Balógun ikọ̀ Tunisia, Khazri gbàgbọ́ pé ìdíje World Cup yóò ṣẹnure

Khazri ati agbabọọlu Brazil kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Brazil na Tunisia ni 5-1 loṣu kẹsan an ṣugbọn Wahbi Khazri ni eyi ko ni itumọ si ilepa awọn ni Qatar

Balogun ikọ agbabọọlu orilẹede Tunisia, Wahbi Khazri gbagbọ pe Tunisia ni awọn amuyẹ gbogbo to yẹ lati ta biọbiọ ni Qatar 2022.

Eyi ni igba kẹfa ti wọn yoo maa kopa ni idije ife ẹyẹ agbaye, eleyi ti yoo maa waye lorilẹede Qatar lọtẹ yii.

Ni igba marun un iṣaaju ti orilẹede naa to wa ni iha ariwa Afirika kopa ni idije naa, ipele akọkọ ni wọn ti jabọ.

Eyi to si jẹ wi pe ninu ifẹsẹwọnsẹ marundinlogun ti wọn ti gba ni ife ẹyẹ agbaye lapapọ, meji pere ni wọn tii bori.

–Alakọkọ wọn ni ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Mexico lọdun 1978 ati eyi ti wọn gba pẹlu Panama lọdun 2018.

Lọtẹ yii, Tunisia yoo tun gbiyanju lati lepa wiwọ ipele komẹsẹ o yọ fun igba akọkọ.

O n wu Khazri pe ki ikọ Tunisia o bẹrẹ daadaa pẹlu ifẹsẹwọnsẹ wọn meji akọkọ pẹlu Denmark ati Australia nitori ikọ France ni wọn yoo koju ni ifẹsẹwọnsẹ wọn to gbẹyin ni ipin D ti wọn wa ni ipele akọkọ idije ife ẹyẹ agbaye tọdun yii.

“Mo gbagbọ pe a lee kogoja ninu ipin yii. Muṣemuṣe ikọ wa gba muṣe, nitori ikọ to ti wa papọ fun igba pipẹ ni.”

Khazri sọ fun BBC Sport Africa pe, “Ikọ France le juwa lọ, o si daju pe ife ẹyẹ naa ni wọn n le ni tiwọn,

Denmark ati Australia pẹlu ta lẹnu daadaa. o ṣi ni igbagbọ pe a lee kogoja lọ sinu ipele keji bi a ba lee gbiyanju ṣe daradara ni ifẹsẹwọnsẹ meji akọkọ ti a ba gba.

“Ṣaaju idije ife ẹyẹ agbaye to waye kẹyin lorilẹede Russia, a gba bọọlu daadaa ni ifẹsẹwọnsẹ wa pẹlu Spain ati Portugal,

A si tun na Croatia lọdun naa to jẹ ọdun kan lẹyin ti wọn ṣe ipo keji ni idije naa.

Orilẹede Tunisia ya ọpọlọpọ lẹnu nigba ti wọn gba idije olorilẹede mẹrin ife ẹyẹ Kirin cup loṣu kẹfa.

Nibi ti wọn ti na Chile ati Japan to gbalejo idije naa ki wọn to po ẹkọ iya fun Comoros pẹlu goolu kan si odo ki Brazil to wa ja ewe iya fun wọn pẹlu goolu marun un si ẹyọ kan ni awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba loṣu kẹsan an lati gbaradi fun ife ẹyẹ agbaye.

Khazri sọ pe anfani nlanla ni ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Brazil, to ti gba ife ẹyẹ naa ni igba marun un, jẹ fun awọn bi o tilẹ jẹ wi pe alubami ni wọn lu awọn.

“O fun wa lanfani lati mọ awọn ibi ti a ku si, ati lati mu awọn ẹkọ pataki lori awọn ibi ti a ti nilo lati ṣe atunṣe fun itẹsiwaju.”

Awọn agbabọọlu Tunisa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọna si Qatar.....

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tunisia ko koju eyikeyi awọn ogunagbongbo orilẹede agbabọọlu kankan l’Afirika lasiko ifẹsẹwọnsẹ ati kopa fun idije ife ẹyẹ agbaye naa loṣu kẹta. Orilẹede Mali ni wọn pade lati wọ idije naa

Ikọ Tunisia labẹ akọnimọọgba Jalel Kadri fi goolu kan si odo gbẹyẹ mọ Mali lọwọ.

Bo tilẹ jẹ pe ọmọ ile Mali, Moussa Sissako lo gba goolu naa si awọn ile ara rẹ ki alamojuto ifẹsẹwọnsẹ naa to tun fun un ni kaadi pupa lẹyin iṣẹju diẹ si eyi.

Pẹlu bi ipin ti wọn wa ṣe le si ni iwoye awọn onworan bọọlu, Tunisia yoo ni lati ṣiṣẹ gidigidi.

Awọn atamatase orilẹede France bii Kylian Mbappe, tabi Karim Banzema to ṣẹṣẹ gba ami ẹyẹ Ballon d’Or ko mọ ila ti goolu kọ.

Denmark pẹlu na an tan bi owo pẹlu England ni ipele to kangun si aṣekagba ni idije ife ẹyẹ ilẹ Yuroopu to waye lọdun to kọja.

Lori beba, orilẹede Australia nikan lo daju pe Tunisia lee fi ẹyin rẹ balẹ.

Nitori lori atẹ agbelewọn FIFA fun awọn orilẹede to n gba bọọlu lagbaye, ipo kejidinlogoji ni Australia wa eyi si jẹ ipo mẹjọ lẹyin ipo ti Tunisia wa.

Ifẹsẹwọnsẹ to lamilaaka pẹlu ikọ Les Bleus ti France

Balogun ikọ Tunisia, Wahbi Khazri

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Khazri dara pọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Montpellier loṣu kẹfa

Awọn iranti ọdun 2018

Tunisia ati Khazri n pada lati kopa ni idije ife ẹyẹ agbaye lẹyin ti wọn kopa leyi to waye kọja lorilẹede Russia.

Nibẹ orilẹede England na wọn pẹlu goolu meji si ẹyọkan, belgium gbo ewuro si oju wọn pẹlu marun un si meji, ki wọn to wa na Panama ni meji si ẹyọ kan.

“Awọn ikọ to ga ju wa lọ la koju;

Bi o tilẹ jẹ pe a ni awọn abamọ kan lori ti ifẹsẹwọnsẹ wa pẹlu England nigba ti Harry Kane gba gbọọlu sinu awọn wa nigba ti ifẹ̀sẹwọnsẹ naa n lọ si opin, nitori iṣubu ni ere aṣiṣe diẹ niwaju awọn ikọ nlanla bẹẹ.”

Wahbi Khazri n yọ lẹyin to gba goolu wọle Panama

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ifẹsẹwọnsẹ mọkanlelaadọrin ni Khazri ti gba fun Tunisia, idije ife ẹyẹ adulawọ marun un lo si ti gba pẹlu goolu mẹrinlelogun.

Lẹyin to gba goolu wọle Belgium ati Panama ni idije ife ẹyẹ tọdun 2018, Khazri ni agbabọọlu Tunisia to ni goolu to pọ julọ ni idije ife ẹyẹ agbaye.

O si ni oun n ni ero ati lo gbogbo anfani to ba fi ara han fun oun ni idije naa lorilẹede Qatar.

“O ko lee sọ boya eyi gan ni idije ife ẹyẹ agbaye ti o lanfani ati gba kẹyin.

Mo lero pe ikọ mi yoo duro daadaa nitori pe mo mọ pe a lee ṣe nnkan to ga gidigidi bi gbogbo wa ba duro deede.”