Ọwọ́ ọlọ́pàá Ogun tẹ olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn Eiye lásìkò tó ń lọ ṣọṣẹ́

 Olamide Olabode

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi

Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, Olamide Olabode, lasiko ti oun atawọn ẹmẹwa rẹ n lọ ṣe ikọlu.

Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ ninu atẹjade kan pe Oke-Iganmu, lagbagbe Ilaro si Papalanto ni ọwọ ti tẹ afurasi naa.

O ni wọn mu lasiko ti ikọ akọmọṣẹ ọlọpaa n kaakiri agbegbe Ilaro.

Bi ọwọ ṣe tẹ afurasi naa

Oyeyemi ni “Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii ni ọwọ wa atẹfurasi naa ni Oke-Iganmu, lagbegbe Ilaro/papalanto.”

“Ori alupupu ni a ti ri afurasi ọhun pẹlu awọn meji mii, amọ ni kete to ri awọn ọlọpaa lo fo kuro lori alupupu naa to si salọ sinu igbo toun ti apo kan to wa lọwọ rẹ.”

“Awọn ọlọpaa le, wọn si mu, amọ awọn ẹmẹwaa rẹ salọ pẹlu alupupu ti wọn gun.”

Alukoro ọlọpaa ṣalaye siwaju si pe nigba ti wọn yoo fi yẹ apo naa wo, ibọn, ọta ibọn marun un, ọbẹ ati egbogi igbo ni wọn ba ninu rẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ, nigba ti wọn fi ọrọ wa lẹnu wo, o ni ọmọ ẹgbẹ okunkun Eiye ni oun, ilu Agodo ni awọn n lọ lati lọ ṣọṣẹ ki akara oun to tu sepo.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti ni ki wọn tare afurasi naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si ọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun fun iwadii ni kikun.