Àlàyé rèé lórí bí ilé ẹjọ́ ṣe fún Oluwo Nla Tede ní béèlì tó sì sún ìgbẹ́jọ́ Tani Olohun síwíajú

Oríṣun àwòrán, Muyiwa Omo Yoruba/X
Ile ẹjọ Upper Area niluu Ilọrin ti fun Oluwo Nla Tede ni beeli, o si tun sun igbẹjọ Tani-Ọlọhun si ọsẹ to n bọ.
Awọn oniṣẹṣe mejeeji yii, Tani Ọlọhun ati Oluwo Nla Tede, ni wọn kawọ sẹyin rojọ niwaju ile-ẹjọ lẹyin ti Alfa Okutagidi pe wọn lẹjọ fun ẹsun igbimọpọ lati tabuku ati ibanilorukọ jẹ ati dida rogbodiyan silẹ, eyi ti wọn ni o lodi sofin orilẹ-ede Naijiria.
Agbẹjọro Tani-Ọlọhun, Ademọla Bank, lo mu iwe kan wa si kootu pe ki adajọ fun onibara oun ni beeli, o ni ẹsun ti wọn fi kan an ko lagbara to ki wọn ma lee gba beeli rẹ.
Ninu atako tirẹ, agbẹjọro Okutagidi, Usman Imaam, rọ ilẹ-ẹjọ lati keti ọgbun si akẹgbẹ rẹ wi pe ahamọ gan an lo tọ si olujẹjọ naa.
O ni "Tani Ọlọhun n gbele ọfẹ ni ahamo, o n jẹ ounjẹ ọfẹ, ọkọ ọfẹ lo si n gbe wa sile ẹjọ, ẹ fi i silẹ ko maa jẹgbaladun awọn nkan ọfẹ yii lọ.''
O tẹsiwju pe, olujẹjọ ọhun n wa sile ẹjọ pelu awon ẹsọ alaabo lọpọ yanturu fun idaabobo ẹmi rẹ, ati pe fifun un ni beeli le mu ki ẹmi rẹ wa ninu ewu.
O tun tako o pe ko ni adirẹsi kan gidi ti wọn le wa a si, ati pe o n jẹjọ nile ẹjọ miiran fun ẹsun ọdaran bakan naa.
Niti Oluwo Nla Tede, o ni oun ko ta ko beeli rẹ nitori o ti mọ ẹṣẹ rẹ lẹṣẹ, o si ti tuu ba.
Ademọla Bank da a lohun pe, o wa ninu iwe itako ti won fi pe ẹjọ pe nọmba 53, niluu Ibadan ni Adirẹẹsi Tani Ọlọhun.
O tẹmpẹlẹ mọ an pe idajọ ododo ni oun fẹ ko waye lori ẹjọ naa.
Onidaajọ Sunday Adeniyi, fun Oluwo Nla Tede ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (500,000), pẹlu oniduuro meji, ti ọkan yoo si ni dukia lagbegbe ile-ẹjọ.
O sun igbẹjọ si ọjọ Aje, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii.
Ẹ má ṣe sà sí mi, ara yín ni kí ẹ sà sí - Adájọ́ tó ń gbẹ́́jọ́ Tani Olohun ké gbàjarè

Oríṣun àwòrán, Tani Olohun/Facebook
Adajọ ile-ẹjọ Upper Area, Họnọrebu Sunday Adeniyi ti ke gbajare si awọn to n ṣ'atilẹyin fun Tani Ọlọhun ati Alfa Okutagidi ti o jẹ olupẹjọ wi pe ki wọn ma ṣe ṣa si oun ṣugbọn ki wọn kọju si ara wọn.
Họnọrebu Adeniyi ni o sọ eleyii logunjọ oṣu kẹsan an ọdun 2023 ni ile ẹjọ ọhun nigba ti wọn n gbọ ẹjọ lọwọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan Tani Ọlọhun ati Oluwo Nla ti ilu Tede.
Adajọ ọhun tẹsiwaju pe ki wọn ye wa fọto oun kiri, o si sọ pẹlu igboya wi pe wọn ko lee ri i.
O ṣalaye pe, oun ko mọ ẹnikankan ninu olupẹjọ ati olujẹjọ tabi awọn alatilẹyin wọn, wi pe iṣẹ ohun ni oun loun n ṣe.
Adajọ Adeniyi ko ṣai sọ pe oun yoo gbe idajọ kalẹ lai gbe lẹyin ẹnikẹni ṣugbọn ninu ootọ ati ododo.
Ni ibi ti ọrọ naa ka a lara de, niṣe ni o pa ede Gẹẹsi ti, ti o si n sọ ede abinibi rẹ ti o jẹ Yoruba.
Adajọ Adeniyi ni "ẹ ma ṣe ṣa si wa, ẹ ye wa fọto wa kiri, ẹ ko lee ri i nitori pe a o ṣẹ yin.
A ko mọ ẹnikẹni ri ninu Tani Ọlọhun ati Alfa Okutagidi, arayin ni ki ẹ ṣa si i ati awọn agbẹjọro yin, kii ṣe awa.
A ti bura wi pe a o ṣe idajọ ododo ṣugbọn ti a ba ṣe aṣiṣe, ile ẹjọ wa loke ti ẹ tun le lọ."
Họnọrebu Adeniyi sọ ọrọ wọnyii ni kete to jokoo si ori aga rẹ ni ibẹrẹ igbẹjọ naa.
A ko mọ idi pato ti o fi sọ ọrọ naa nitori a o mọ iriri rẹ lori ẹjọ ọhun .
Igbẹ́jọ́ Tani Ọlọ́run lórí ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́ tẹ́síwájú lónìí ní Upper Area Court

Oríṣun àwòrán, Tani Olohun/BBC
Igbẹjọ Tani Ọlọhun yoo bẹrẹ ni pẹru lonii Wẹsidee ogunjọ, osu kẹsan an ni ile ẹjọ Uppper Area ti o kalẹ si ilu Ilọrin, ni ipinlẹ Kwara.
Eleyi yoo ma waye lẹyin ti ile ẹjọ ti wọgile awon ẹbẹ meji ọtọọtọ ti awon agbẹjọro onisẹse naa pe fun.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ni ọjọ kọkanla osu yi ni ile ẹjọ yi kan naa labẹ idari, Honourable Sunday Adeniyi wọgile iwe atako si ofin ti agbarijọ agbẹjọro olujẹjọ ọhun pe fun.
Ni ana ode yii bakan naa ni ile ẹjọ Majisireeti tun wọgile ẹbẹ fun beeli tabi oniduro fun un.
Oni ni Tani Ọlọhun ati awon agbẹjọro rẹ yoo mo odo ti won yoo da ọrunla si nitori igbẹjọ lori ẹsun ibanilorukọ jẹ ti won fi kan an gangan ni ile ẹjọ yoo gbọ.
Ti ẹ ko ba gbagbe bakan naa, ọjọ kẹtadinlogun osu kẹsan an ọdun yii ni won kọkọ wọ Olujẹjọ ọhun wa si iwaju, Magistrate Muhammed Ibrahim ti ile ẹjọ Majisireti. Ile ẹjọ naa si pasẹ ahamọ aadọta ọjọ fun un.
Ilé ẹjọ́ kọ̀ láti fún Tani Ọlọhun ní béèlì, àwon agbẹjọ́rò rẹ̀ fárígá
Ile ẹjọ Majisireti, ti o fi ilu Ilọrin se ibujoko ti kọ lati fun gbajugbaja oniṣẹṣe un ni, Addulazeez Adegbola,Tani-Ọlọhun, ni
beeli.
Tani Ọlọhun ni o n jẹ ẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Ogo Ilorin fi kan an.
Ninu idajọ ranpẹ ti o gbe kalẹ lonii ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹsan an ọdun yii, Adajọ Muhammed Ibrahim da ẹjọ beeli ti awọn agbẹjọro olujẹjọ naa pe
fun nun.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ni ọjọ kejila oṣu yii ni awọn agbẹjọro Tani Ọlọhun farahan ni ile ẹjọ naa lati fi iwe beeli rẹ sita ti ile ẹjọ si sun igbẹjọ si oni.
Ni oni, olufisun ajọ Ọlọpaa, Supo Nasir Yusuf tako ẹbẹ fun gbigba oniduro tabi beeli olujẹjọ ọhun.
O sọ wi pe ẹjọ ti wọn fi lede ninu iwe beeli naa tako ara wọn ti ko si ni ojutuu.
O tun tẹsiwaju pe ile ẹjọ ko mọ ibugbe ti o le wa olujẹjọ naa si, bẹẹ si ni ko ni oniduro ti o yanranti ti wọn le kepe to ba kọ lati farahan nile ẹjọ lẹyin ti wọn ba fun un ni beeli tan.
O rọ ile ẹjọ ki o da ẹjọ beeli naa nun wi pe olujẹjọ naa yoo salọ.
Adajọ Muhammed Ibrahim gba si i lẹnu, o si da ẹjọ naa nu.
Lẹyin igbẹjọ naa, Ademọla Bank ti o jẹ adari awon agbẹjọro Tani Ọlọhun sọ wi pe o jẹ ohun iyalenu pe ile ẹjọ le da ẹjọ beeli naa nu.



Lẹyin igbẹjọ naa, Ademọla Bank sọ wi pe o jẹ ohun iyalenu pe ile ẹjọ le da ẹjọ beeli naa nu.
O ni ẹsun ti wọn fi kan onibara ohun jẹ ẹsun ti wọn le gba beeli tabi oniduro fun lọjọkọjọ ṣugbọn idajọ ti ẹjọ gbe kalẹ jẹ kayeefi.
O ni nibi ti ọrọ de duro bayi, awọn yoo fori kori lati gbe igbesẹ ti o ba kan.















