Àwọn agbébọn tú àwọn ọmọdé mọ́kànlélógún sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Katsina

aworan

Oríṣun àwòrán, others

Pẹlu idunnu ati ayọ ni awọn mọlẹbi awọn ọmọde mọkanlelogun fi ṣe opin ọsẹ lẹyin ti awọn agbebon tu wọn awọn ọmọ silẹ ni ipinlẹ Katsina

Awọn ọmọde ọhun ni awọn agbebọn kan palẹmọ wọn lori oko kan ti wọn ti dako ni agbegbe Mairuwa ni ipinlẹ naa lọsẹ to kọja.

Saaju ni ajọ UNICEF ti ra ọwọ ẹbẹ si ijọba lati ṣe ohun to tọ lia fi koko sofọ lori itusilẹ awọn ọmọde naa

Ninu atẹjade kan ti asoju ajọ lorilẹede Naijiria, Ms Christian Munduate fi ransẹ si awọn akọroyin, sapejuwe igbesẹ awọn ajinigbe naa gẹgẹ nii ohun ibanujẹ ọkan.

O ni kobojumu rara nitori ko si ibi awọn ajinigbe yii ko ti ma ṣo sẹ wọn, ti wọn si pa ọpọlọpọ lẹkun.

“Ijinigbe ni ilẹ ẹkọ, ni ilegbe wa, lori oko ati bi gbogbo ti Ọlọrun lodi si.

“Ko ye ki awọn ọmọde maa la awqọn nnkan bayi kọja rara nitori ohun buruku ni ati pe o yẹ ki ijọba da bobo awọn ọmọ wọnyi ni

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, SP Gambo Isah kede pe awọn ọmọde ọhun ti ri itusilẹ gba, ti wọn si ti pada si ọdọ awọn mọlẹbi, sugbọn iwadii si n tẹsiwaju lati fi ofin de awọn ajinigbe naa.

O ni ọkunrin mẹrin ati obinrin mẹtadinlogun ni awọn gba pada lọwọ ajinigbe naa, ti ọjọ ori wọn ko si ju ọdun mẹdogun ati ọdun mẹrindinlogun.

“Pẹlu idunu ati ayo ni mo fi n kede itusilẹ awọn ọmọde mẹtadinlogun ti awọn ajinigbe kan ṣe ikọlu si nigba ti wọn sisẹ lọwọ lori oko ni agbbe Kamfanin Mai Lafiya ni ipinlẹ Katsina.

“Gbogbo wọn wa ni alaafia, ti wọn si pada si ọjọ awọn mọlẹbi wọn.

“Lọjọbọ ọsẹ to kọja, ni ago meji abọ, ni a gbo pe awọn ajinigbe ṣe ikọlu si awọn ọmọde ọhun ti wọn si palẹmọ wọn mọ.

“Kete ti a gbọ ni a ti bẹrẹ iwadii wa, ki a to wa ri gba silẹ sugbọn iwadii wa si n tẹsiwaju.

Àwọn ajínigbé pa méjì nínú wa, wọ́n tú àwa méjì sílẹ̀"

Ọkùnrin kan tó ṣe ìdúpẹ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì lẹ́yìn tó bọ́ lọ́wọ́ ajínigbé ní márosẹ̀ Ibadan/Eko

Awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ọkan lara awọn eeyan ti wọn ji gbe loju ọna marosẹ Eko si Ibadan ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lakata awọn ajiigbe naa.

Ṣaaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe awọn ajinigbe kọlu awọn arinrinajo loju ọna maroṣe naa lopin ọsẹ.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 si ni isẹlẹ naa waye.

Ọkunrin naa, ninu fidio kan to ti gba ori ayelujara bayii, lo ṣi aṣọ loju eegun ọrọ ọhun lasiko to n ṣe idupẹ ninu ṣọọṣi Global Impact Church.

Nibẹ si lo ti salaye bo ṣe ṣadede ko si ọwọ awọn ajinigbe naa.

O ni awọn ajinigbe naa di ọkọ ti oun wa ninu rẹ niwaju ati ẹyin, wọn ko jẹ ki awọn kọja.

O ni bẹẹ ni wọn si n dunkoko pe awọn yoo yinbọn lu ẹnikẹni to ba ta felefele.

"Wọn yinbọn pa eeyan meji loju mi"

Ọkunrin naa tun ṣalaye pe “Wọn ni ka paaki ọkọ wa, ki a si jade ninu rẹ ati pe awọn yoo yinbọn pa ẹnikẹni to ba jade kẹyin ninu mọto naa.”

“Ni tootọ, awọn ajinigbe naa yinbọn pa ẹni to jade kẹyin ninu ọkọ ọhun.”

“Lẹyin naa ni wọn ni ki a maa lọ sinu igbo, bi a ṣe n lọ ni adari wọn sọ pe ki a duro.

Mo ro o boya ki n salọ sinu igbo lasiko naa, amọ mo gbọ ohun kan leti mi to sọ pe ki n ma dan wo.

Nitori naa mo fi ara mi balẹ, mo si bẹrẹ si n gbadura ni ifedefọ.”

"Alaye ree lori bi mo ṣe gba itusilẹ"

Lori bo ṣe ri itusilẹ gba lọwọ awọn ajinigbe naa, o ni lẹyin ti wọn ti yinbọn pa eeyan meji, ni wọn tu oun atawọn meji mii silẹ.

O ni “Adari wọn na ọwọ si mi ati awọn meji mii, o ni ki a pada, bi a ṣe gba itusilẹ niyẹn.”

“Ọlọrun ninu aanu rẹ lo ko mi yọ lẹnu kiniun.”

"Awọn ajinigbe ti n pa lara awọn ti wọn ji gbe"

Ninu ifọrọwerọ kan laipẹ yii, ibatan ọkan lara awọn ti wọn gbe loju ọna marosẹ naa sọ pe wọn ti n pa lara awọn eeyan naa.

O ni ti awọn ajinigbe naa ba pe mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe lori aago lati beere owo, ti awọn mọlẹbi ọhun ko si ka ọrọ wọn kun, ẹni ti wọn ji gbe naa yoo fi iku ṣe ifa jẹ.

O wa pari ọrọ rẹ pe ogun miliọnu naira ni wọn beere gẹgẹ bii owo itusilẹ ẹgbọn oun.