Rẹfírí pín 'red card' mẹ́wàá níbi Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kàn lórílẹ̀ede Argentina

aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbabọọlu mẹwaa ni Refiri to n dari idije bọọlu naa le jade nibi ifẹsẹwọnsẹ idije Champions Trophy to waye laarin ikọ Racing Club ati ikọ Boca Juniors lorilẹede Argentina.

Ohun tuntun nipe, ifẹsẹwọnsẹ ọhun tete wa sopin lẹyin to ku agbabọọlu mẹfa lori papa fun ikọ Boca Juniors latari bii wọn ṣe ti le mẹfa jade laarin wọn.

Igbesẹ yii mu wọn kede ikọ Racing Club gẹgẹ bii ikọ to gba ife ẹyẹ Champion Trophy nitori wọn ti n bori ikọ Boca Juniors pẹlu ami ayo meji si ẹyọ kan, ki awuyeawuye to bẹ silẹ laarin wọn.

Ofin ajọ agbaye to n ri si ere bọọlu ni pe, ifẹsẹwọnsẹ ko ni le tẹsiwaju ti ikọ agbabọọlu ko ba ni eeyan meje lori paapa.

Rogbodiyan yii waye lẹyin ti agbabọọlu Racing Club, Carlos Alcaraz gba bọọlu si awọn, to si morile apa ọdọ awọn ololufẹ ikọ Boca Juniors lati lọ kẹdun ọkan rẹ.

Kini ọ̀rọ̀ naa wa yọri si?

Kete ti o gbe igbesẹ ọhun ni awọn agbabọọlu Boca Juniors suru bo, ti wọn si faleti, ti wọn si tun gba bọọlu mọ.

Eyi lo mu ki Rẹfiri Facundo Tello fun Alcaraz jade pẹlu awọn agba bọọlu marun un lati ikọ Boca to wa lori papa pẹlu agbabọọlu meji mii, Dario Benedetoo ati Carlos Zambrano Jonathan Galvan ti ikọ Racing naa fi ẹnu gba kaadi pupa ọhun.

Kete ti ifẹsẹwọnsẹ naa tẹsiwaju ni awọn meji miran, Sebastian Villa lati ikọ Boca juniors ati Johan Carbonero lati ikọ Racing kọlu arawọn, ti wọn si bẹrẹ ariyanjiyan eyi to mu Rẹfiri Tello tun pin kaadi fun awọn mejeeji.

Ko pẹ si igba naa, bi isẹju marun un, ni ọmọ agbabọọlu Boca Juniors miiran, Alan Varela naa tun gba kaadi pupa