‘’Ẹnikẹ́ni tó bá tún dí ojú pópó láì ṣe ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Benue yóò fojú winá òfin’’

Oríṣun àwòrán, Olumuyiwa Adejobi/Facebook
Kọmisọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Benue, Bartholomew Onyeka ti paṣẹ pe ki awọn agbofinro ko gbogbo ohun tawọn eeyan kan ti kii ṣe oṣiṣẹ eleto aabo fi n di ọna kaakiri ipinlẹ naa.
Kọmiṣọnna Onyeka tun paṣẹ pe kawọn agbofinro mu ẹnikẹni to n ba gbegi dina loju popo lai sẹ oṣiṣẹ eleto aabo.
Gẹgẹ bi atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Benue, Catherine Anene, fi sita ọga ọlọpaa paṣẹ naa lẹyin to ṣe akiyesi awọn ibi kan tawọn eeyan kan ti wọn ki i ṣe ọlọpaa ti n dina loju popo.
Anene ṣalaye ninu atẹajde naa pe gbogbo awọn ọga ọlọpaa patapata gbọdọ ri pe wọn pe aṣẹ kọmiṣọnna naa mọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Benue kọmiṣọnna kọminu lori awọn ibudo tawọn kan di di ọna yii tori awọn ọdaran le maa jale nibẹ lalẹ.
Ọga ọlọpaa naa wa kilọ fawọn to ba n ṣe iru rẹ rẹ lati jawọ, bi bẹẹ kọọ, wọn o foju wina ofin.
Bakan naa ni ọga ọlọpaa tun rọ awọn eeyan ipinlẹ Benue to ba kofiri iru awọn eeyan bẹẹ lati fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.











