'Ikú ọmọ kò tíì kúrò lára mi tán, bí wọ́n ṣe tún pa ọkọ mi sínú ilé yìí kan náà lójú mi kòrókòró rèé'
“Iwe ilẹ ti wọn n tẹnu mọ ti wọn n bere lọwọ wa fihan pe nkankan wa nidi ọrọ naa”.
Iyawo arakunrin ti awọn apaayan dede wọ inu ile wọn lọ pa ni ilu Akure, ipinlẹ Ondo sọ fun BBC Yoruba bi iku ọkọ rẹ ṣe tun ba ti ọmọ rẹ ti ko tilẹ tii kuro lara rẹ tan.
Iroyin naa jade pe wọn lọ pa Michael Adesitimi ti o jẹ oṣiṣẹ imọ ẹrọ kọmputa to tun mu iṣẹ agbẹ mọ ọ.
Ninu iroyin kan naa la ti gbọ eyi ti ọmọ ọkunrin arakunrin naa si fi aridaju han fun BBC pe ni oṣu bii mẹwaa sẹyin ni wọn pa ọmọ obinrin oloogbe yii ninu ile kan naa.
“Wọ́n di ọwọ́ ọmọ mi méjèjì lórí aga ni wọ́n sì ti fi odó pà á; Nígbà ti ọkọ mi, mo yọ́ gun orí fẹ́sì ni mo rí bí wọ́n ṣe ń pà á”.
Iyawo arakunrin naa ti a fi oju ati orukọ rẹ pamọ nitori aabo rẹ jẹ ko di mimọ pe awọn kan gbọ ti awọn kan n kan geeti ile awọn ti ọkọ rẹ si lọ ṣilẹkun fun un.
Afi ti wọn wọle to ni oun rii pe wọn ti fi kọ oun si aarin wọn pẹlu ibọn lọwọ ti wọn si n beere pe “iwe naa da”.
Ọmọ ọkunrin oloogbe naa mu BBC Yoruba rin kaakiri inu ile ti iṣẹlẹ aburu iku mejeji ti baba rẹ ati aburo rẹ ti ṣẹlẹ.

Lẹ́yìn oṣù mẹ́sàn-án tí wọn pa ọmọ rẹ̀ ní Akure ni ikú tirẹ̀ náà wáyé

Oríṣun àwòrán, Michael Adesitimi
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti fidirẹ mulẹ pe lootọ ni awọn wọle pa ọkunrin kan, Michael Adesitimi nilu Akure.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Funmilayo Odunlami sọ fun BBC pe ni alẹ ọjọ Satide, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹwaa, ni iṣẹlẹ naa waye ni ile oloogbe to wa ni agbegbe Okuta elerinla.
Iroyin sọ pe ni nkan bi aago mẹsan-an ni oloogbe Adesitimi ati iyawo rẹ deede gbọ ti awọn kan n gbá ilẹkun abawọle wọn.
Awọn iwe iroyin abẹle jabọ pe ọmọkunrin oloogbe naa sọ pe lati igba ti awọn kan ti wọle pa aburo oun, ni awọn ko ti fi ọrọ abo falẹ mọ.
“Iya mi sọ pe lati oju ferese ni oun ti n wo gbogbo nkan to n ṣẹlẹ. Nibẹ lo si ti ri awọn ọkunrin meji to fi ipa gba ẹnu geeti wọle.”
O ṣalaye pe iya oun ni oun ko ri oju awọn ọkunrin naa nitori pe ilẹ ti ṣu. Amọ o ṣa a ri pe ẹnikan lara wọn mu ibọn dani.
“Lati ẹnu ọna si ni wọn ti tẹle baba mi pada wọle.”
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, obinrin naa ri aaye gba ẹyinkule ile jade to si salọ si ile to wa ni ẹ̀gbẹ́ wọn.
Iroyin ni lati ibẹ lo tii lọ pe awọn ọlọpaa to wa ni ibudo kan nitosi, “amọ dipo ki wọn o tẹle wa pada sile, wọn kọkọ gbe wa lọ si agọ wọn naa.
“Ọpọlọpọ asiko ni wọn fi ṣofo ki wọn o to tẹle wa.”
O ni wọn ti pa ọkunrin naa nigba ti wọn o fi pada de ile pẹlu ọlọpaa.
Amọ alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami sọ pe eyi ko ri bẹẹ.
Arabinrin Odunlami ṣalaye pe ko si nkan to buru ninu ki ọlọpaa to wa ni oju ọna, pada lọ si agọ ọlọpaa lati beere fun iranlọwọ awọn akẹẹgbẹ wọn.
“Ko ṣe e ṣe ki ọlọpaa kan tabi meji to wa ni opopona lọ ọ koju awọn to gbe ibọn dani, lai jẹ pe awọn akẹẹgbẹ rẹ pese iranlọwọ.
“Bi igba ti o fẹ fi ẹmi ara rẹ ṣofo ni, to ba da lọ.”
O ṣalaye pe awọn ọlọpaa ọhun naa lo gbe ọkunrin ọhun lọ sileewosan nibi ti dokita ti kede pe o ti ku.
Amọ ṣa, Arabinrin Odunlami sọ pe iwadii ti n lọ lori iṣẹlẹ naa.
Àwọn agbanipa wọlé pa ọkùnrin kan













