Ọta ìbọn ajínigbé dá ọgbẹ́ sáàrin orí mi, mò ń gba ìtọjú lọ́wọ́ - Agbaje

Agbaje

Oríṣun àwòrán, Adigun Agbaje

Ọjọgbọn Jimi Agbaje, tii se igbakeji ọga agba tẹlẹ ni fasiti Ibadan tawọn ajinigbe ji lọjọ Ẹti amọ to gba itusilẹ lọjọ Aiku ti sọrọ sita.

Agbaje ati awọn obinrin mẹta ni awọn ajinigbe ji loju ọna marose Ibadan silu Eko lọjọ Ẹti amọ ti wọn gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe naa lọjọ Aiku.

Nigba to n fi ọrọ idupẹ rẹ sita, Ọjọgbọn Agbaje tun salaye ohun ti oju rẹ ri ni akata awọn ajinigbe naa.

Ninu ọrọ idupẹ ọhun, ti ọmọ rẹ, Adewale Agbaje fọwọsi lọjọ Aje, Agbaje wa dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan to duro tii lasiko isoro atawọn afẹnifẹre gbogbo.

Ọta ibọn ajinigbe da ọgbẹ nla si mi lori, mo n gba itọju lọwọ - Adigun Agbaje

Ọjọgbọn Adigun Agbaje wa sisọ loju rẹ pe ọta ibọn awọn ajinigbe naa to gba gilaasi iwaju mọto oun kọja, kọja lẹgbẹ ori oun.

O ni ọta ibọn naa si lo da ọgbẹ nla si oun lori, eyi ti oun ti n gba itọju lori rẹ nile iwosan lẹyin ti oun bọ ni ahamọ awn ajinigbe naa.

“Ojumọ tuntun lo mọ mi loni, inu mi si dun pe mo si wa laye lẹyin ti mo lo ọjọ meji ni ahamọ wọn.

Irọlẹ ọjọ Aiku ana ni awọn ajinigbe naa tu mi silẹ ninu igbo kijikiji to wa laarin ipinlẹ Oyo ati Ogun naa.

Kan mi wa lọ sọdọ awọn awọn eeyan marun yoku ti mo fi silẹ ni ahamọ awọn ajinigbe naa, ọdọkunrin meji ati ọdọ̀binrin meji pẹlu agbalagba kan.

Mo si dupẹ pe ọta ibọn to gba iwaju mọto la ori mi kọja ko pa mi amọ o kan fi ọgbẹ siwaju ori mi ni.

Bakan naa ni ọta ibọn ọhun da iho nla si aarin fila ti mo de, koda n ko mọ titi di aarọ ọjọ Satide nigba ti mo ri ẹjẹ to ti gan mọ fila mi.”

“Mo mọ riri aayan awọn eeyan lati ri pe idunadura pẹlu awọn ajinigbe seso rere”

Ọjọgbọn Agbaje wa salaye pe oun si n se ẹkunrẹrẹ ayẹwo ilera ara oun lọwọ, yoo si gba oun ni akoko lati ri aaye dupẹ lọwọ awọn ẹbi, ara ọrẹ ati afẹnifẹre fun aduroti wọn.

Amọ Atẹjade idupẹ naa wa mọ riri atilẹyin awọn ọga agba to ti dari fasiti Ibadan kọja atawọn to si wa nibẹ lọwọlọwọ.

Lara wọn ni Ọjọgbọn Olufemi Bamiro, Isaac Adewole, Idowu Olayinka ati Kayode Adebowale.

Bakan naa lo tun nawọ imoore rẹ si awọn alabasisẹpọ rẹ ni fasiti Ibadan atawọn faisiti miran nilẹ yii ati loke okun, pẹlu awọn akẹkọọ rẹ atijọ atawn to si wa nile ẹkọ bayii.

Agbaje ni oun mọ riri aayan wọn lati ri daju pe idunadura wọn pẹlu awọn ajinigbe naa seso rere, ti oun fi ri idande gba lọjọ Aiku.

O wa mọ riri inawo wọn pẹlu to fi mọ awọn asaaju ijọba, awọn ologun atawọn osisẹ agbofinro miran.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Agbaje tí wọ́n jí gbé ní márosẹ̀ Ibadan/Eko ti gba ìtúsílẹ̀

Ọjọgbọn Adigun Agbaje

Oríṣun àwòrán, other

Awọn ajinigbe ti tu Ọjọgbọn Adigun Agbaje, ẹni to ti fi igba kan ri jẹ Igbakeji ọga agba fasiti ilu Ibadan silẹ.

Gẹgẹ bi ọrọ ti Ọjọgbọn Rẹmi Ayede, to jẹ ọga agba ẹka imọ nipa oṣelu ni fasiti Ibadan se sọ, lọjọ Aiku ni wọn tu u silẹ, ti o si ti n gba itọju nileewosan.

Awọn ajinigbe ji eekan onimọ nipa ẹkọ oṣelu naa ni opopona marosẹ Ibadan si Eko lọjọ Ẹti.

Nnkan bii agogo mẹfa irọlẹ lawọn ajinigbepawo naa dabu rẹ lọna nitosi agbegbe Sat Guru Maharaji loju ọna marosẹ ọhun.

Ajínigbé ya bo márosẹ̀ Ibadan sí Eko, wọn pa ọlọ́pàá kan, jí igbákejì ọ̀gá àgbà tẹ́lẹ̀ ní fásitì Ibadan àti akẹ́kọ̀ọ́ MAPOLY méjì gbé lọ

Agbaje atawọn agbebọn

Igbakeji ọga agba tẹlẹ nile ẹkọ fasiti Ibadan, Ọjọgbọn Adigun Agbaje atawọn eeyan mii ti ko sọwọ awọn ajinigbe.

Bakan naa ni wọn tun ji akẹkọ ile ẹkọ gbogbonse Moshood Abiola nilu Abeokuta (MAPOLY) gbe lọ pẹlu Agbaje lasiko isẹlẹ naa.

Orukọ awọn akẹkọ MAPOLY naa ni Orekoya Oluwatobi ati ẹgbọn rẹ obinrin, Aminat, ti oun lọ gba lẹta isinru ilu NYSC nile iwe ẹkọ naa.

Opopona marose Ibadan silu Eko ni isẹlẹ naa ti waye ni deede aago mẹfa irọlẹ ọjọ Ẹti nigba tawọn ajinigbe sẹburu ọna lẹba ibudo Guru Maharaji nilu Ibadan.

Awọn ero to n kọja ni opopona naa lo kọkọ figbe ta pe wọn ri awọn ọkọ mẹta kan ti wọn gbe soju titi, wọn si ilẹkun wọn silẹ lai ri ero ẹyọ kan ninu rẹ.

Awọn eeyan naa si lo n lọgun pe o seese ko jẹ pe awọn ajinigbe lo ti ko awọn ero inu ọkọ naa lọ.

Amọ ajọ kan to wa fun iwadi iroyin Foundation for Investigative Journalism (FIJ) ti fi ikede sita lori isẹlẹ naa loju opo ayelujara rẹ.

Ajọ naa wa sisọ loju rẹ pe Ọjọgbọn Agbaje to n lọ sisẹ isinmi rẹ nile ẹkọ fasiti Olabisi Onabanjọ wa lara awọn ero ti awọn ajinigbe naa ko, lasiko to n pada bọ silu Ibadan.

“Miliọnu lọna aadọta naira lawọn ajinigbe n beere fun idande Agbaje”

Wayi o, Ajọ FIJ tun salaye pe awọn ajinigbe to ji Ọjọgbọn Agbaje ti kan sawọn mọlẹbi rẹ ni ọjọ Abamẹta lati beere owo idande rẹ.

Miliọnu lọna aadọta naira si ni awọn ajinigbe naa n beere fun, ki wọn to ji ọjọgbọn naa silẹ.

Bakan naa la gbọ pe wọn ti kan si awọn mọlẹbi awọn akẹkọ meji tile ẹkọ Mapoly ti wọn ji gbe naa, ti wọn si n beere miliọnu mẹwa naira lori ikọọkan wọn.

Ajinigbe gbẹmi ọlọpaa kan, òmíràn fara gbọgbẹ́ lasiko isẹlẹ ijinigbe naa

Iroyin naa ni awọn ajinigbe ọhun gbẹmi awọn osisẹ ọlọpaa kan nibi isẹlẹ naa.

Awọn osisẹ ọlọpaa to wa lagbegbe Toll Gate nilu Ibadan ni wọn lọ dahun si ipe pajawiri araalu pe ajinigbe n sọsẹ lọwọ lẹba ibudo Guru naa.

Idi si ree tawọn igun mejeeji fi doju ibọn kọ ara wọn lẹba fasiti Dominion to wa lagbegbe naa.

Asiko yii si ni ẹmi ọlpaa kan bọ, tawọn ajinigbe si raye gbe awọn ero ti wọn fẹ ji gbe lọ.

Àkọlé fídíò, Ojo Ade: Ìṣẹ́ àti òṣì bá mi fínra, mo fọdún mẹ́wàá ṣe àìsàn láìsí ẹni tó mọ̀

A ti bẹrẹ iwadii amọ kawọn eeyan agbegbe ti isẹlẹ ijinigbe naa ti waye maa fura sawọn eeyan to ba ni ọgbẹ ọta ibọn lara - Ọlọpaa Oyo

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wayi o, ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fidi isẹlẹ ijinigbe naa mulẹ ninu atẹjade kan to fisita lọjọ Abamẹta.

Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Adewale Williams si ti pasẹ pe ki iwadi alagbara bẹrẹ lati sawari bi isẹlẹ ijinigbe naa se waye.

O tun pasẹ pe Igbakeji Kọmisana ọlọpaa to wa ni ẹka ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni ko lewaju iwadii naa.

Atẹjade ọhun, ti alukoro ileesẹ ọlọpaa Oyo, Adewale Osifeso fọwọsi ti wa rọ awọn ẹgbẹ alaanu, awọn onisegun ibilẹ atawọn olugbe adugbo ti isẹlẹ naa ti waye lati maa foju sọri.

O tun gba wọn nimọran lati maa se akiyesi awọn eeyan to ba ni ọgbẹ ọta ibọn, ki wọn si fi iroyin naa to ọlọpaa leti.

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo wa tun fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni oun padanu osisẹ kan lasiko isẹlẹ naa.

“Ọkan lara awọn osisẹ ọlọpaa to wa ni agọ ọlọpaa Toll Gate, to wa lara awọn osisẹ ọlọpaa to lọ dahun ipe pajawiri nipa ijinigbe naa ti jade laye.

Bakan naa ni osisẹ ọlọpa miran fara pa yannayanna lasiko ikọlu ijinigbe naa, amọ to n gba itọju lọwọ nile iwosan.

Lara awọn eeyan to si dide si ipe pajawiri naa ni ikọ ọlọpaa to n gbogun ti iwa ọdaran, ikọ ọlọpaa to n se aato, awọn ikọ ọlọpaa kogberegbe atawọn ọdẹ ibilẹ.”

Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo fikun pe oun ti gba ọkọ mẹrin ti wọn gbe kalẹ nibi isẹlẹ naa, ti oun si tun ko aloku ọta ibọn nilẹ lorisirisi.

Adigun Agbaje

Oríṣun àwòrán, Adigun Agbaje

Ta ni Ọjọgbọn Adigun Agbaje tawọn ajinigbe ji gbe lọ?

Odu ni Ọjọgbọn Adigun Agbaje ni awujọ awọn olukọ fasiti Ibadan ati lorilẹede Naijiria lapapọ.

Agbaje jẹ akọsẹmọsẹ Ọjọgbọn ni ẹka imọ nipa oselu nile ẹkọ faisiti Ibadan.

Lati ọdun 1998 si lo ti bẹrẹ isẹ olukọ nile ẹkọ fasiti naa titi di oni.

Agbaje jẹ oludari ẹka imọ apapọ fun eto ẹkọ nipa awujọ (Dean, Faculty of Social Science) laarin ọdun 2003 si 2005.

Bakan naa lo tun jẹ igbakeji ọga agba fun ẹka eto ẹkọ nile ẹkọ fasiti Ibadan naa laarin ọdun 2006 si 2010.

Ọjọgbọn Adigun Agbaje lo tun n se idanilẹkọ nipa ilana isẹ iwadii fawọn ileesẹ ologun pẹlu awọn ileesẹ agbofinro mii atawọn ileesẹ miran ti isẹ wọn fara pẹ ti ologun nilu Abuja laarin ọdun 2001 si 2013.

Lara awọn iwe ti Ọjọgbọn Adigun Agbaje kọ sita ni The Nigeria Press, Hegemony and the Social Construction of Legitimacy atawọn iwe miran lorisirisi.

Ọpọ awọn akẹkọọ ati alabasisẹpọ rẹ lọgba fasiti Ibadan si lo nifẹ Ọjọgbọn naa nitori iwa ikonimọra rẹ.