Mọ̀ síi nípa fídíò ayédèrú owó N5000 àti N2000 tó ń káàkiri ní Nàìjíríà

Ayederu Owo

Oríṣun àwòrán, Twitter

    • Author, Chiagozie Nwonwu
    • Role, BBC Disnformation Unit

Fidio kan n kaakiri bayii to n ṣe afihan ayederu beba owo ẹgbẹrun marun un naira odindi ati beba ẹgbẹrun meji naira odindi eyi to jẹ pe o kọkọ bọ sori ayelujara ni ọdun 2020.

Lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹwaa ọdun 2022 ni Banki apapọ orilẹede Naijiria CBN ti kọkọ kede pe irọ ti ko labula ni fidio naa nigba to kọkọ jade lọdun naa to si rọ awọn ọmọ Naijiria lati fi ẹjọ ẹnikẹni to ba n pin fidio naa sun awọn agbofinro.

beba owo naijiria

Oríṣun àwòrán, other

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Ninu fidio ayederu naa, ohun obinrin kan n lọ labẹlẹ to si n sọ pe onibara kan lo wa lati wa fi owo naa pamọ, eyi to ni iye rẹ to miliọnu mẹtadinlogun naira ni ẹka banki to ti n ṣiṣẹ.

Ẹya owo Naira mẹjọ lo wa lorilẹede Naijiria, ninu eyi ti ẹgbẹrun kan naira odindi ti jẹeyi to ga julọ.

Pẹlupẹlu atẹjade yii ti banki apapọ Naijiria fi sita, fidio yii ṣi n ja ranyinranyin kiri lori ayelujara. Fun apẹrẹ iru eleyii to jade lọjọ kejidinlogun oṣu keje ọdun 2021.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Bi fidio yii tun ṣe bẹrẹ si nii tan lọdun 2021 lo mu ki ki ajọ aṣewadi iroyin ofege kan nilẹ Afrika, ti orukọ rẹ n jẹ Africa Check o ṣe iwadi lati bu omi pa ina iroyin ofege ti fidio naa n gbe kiri logunjọ oṣu keje ọdun 2021. Nibẹ ni wọn ti tọ ipasẹ fidio naa lọ si oju opo iroyin ayelujara kan ti orukọ rẹ n jẹ, Oriental Times.

Ayẹwo ti ẹka to n bomi pa ayederu iroyin ni BBC, iyẹn BBC Disinformation Unit ṣe pẹlu fihan pe oju opo atẹdahun lori ayelujara, iyẹn link ti fidio yii n ba jade ko tii dipa. Lootọ oju opo ileeṣẹ iroyin Oriental Times ti kogbawọle, wọn si ti n kiri oju opo ayelujara wọn fun tita bayii.

aworan oju opo Oriental times bayii

Oríṣun àwòrán, screenshot

Fidio ofege yii tun ti n kaakiri lori oju opo Twitter, Tiktok, Whatsapp ati Facebook bayii.

Ẹka to n bomi pa ayederu iroyin ni BBC, iyẹn BBC Disinformation Unittọpasẹ ẹda fidio naa to n kaakiri bayii de ọdọ eeyan kan to n lo oju opo tiktok pẹlu adirẹsi @smartgabriel. Eeyan ẹgbẹrun mọkandinlẹgbọn lo n wọ tẹle @smartgabriel loju opo tiktok rẹ.

Ni ọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹwaa ọdun 2022 ni wọn fi fidio si oju ayelujara. Eeyan miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun lo ti wo fidio yii (Views), o le lẹgbẹrun mẹẹdogun to ti pin kaakiri (Shares), ẹgbẹrun mọkandinlọgbọn lo ti tẹka mo fẹran rẹ le e lori (like) ti ẹgbẹrun meji miran si ti sọ ero wọn lori rẹ (comments).

Skip TikTok post
Allow TikTok content?

This article contains content provided by TikTok. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read TikTok cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites. TikTok content may contain adverts.

End of TikTok post

Lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹwaa ọdun 2022 ni banki apapọ Naijiria, CBN kede pe oun yoo ṣefilọlẹ ayipada oju owo Naijiria loṣu kejila ọdun 2022.

Awọn owo odindin ti ayipada yii yoo kan ni ọgọrun naira odindi, igba naira odindi, ẹẹdẹgbẹta naira odindi, ati ẹgbẹrun kan naira odindi.

Ko si si igba kan ti banki apapọ naa mẹnuba titẹ ẹgbẹrun meji olodindi ati ẹgbẹ marun un odindi ninu atẹjade to fi sita.