹni ọdun mẹtalelogun naa wa lara awọn agbabọọlu ti wọn pe lati ṣoju Cameroun ni Qatar nibi ti wọn yoo ti maa koju Brazil, Serbia ati Switzerland.
Mbeunmo sọ fun BBC Sport Africa pe, “O ti n wu mi lati igba ewe mi lati kopa ni idije agbaye.
“Ki n kan maa rin kiri papa iṣire pẹlu ọpọ ero to n woran yoo fẹrẹ mu mi ya were.”
Papa iṣire Al Janoub to gba ẹgbẹrun lọna ogoji ero iworan ati papa iṣire Lusai iconic stadium to gba ẹgbẹrun lọna ọgọrin ni Cameroun yoo ti gba ifẹsẹwọnsẹ wọn.
Laipẹ yii ni Mbeuna yi oju pada lati bẹrẹ si ni ṣoju orilẹede Cameroun lẹyin to ti gba bọọlu fun ikọ agbabọọlu ọjẹ wẹwẹ orilẹede France ṣaaju.
Ọmọ ilu Douala ni baba rẹ, nibẹ si tun ni ilu gbajumọ agbabọọlu ni Samuel Eto’o. Eto’o di alaga ajọ ere bọọlu Cameroun lọdun 2021.
Kii ṣe ipa kekere ni Eto’o kan lati rii pe Mbeuno di agbabọọlu fun Cameroun.
Awọn mọlẹbi rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Mbeuno ni ipinnu to nira diẹ lo jẹ fun oun lati fi ta ilu iya oun nu lati wa gba bọọlu fun Cameroun.
O ni oun mọ ikọ agbabọọlu Cameroun daadaa nitori pe nigba ewe loun ti maa n wo idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika, AFCON.
“Nitori pe mio ti gba bọọlu fun ikọ ọjẹ wẹwẹ orilẹede France ri, ti mo si gbe ni France, O ṣoro pupọ ṣugbn mo ti wa si Cameroun lọpọ igba.”
“Inu baba mi dun gidigidi. Inu mi dun lati kopa ninu eyi nitori baba mi, ati ẹbi mi. Inu baba mi si dun gidigidi.”
Ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Uzbekistan ni Mbeuno ti kọkọ gba bọọlu fun Cameroun. Goolu meji sodo ni wọn si fi fidirẹmi ki South Korea to gbo ewuro si oju wọn pẹlu goolu kan si odo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
“Awọn ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti mo kọkọ gba niyi, ẹkọ pupọ ni mo si kọ.”
Bi o tilẹ jẹ wi pe orilẹede Cameroun ja fafa ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ to kọkọ gba ni idje ife ẹyẹ agbaye.
Lọdun 1990 lo pegede gẹgẹ bi orilẹede akọkọ ni Afrika ti yoo wọ ipele quarter finals ni idije ife ẹyẹ agbaye.
Amọṣa, lẹnu lọwọlọwọ yii, Cameroun ko ja fafa to bayi ni idije ife ẹyẹ agbaye.
Lati ọdun 1994, ifẹsẹwọnsẹ marundinlogun ni Cameroun ti gba ni idije ife ẹyẹ agbaye, ẹyọ kan ṣoṣo pere ni wọn tii bori.
Goolu kan ṣoṣo ni wọn fi bori Saudi Arabia, Samuel Eto’o lo gba goolu naa sinu awọn lọdun naa ni 2002.
Ifẹsẹwọnsẹ mẹwaa ni wọn ti fidirẹmi ti wọn si gba ọgbọn goolu sinu awọn wọn.
Cameroun yoo ṣi gba ifẹsẹwọnsẹ lọrẹsọrẹ kan pẹlu Panama lọjọ kejidinlogun oṣu kọkanla ọdun 2022 lati gbaradi fun idije ife ẹyẹ agbaye.
Ipin G ni Cameroun wa, orilẹede Switzerland ni yoo koju lọjọ kẹrinlelogun oṣu kọkanla, ki wọn to koju Serbia ni ọjọ kejidinlọgbn oṣu kejila.
Btazil ni wọn yoo koju gbẹyin ni ipin naa ni ọjọ keji oṣu kejila ọdun 2022.












