Èèyàn 141 kú lórí afárá lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tí wọn ṣàtúnṣe rẹ̀

Afara ẹlẹsẹ naa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ko din ni eeyan mọkanlelogoje to ku ninu iṣẹlẹ ijamba afara ẹlẹsẹ kan to ja lẹkun iwọ oorun orilẹede India.

Afara naa ja ni ipinlẹ Gujarat ni irọlẹ ọjọ Aiku.

Aṣoju ijọba kan lẹkun naa sọ pe awọn obinrin, ọmọde atawọn arugbo lo pọ julọ lara awọn to padanu ẹmi wọn ninu ijamba afara to ja naa.

Afara alasorọ, iyẹn Suspended bridge ni afara yii, o si ga ni iwọn ẹsẹ bata ọtalelẹẹdẹgbẹrin o din mẹfa (754ft).

Awọn oyinbo Amunisin ilẹ Gẹẹsi lo kọ afara yii si ori odo Machchu ni ilu Morbi ni nkan bii ọgọrun ọdun o le sẹyin.

Ni nnkan bii ọsẹ kan sẹyin ni wọn ṣi afara naa pada lẹyin ti wọn pari iṣẹ atunṣe lori rẹ.

Ohun ti a gbọ ni pe ero pọ lori afara naa lasiko to ja yii nitori asiko ayẹyẹ ajọdun Diwali ti wọn maa n ṣe lorilẹede naa ni.

Awọn ọlọpaa, ologun atawọn oṣiṣẹ adoola ẹmi gbogbo ni wọn ti n ṣiṣẹ idoola ẹmi ati igbofinro nibẹ loru mọju.

“Apọju ero lori afara naa lo jẹ ko ja”

Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi nibi ijamba naa

Oríṣun àwòrán, AFP

Awọn oṣiṣẹ nibẹ sọ pe, nnkan bii eeyan mẹtadinlọgọsan ni wọn ti doola ẹmi wọn ninu ijamba naa, gẹgẹbi awọn alaṣẹ ṣe sọ.

Eeyan kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe, “Ọpọlọpọ ọmọde ni wọn n jẹ igbadun isimi ọdun Diwali ti wọn si wa si ibi yii gẹgẹ bi arinrinajo afẹ”

“Gbogbo wọn ṣubu lori ara wọn. Afara naa ja nitori apọju ero lori rẹ.”

Nnkan bii aadọta ninu awọn to ku yii lo jẹ obinrin ati ọmọde.

Awọn eeyan loju omi

Oríṣun àwòrán, AFP

Minisita kan lagbegbe naa ṣalaye pe iyalẹnu nla ni iṣẹlẹ naa jẹ o nitori pe iṣẹ atunṣe ṣẹṣẹ pari lori afara naa ni ‘lọsẹ to kọja.’

Titi di owurọ ọjọ Aje, awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ṣi n wa awọn eeyan to ṣeeṣe ko ṣi wa laye ninu awọn eeyan to ja bọ sinu omi odo naa nigba ti afara naa ja.

Iroyin n sọ pe o ṣeeṣe ki iye awọn to ku ṣi pọ sii

'Wọn ṣi afara naa lai si iwe aṣẹ pe iṣẹ rẹ ti kun oju iwọn'

awọn irinṣẹ idoola ẹmi nibi ijamba afara naa

Oríṣun àwòrán, AFP

Afara ẹlẹsẹ alagbekọ naa ti wa lori odo Machchu fun igba pipọ, koda o ti ju ọgọrun ọdun lọ

Ọgbẹni Sandeep Jhala to jẹ alaga ijọba ibilẹ Morbi ṣalaye fun awọn akọroyin pe awọn ko tii mọ ohun to fa a ti afara naa fi ja tabi iye awọn to wa lori rẹ ni pato.

“Ni oṣu kẹta ọdun yii, wọn gbe e ti pa lati lee ṣe atunṣe lori rẹ. Amọṣa ijọba agbegbe naa ko tii fun ni iwe aṣẹ pe iṣẹ ti wọn ṣe lori rẹ ti pe to yẹ ki wọn fun un lẹyin atunṣe yii.”

Ijọba orilẹede naa ni iwadii ti bẹrẹ

Awọn fidio to jẹyọ lori ayelujara ṣe afihan bi awọn eeyan ṣe n rọ mọ awoku afara naa bi awọn oṣiṣẹ addola ẹmi ṣe n gbiyanju ati doola ẹmi wọn. Awọn kan gbiyanju lati rọ mọ awọn okun ti wọn fi so afara naa, awọn miran si gbiyanju luwẹ de bebe odo naa.

Odo naa ati afara to ja nibẹ

Ipinlẹ Gujarat ni ipinlẹ ibinibi olotu ijọba orilẹede India, Narenda Modi. Modi ti kede owo gba ma binu fun awọn ẹbi awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ. O ni ijamba naa jẹ eyi to ba oun ninu jẹ gidigidi.

Awọn alaṣẹ ijọba lorilẹede naa ti ṣeleri lati gbe iwadi kalẹ lẹkunrẹrẹ lati mọ ohun to wa jija afara naa. Ohun ti ọpọ n beere bayi ni pe boya wọn ṣe gbogbo awọn ayẹwo to yẹ lẹyin ti wọn pari atunṣe afara naa ki wọn to ṣii.

Minisita fun ọrọ abẹle, Harsh Sanghavi sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati fi ẹsẹ ofin iwa ọdaran tọ gbogbo ọrọ ijamba naa.