Wo ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nídìí fídíò ọ̀mùtí ọlọ́pàá tó gbòde

Oríṣun àwòrán, Muyiwa Adejobi
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti fesi lori ọlọpaa ọmuti kan ti fidio rẹ gbori ayelujara, to ti muti yo lai le da rin mọ.
Muyiwa Adejobi, to jẹ alukoro agba nileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ti gbe igbesẹ ti o yẹ, tawọn si ti ba ọlọpaa to ṣe aṣemaṣe yii wi ni ibamu pẹlu ofin ileeṣẹ ọlọpaa.
Adejobi sọ pe lọdun 2020 ni ọlọpaa yii mu ọti yo ninu fidio tawọn eeyan ṣẹṣẹ wa n pin kaakiri bayii.
O ni nigba naa lọhun ti fidio yii jade, awọn gbe igbesẹ to yẹ lati ri pe Insipẹkọtọ naa koju ibawi ni ilana to yẹ.
"Iyalẹnu ni bawọn eeyan ṣe n gbe fidio yii sita lai ṣe alaye ohun to ṣẹlẹ gan"
Gẹgẹ bi Adejobi ṣe wi, iyọniniṣẹ ati igbesẹ ibawi to yẹ fun ọlọpaa yii ni wọn ti ṣe lati igba ti fidio yi kọkọ waye.
Muyiwa sọ pe o jẹ iyalẹnu bi awọn eeyan ṣe wa n gbe fidio yii sita lai ṣe alaye ẹkunrẹrẹ nipa ohun to ṣẹlẹ gan.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni ye ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ ni gbogbo igba ti wọn ba wa lẹnu iṣẹ ati igba ti wọn ko ba ṣi lẹnu iṣẹ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post











