Ẹ yé gbé ìròyìn irọ́ kiri, kò sí àdó olóró kankan ní Abuja – Ọlópàá

Muyiwa Adejobi

Oríṣun àwòrán, Juliana Francis

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nílùú Abuja ti ní kí àwọn ènìyàn fọkàn balẹ̀ pé kò séwu lóko àfi gìrì aparo.

Àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá l’Abuja, Olumuyiwa Adejobi fi síta ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn pé àwọn kan ń gbé ìròyìn kiri lórí ayélujára àti àwọn Iléeṣẹ́ ìròyìn kan pé àwọn kan ti fi àdó olóró káàkiri Abuja.

Adejobi ní àwọn tó gbé ìròyìn bẹ́ẹ̀ kàn fẹ́ dá ìbẹ̀rù bojo sọ́kàn àwọn ará ìlú lásán ni nítorí kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀.

Ó ní gbígbé irú ìròyìn báyìí kò ní àǹfàní kankan láti máa dá ìbẹ̀rù sí àwọn ènìyàn lára lórí ìròyìn òfégè.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà ní ààbò tó péye wà ní ìlú Abuja tí kò sí sí fífi àdó olóró sí àwọn ibì kankan ní agbègbè ọ̀hún.

Ó wá rọ àwọn olùgbé ìlú Abuja àti ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀ láti kọ tí ọ̀gbọin sí àwọn ìròyìn tí àwọn ènìyàn ń gbé kiri láti fi dá ìbẹ̀rù sọ́kàn àwọn ènìyàn.

Bákan náà ló ní àwọn ń sa gbogbo ipá láti ri dájú pé àwọn lájọṣèpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣọ́ ààbò tó kù láti ri dájú pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pàápàá ìlú Abuja wà ní ààbò tó péye fún àwọn ènìyàn.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ẹ má ṣe bẹ̀rù! Ìkìlọ̀ UK, US, kò tó ohun à ń gbọ̀ kiri sí l'Abuja – Ààrẹ Buhari

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

Aarẹ orilẹede Naijria ti ni ipe ilẹ Amẹrika ati United Kingdom si awọn eeyan wọn ni Naijiria ko fa ibẹru lọwọ.

Aarẹ ni ikilọ awọn orilẹede ilẹ okere mejeji yii ko tumọ si wipe ikọlu yoo waye.

Ninu ọrọ ti agbẹnusọ aarẹ Garba Shehu fi sita ni Ọjọ Ẹti ni aarẹ ti sọ eyi to si ti pe awọn oṣiṣẹ alaabo nija lati igba ti ikọlu ọgba ẹwọn Kuje ti ṣẹlẹ pe ki alakan wọn fi oju ṣọ ori.

“Kii ṣe orilẹede Naijiria nikan lo wa lori iwe akọsilẹ awọn ilu ti ipaya ikọlu ti gbilẹ tawọn ilu okere si n kilọ nipa wọn”.

Aarẹ ni ipe ikilọ UK ati US lori irinajo ta ba awọn ikọlu to ṣeeṣe ko waye lawọn orilẹede ilẹ alawọfunfun naa.

“Amọ eyi ko tumọ́ si wipe ikọlu yoo waye nilu Abuja”.

DSS ni awọn ko pawọpọ pẹlu ikọ ogun Amẹrika

Awọn ileeṣẹ alaabo orilẹede Naijiria ti ni awọn ko ṣe ikọ amuṣẹya kankan pẹlu awọn ologun ilẹ okere ni ilu Abuja tii ṣe olu ilu orilẹede yii.

Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS sọ fun BBC pe awọn ko gbe igbesẹ tabi ṣe iṣẹ kankan gẹgẹ bi ikọ amuṣẹya pẹlu awọn ologun ilẹ okere.

Iroyin ti awọn oniroyin abẹlẹ ti n gbe ṣaaju eyi ni pe itujade awọn ologun waye ni ọjọ Aje nibi ti awọn ologun ti fi panpẹ ofin mu awọn afurasi kan pẹlu awọn nkan abugbamu.

Ẹwẹ, awọn oṣojumikoro sọ pe ni alẹ ọjọ Aje ni iṣẹ naa waye ti wọn si ti gbogbo awọn olugbe ọgba ile elero kan mọ inu ọgba wọn lasiko ti wọn n ṣiṣẹ.

Iroyin naa n jade lẹyin ti ileeṣẹ ilẹ US ati UK ni Naijria fi ikilẹ ipaya sita fun awọn araalu wọn to wa lorilẹede Naijiria.

Eyi si ti da ibẹrubojo si ọkan ọpọlọpọ̀ eeyan nilu Abuja.

Bulgaria, Germany pẹlú Amerika fí ìkìlọ sita lórí ikọlù àwọn agbésùmọ̀mí sí Abùjá

Asia U.S ati ilu Abuja

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gẹgẹ bi Amẹrika ti ṣe fi ikilọ fawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ aṣoju rẹ ni Abuja lati maa ṣọra lori ikọlu awọn agbesunmọmi si Abuja, awọn orileede mii na ti ṣe bẹẹ.

Ninu awọn to kọwọ rin fi ikilọ ẹdira yi sita la ti ri Bulgaria, Germany ati Ireland.

Wọn kede pe awọn yoo mu adinku ba iṣẹ tawọn oṣiṣẹ aṣoju ilẹ wọn n ṣe ti wọn si tun kilọ fawọn ọmọ ilẹ wọn lati sọra pẹlu irinajo.

Niṣe lawọn naa ke igbe ikilọ fawọn ọmọ ilẹ wọn lati ṣọra pẹlu eyikeyi irinajo ti wọn yoo ṣe si Abuja.

Ikilọ wọn yi n waye lẹyin bi ọjọ meloo kan ti orileede Amẹrika ati ilẹ Gẹẹsi fi ikilọ sita pe o ṣeeṣe ki awọn kan ṣe ikọlu si ilu Abuja.

Australia ati Canada naa fi ikilọ iru rẹ sita.

Ninu esi ti ijọba Naijria fọ si ọrọ yi, wọn ni ko si ewu loko ati pe wamuwamu lawọn agbofinro wa lati koju ipenija eyikeyi to ba w nipa aabo.

Laipẹ yi, ọga agba ọlọpaa Naijiria sọ pe ko si ewu ikọlu kankan to to ki awọn araalu maa kaya soke ni Naijiria.

Usman Baba fi awọn nọmba taraalu le pe sita lalẹ Ọjọbọ yi to si ni ileeṣẹ ọlọpaa n ṣiṣẹ pẹlu awọn ikọ alaabo lati ri pe aabo to peye wa fun awọn araalu.

O tun tẹnu mọ pe ko si ewu ikọlu si Abuja gẹgẹ bi orileede Amẹrika ti ṣe figbe sita.

U.S pàṣẹ kí àwọn òṣìṣẹ́ wọn tí iṣẹ́ wọn kìí ṣe pàjáwìrì gbéra kúrò ní Abuja

Orilẹede Amẹrika ti fi aṣẹ sita ni Ọjọbọ ọsẹ pe ki awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ wọn to wa nilu Abuja ti iṣẹ kii ṣe iṣẹ pajawiri kuro ni ilu naa tii ṣe olu ilu orilẹede lẹyẹ o sọka. Koda wọn tun paṣẹ pe ki wọn rii pe awọn ati ẹbi wọn ni wn kuro ni ilu Abuja ti wọn si n tọka si ikọlu awọn agbesunmọmi ti wọn ni o tun ti le sii.

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ilẹ Amẹrika yii ko sọ patọ idunkokomọni ti wọn kẹfin amọ orilẹede wọn ti ṣaaju kilọ fun orilẹede Naijiria pe ki wọn fura tori awọn agbesunmọmi lee ṣe ikọlu ti wọn si darukọ awọn ibi to yẹ ki wọn ti ṣọra bii awọn ile itaja nla nla, ọja, ile itura, ile ounjẹ, ile ọti tabi awọn ileewe.

Igbesẹ tuntun ti akọwe agba ileeṣẹ Amẹrika lorilẹede Naijiria yii waye lẹyin ti wọn kilọ pe ki awọn ara Amẹrika to wa lorilẹede Naijiria din irinkaakiri wọn ku paapaa nilu Abuja.

Bakan naa, ilẹ Britain, Canada ati Australia gan ti fi iru ikilọ yii ranṣẹ saan eeyan wọn.

Bawo ni ọrọ abo Abuja ṣe ri tẹlẹ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu itan, Abuja wa lara awọn ilu ti aabo ti daju ni Naijiria ṣugbọn nigba ti o ti so mọ ọrọ igbesunmọmi ti awọn alakatakiti ẹsin Islam n ṣe lawn agbegbe rẹ lati nkan bii oṣu mẹfa bayii ni nnkan ti yipada.

Ẹwẹ, ijọba apapọ ti ni ki awọn araalu fọkan balẹ ki wọn si gbe igbesẹ to ba yẹ. Bakan naa, awọn ọlọpaa ti fohun wọn lee ti wọn si gbe igbesẹ igbogun ti iwa sunmọmi kankan to ba fẹ yọju.

Eyi ti n gbe ọkan ọpọlọpọ́ eeyan soke nilu Abuja ati lawọn ipinlẹ mii Lara ọrọ inu atẹjade U.S ka bayii pe:

“A gba imọran pe ki awọn ọmọ U.S ma rinrinajo lọ si ilu Abuja bayii”.

Lafikun, atẹjade to jade lọjọ Kẹtadinlọgbọn sọ pe ẹka ileeṣẹ Amẹrika to wa ni

Naijiria ti paṣẹ pe ki gbogbo gbogbo oṣiṣẹ Amẹrika to wa ni Naijiria kuro ni Abuja bayii.

“Ki awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Amẹrika gbero lati kuro ni Abuja lasiko yii nitori ibẹrubojo to kalẹ lori igbesunmọmi”.

Wọn ti fi awọn adirẹsi sita pe ẹnikẹni ti ko ba ri ọna kuro ni Abuja ki wọn kan si awn adirẹsi naa fun iranwọ paapaa adirẹsi ori ayelujara ti ọfiisi wọn to wa ni ipinlẹ Eko.